safe2choose

ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ aláfọwọ́yí (MVA) àti ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ oníná (EVA) –Ìṣẹ́yún inú ilé ìwòsàn

Ìsẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA) tàbí ẹ̀rọ aláfọwọ́yí oníná (EVA) jẹ́ irúfẹ́ ìṣẹ́yún inú ilé ìwòsàn tí a lè ṣe tó ọ̀sẹ̀ mẹ́rìnlá 14 (MVA) àti ọ̀sẹ̀ Mẹ́rìndínlógún (16) (EVA) ti ìlóyún. O lè wá gbogbo àlàyé ti o nílo lórí ojú-ewé yìí. Tí o bá ṣì ní ìbéèrè, kàn sí ẹgbẹ́ ìmọ̀ràn wa.

Pín

Kí ni àwọn ọ̀nà ìyọkúrò oýun pẹ̀lú afẹ́fẹ́ (vacuum aspiration)?

Gloved hands with syringe, droppers, and two-bottle device on blue-striped background, illustrating vacuum aspiration abortion methods
Turquoise stylized machine with three tubes like tentacles on a white background, symbolizing vacuum aspiration.

Àwọn ọ̀nà ìṣẹ́yún pẹ̀lú afẹ́fẹ́ ni a mọ̀ sí ìṣẹ́yún pẹ̀lú iṣẹ́-abẹ, ìyọkúrò oyún pẹ̀lú afẹ́fẹ́, ìsẹ́yún pẹ̀lú àfàmọ́ra agbára afẹ́fẹ́, tàbí àwọn ìṣẹ́yún inú ilé-ìwòsàn.

Oríṣi méjì ti àwọn ọ̀nà ìṣẹ́yún pẹ̀lú afẹ́fẹ́ , èyítí ó wọ́pọ̀ jùlọ jẹ́ MVA, tàbí ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ aláfọwọ́yí , àti EVA,Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ oníná. Ìyàtọ̀ àkọ́kọ́ laarin MVA àti EVA ni pé a lo iná mọ̀ǹamọ́ná láti ṣẹ̀dá àfàmóra láti yọ oyún ní EVA, àti pé ó le ṣee ṣe títí di ọ̀sẹ̀ mẹ́rìndínlógún(16) ti oyún.

Icon of a light blue heart with a teal medical cross overlapping it on the right side, suggesting themes of healthcare and compassion.

MVA àti EVA jẹ́ àwọn ọ̀nà àìléwu tí ó múnádóko fún ìṣẹ́yún àti ìṣákoso ìṣẹ́yún. Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) dábàá àwọn ìlànà ìṣẹ́yún pẹ̀lú afẹ́fẹ́ nítorí wọ́n ní ewu kékeré, yára, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ dáadáa ju ìdá méjìdínlọ́gọ́run sí kọkàndínlọ́gọ́run (98-99%) lọ nígbà tí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ bá ṣe é. Ìlànà náà kò ju ìṣẹ́jú márùn (5] sí mẹ́wa (10) lọ, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìrírí àìsàn díẹ̀ àti ẹ̀jẹ̀ díẹ̀, àti pé ìpadàbọ̀sípò kíkún máa ń gba ọjọ́ díẹ̀. MVA àti EVA ní ewu kékeré fún àwọn ìṣòro àti pé wọn kò ní ipa lórí ìbímọ ọjọ́ iwájú. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀nà tí wọ́n fọwọ́ sí nípa ìṣègùn, wọ́n jẹ́ àṣàyàn tí ó se gbẹ́kẹ̀lé tí ó sì dára fún ìṣẹ́yún àti ìyọkúrò oyún nígbà tí àwọn oníṣègùn tó kúnjú ìwọ̀n bá ṣe é.

Báwo ní ìṣẹ́yún pẹ̀lúẹ̀rọ afẹ́fẹ́ aláfọwọ́yí (MVA) ṣe ń Ṣiṣẹ́?

ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ aláfọwọ́yí (MVA) jẹ́ ìlànà ìṣẹ́yún tí ó ní ààbò nínú ilé ìwòsàn tí a lè ṣe títí di ọ̀sẹ̀ kẹrìnlá (14) oyún. Ìlànà yìí máa ń lo ẹ̀rọ àfàmọ́ra agbára afẹ́fẹ́ ọwọ́ láti yọ oyún náà jáde ó sì máa ń pẹ́ tó ìṣẹ́jú márùn (5) sí mẹ́wà (10).

ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ aláfọwọ́yí (MVA) jẹ́ ọ̀nà ìṣẹ́yún tí ó ní ààbò fún oyún ní oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ àti/tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù mẹ́ta kejì, títí di ọ̀sẹ̀ kẹrìnlá (14) óyún. Òpin ọjọ́ orí oyún fún MVA sábà máa ń yàtọ̀ lórí ilé ìwòsàn àti olùpèsè ìlera tó ń ṣe ìlànà náà.

