Báwo ni mo ṣe lè rí ìtọ́jú oyún ṣíṣẹ́ tí kò béwu dé?

A mọ̀ pé ó máa ń nira láti rí ìtọ́jú oyún ṣíṣẹ́ tí kò béwu dé tí o bá wà ní ìwọ nìkan. Nítorí náà ni a ṣe wà nílẹ̀ láti gbọ́ gbogbo ohun tí o bá ní láti sọ, ṣe àlàyé nípa oyún ṣíṣẹ́ lọ́nà tí kò béwu dé tí ó sì rọrùn, àti bá ọ wá àwọn olùtọ́jú tí ó wà ní agbègbè rẹ bí o bá nílò wọn. Àwọn olùdáninímọ̀ràn wa tí wọ́n ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìṣègùn, ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùtọ́jú oyún ṣíṣẹ́ ni agbegbe rẹ, yóò ṣe àtìlẹyìn fún ọ láì sí ìbẹ̀rù tàbí pẹ̀gàn rẹ.

Aboyun Itọju Iṣẹyun

Ṣe oyún ṣíṣẹ́ kò ní ṣe ìpalára fún mi?

Ní gbogbo àkókò oyún, oríṣiríṣi ìlànà oyún ṣíṣẹ́ tí kò béwu dé ní ó wà fún ọ láti yàn. Àwọn nǹkan wà tí ó lè mú kí ó má le ṣẹ́yún, àwọn olùdáninímọ̀ràn wa sì le gbà ọ́ nímọ̀ràn nípa ohun tí ó bá ipò rẹ mú. Kí o tó bẹ̀rẹ̀ oyún ṣíṣẹ́, ó ní láti mọ iye ọ̀sẹ̀ tí oyún náà jẹ́. Ó lè lo ẹ̀rọ ìṣirò oyún tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí láti ṣírò rẹ̀.

Ẹ̀RỌ ÌṢIRÒ OYÚN

Ọjọ́ wo ni ó ṣe nǹkan oṣù kẹ́yìn?

//

Kọ́ bí o ṣe máa ṣe ìṣirò.

Safe Abortion Care

Oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú oògùn

Oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú òògùn jẹ́ ìlànà kan tí ó rọrùn nípa lílo oríṣi òògùn méjì (Mifepristone and Misoprostol) tàbí ẹyọọ̀kan. Òògùn yìí yóò jẹ́ kí ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ fún pọ̀ tí yóò sì ti oyún náà jáde ní ọ̀nà tí ó jọ tí nǹkan oṣù. Ó lè lò tó ọjọ́ díẹ̀ sí ọ̀sẹ̀ díẹ̀, ó sì ṣeé ṣe ní ilé. Ní safe2choose, a máa ń ṣe àtìlẹyìn fún àwọn obìnrin tí ó bá fẹ́ ṣẹ́ oyún fúnra wọn ní ilé pẹ̀lú òògùn nípa fífún wọn ní àwọn ohun ìrànwọ́ àti àlàyé tí ó péye nípa oyún ṣíṣẹ́ náà. Fún ìlànà yìí, a máa ń ṣe àtìlẹyìn fún àwọn obìnrin tí oyún wọn ò ju ọ̀sẹ̀ mọkanla lọ, a sì máa ń ní kí àwọn tí tiwọn bá ti ju ọ̀sẹ̀ mọkanla lọ lọ rí àwọn alábáṣepọ̀ wa tí ó wà lágbègbè wọn fún àfikún ìtọ́jú oyún ṣíṣẹ́.

OYÚN ṢÍṢẸ́ PẸ̀LÚ ÒÒGÙN

Oyún ṣíṣẹ́ tí kò béwu dé pẹ̀lú òògùn


get-care-clinic

Oyún ṣíṣẹ́ ní ilé ìwòsàn

Ara oyún ṣíṣẹ́ ní ilé ìwòsàn ni oyún ṣíṣẹ́ ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó tí oníṣègùn ṣe, fífà oyún jáde, oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ àti ìtọ́jú ẹ̀yìn tí oyún bá bọ́. Wọ́n máa ń ṣe eléyìí ní ọ́fíìsì olùtọ́jú tàbí ilé ìwòsàn bí òfin ìlú bá fi ààyè gbà á. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, kò kí n mú ìnira lọ́wọ́ nítorí òògùn adániradúró tí wọ́n máa ń lò, kò sì kí ń ju ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ. Tó bá jẹ́ pé èyí ni ó bá ọ lára mu jù, bá wa sọ̀rọ̀ kí á lè darí rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olùtọ́jú tí ó ṣé fọkàn tán.

OYÚN ṢÍṢẸ́ NÍ ILÉ ÌWÒSÀN

Àwọn ìlànà oyún ṣíṣẹ́ ní ilé ìwòsàn tí kò béwu dé.