MVA ni a ṣe nípasẹ̀ olùpèsè tí a kọ́ ní ilé-iṣẹ́ ìlera kan. Nígbà ìlànà náà, oníṣègùn náà máa ń lo àwọn ohun èlò, pẹ̀lú ẹ̀rọ àfàmọ́ra agbára afẹ́fẹ́ ìdákẹ́jẹ́ẹ́, láti yọ oyún náà kúrò nínú inú ilé-ọmọ. Ìlànà yìí ni wọ́n sábà máa ń ṣe pẹ̀lú oògùn ìrora ìbílẹ̀ nígbà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá jí, tí ó máa ń waye láàárín ìṣẹ́jú márùn (5) sí mẹ́wà (10).

Nígbà tí wọ́n bá pa á lábẹ́ àwọn ipò ààbò láti ọwọ́ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí wọ́n kọ́, MVA ṣe àfihàn ìmúṣe ni ìdá méjìdínlọ́gọ́run sí kọkàndínlọ́gọ́run (98-99%) pẹ̀lú àwọn ìṣòro kékeré, tí ó jẹ́ kí ó jẹ́ àṣàyàn tí ó se gbẹ́kẹ̀lé fún ìfòpin sí oyún ní oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù mẹ́ta kejì.

Báwo ní ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ oníná (EVA) ṣe ń Ṣiṣẹ́?

Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ oníná (EVA) jẹ́ ìlànà fún ìṣẹ́yún tí wọ́n ṣe ní ilé ìwòsàn tí ó ń lo àfàmọ́ra agbára afẹ́fẹ́ o ni iná mọ̀nàmọ́ná. Ó jẹ́ ọ̀nà tí ó ní ààbò àti ìyara tí ó le ṣeé ṣe títí di ọ̀sẹ̀ kẹriǹdínlógún (16) ti oyún.

Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ oníná (EVA) jẹ́ ọ̀nà tí ó ní ààbò tí ó sì jọra púpọ̀ pẹ̀lú ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ aláfọwọ́yí MVA). Ó le ṣe lò fún àwọn oyún títí di ọ̀sẹ̀ kẹriǹdínlógún (16).Olùpèsè tí a kọ́ ní ilé-iṣẹ́ ìtọ́jú ìlera ni ó le se. Nígbà ìlànà náà, oníṣègùn náà máa ń lo àwọn ohun èlò, pẹ̀lú ẹ̀rọ agbára afẹ́fẹ́ o ni iná mọ̀nàmọ́ná láti yọ oyún kúrò nínú ilé-ọmọ.

EVA nílò iná mọ̀nàmọ́ná, nítorínà ó lè má wà ní gbogbo àwọn agbègbè. Àwọn oníṣègùn lè lo ọ̀nà yìí dípò MVA nítorí pé ìlànà náà lè di ṣíṣe ní kíákíá.

Ẹ̀rọ EVA ń pa ariwo díẹ̀ sii nítorí a lo iná láti ṣẹ̀dá àfàmọ́ra àti yọ oyún náà kúrò.

EVA ni a mọ̀ láti jẹ́ ọ̀nà àìléwu tí ó ṣe gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú ewu kékeré ti àwọn ìṣòro nígbàtí o bá ṣe ní agbègbè tí kò ní ìdíwọ́ nípasẹ̀ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ìtọ́jú ìlera tí a kọ́. Ìwọ̀n àṣeyọrí rẹ̀ yàtọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ pàtó, ṣùgbọ́n EVA ni wọ́n sábà máa ń ròyìn pé ó ní ìwọ̀n àṣeyọrí ìdá kọkàndínlọ́gọ́run 99% nígbà tí wọ́n bá ṣe é dáadáa.

EVA ni a mọ̀ láti jẹ́ ọ̀nà àìléwu tí ó ṣe gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú ewu kékeré ti àwọn ìṣòro nígbàtí o bá ṣe ní agbègbè tí kò ní ìdíwọ́ nípasẹ̀ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ìtọ́jú ìlera tí a kọ́. Ìwọ̀n àṣeyọrí rẹ̀ yàtọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ pàtó, ṣùgbọ́n EVA ni wọ́n sábà máa ń ròyìn pé ó ní ìwọ̀n àṣeyọrí ìdá kọkàndínlọ́gọ́run 99% nígbà tí wọ́n bá ṣe é dáadáa.

Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni kí n tó ṣe kí n to se ìṣẹ́yún àfàmọ́ra agbára afẹ́fẹ́?

Ṣáájú ìṣẹ́yún MVA tàbí EVA, ó yẹ kí o kàn sí olùpèsè iṣẹ́ ìlera kan, ṣe àtúnyẹ̀wò ìtàn-àkọọlẹ̀ ìṣègùn rẹ, kí o sì tẹ̀lé èyíkéyì àwọn ìlànà ìgbáradì, gẹ́gẹ́bí lí́lo ìtùnú ìrora tàbí àwọn òògùn àrùn-kòkòrò.

Illustration of a calendar with circled dates, “>14” speech bubble, syringe, and test strips, symbolizing steps before vacuum aspiration abortion.

Ta ni ó yẹ fún ìṣẹ́yún MVA tabi EVA?

MVA/EVA le ṣee ṣe lórí àwọn ẹni-kọ̀ọkan tí ó:

  • nílò ìṣẹ́yún tí ó fa títí di ọ̀sẹ̀ kẹrìnlá (14) ti oyún;

  • ní ìrírí oyún tàbí ìṣẹ́yún tí kò pẹ́ àti pé ó nílò yíyọ kúrò ilé ọmọ;

  • ti ní àyẹ̀wò pẹ̀lú oyún ìju àti nílò yíyọ ilé ọmọ; àti

  • nílò yíyọ kúrò ilé ọmọ lẹ́hìn pípàdánù oyún láti ṣe ìdíwọ́ àwọn ìyọnu.

Tálọ́ kò yẹ kí ó ṣe ìṣẹ́yún àfàmọ́ra agbára afẹ́fẹ́?

Àwọn ìlànà MVA àti EVA máa ń wà ní ààbò àti pé ó máa ń ṣiṣẹ́ dáadáa nígbà tí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ìlera tó kúnjú ìwọ̀n bá ṣe é. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ohun èlò pàtó àti ìṣọ́ra gbọ́dọ̀ jẹ́ àkíyèsí láti ṣe ìdánilójú ààbò.

Báwo ni mo ṣe gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ fún ìṣẹ́yún MVA tàbí EVA?

Ìmúra sílẹ̀ fún ìlànà ṣáájú ṣe ìrànlọ́wọ́ láti ṣe ìdánilójú ìrírí tí ó rọrùn tí ó sì dín ewu tí o le jáde kù. Èyí ni àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì láti ṣe àkíyèsí ṣáájú ìpàdé rẹ fún MVA tàbí EVA kan.

Illustration of a thoughtful woman with long hair, wearing a floral yellow top and blue pants. She touches her chin, next to a speech bubble with a question mark.

Àwọn Ìbéérè tí wọ́n maa ń bèèrè lọ́pọ̀ ìgbà lórí ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ aláfọwọ́yí (MVA)

Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ àfámọra agbára afẹ́fẹ́ Ati Iṣẹ́ Abẹ ìtànkálẹ̀ àti ìgbàsilẹ̀ (D&E)? jẹ́ àwọn ọ̀nà ìṣẹ́yún tí kò léwu, tí ó sì múnádoko, ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn ni ìgbà tí wọ́n ń lò wọ́n àti bí wọ́n ṣe ń lò wọ́n, èyí tó lè nípa lórí ìrírí náà lápapọ̀. Ìgbà wo ni:

A sábà máa ń lo ẹ̀rọ àfámọra agbára afẹ́fẹ́ (ọlọ́wó tabi itanna) ní oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú oyún, títí di nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́rìnlá sí mẹ́rìndínlógún nínú oyún. A sábà máa ń lo D&E ní oṣù mẹ́ta kejì, lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́rìnlá sí mẹ́rìndínlógún àti títí dé nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́rìnlélógún, ó dá lórí òfin àdúgbò àti ìlànà ilé ìwòsàn.

Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é: Wọ́n máa ń fi ẹ̀rọ rọra fa ẹ̀jẹ̀ ọmọ náà jáde láti inú ọlẹ̀. Ìtọ́jú yìí kì í pẹ́ rárá, wọ́n sábà máa ń ṣe é ní ilé ìwòsàn, wọ́n á sì fi oògùn tó ń dẹnu kọlẹ̀ mú un, kò sì ní gba pé kí ònà ilé ọmọ máa gbòòrò sí i. Nítorí pé a máa ń lo D&E nígbà tó bá yá nínú oyún, ó ní àwọn ìgbésẹ̀ àfikún nínú, bíi fífa ònà ilé ọmọ kó gbòòrò sí i àti mímú oyún náà kúrò nípa lílo àdàpọ̀ ẹ̀rọ àfámọra agbára afẹ́fẹ́ àti àwọn ohun èlò abẹ (bí ọ̀bẹ̀) nítorí pé oyún náà ti dàgbà sí i.

Àkókò àti ìrírí ìmúbọ̀sípò: Àwọn ìgbésẹ̀ méjèèjì kúrú, ó sì sábà máa ń yára láti mú ara dá. D&E lè gba ìmúrasílẹ̀ tó pọ̀ sí i fún ọ̀nà ilé ọmọ, ó lè gba àkókò tó gùn sí i, ó sì lè gba ìtọ́jú ìrora tó lágbára ju ẹ̀rọ àfámọra agbára afẹ́fẹ́ lọ.

Blogs

Latest Posts on Pregnancy Confirmation

Explore our articles for more information about pregnancy confirmation and the gestational age calculator.

Àwọn ìtàn gidi láti inú àwùjọ wa

Ṣàwárí àwọn ìtàn àti irírí tó jinlẹ̀ ti àwọn ẹni tó ti gbẹ́kẹ̀lé safe2choose. àwọn Ìjẹ́rìsí wọ̀nyí fi ìtìlẹ́yìn àti ìtọ́sọ́nà tí a pèsè hàn, tí ń ṣàfihàn ipa tí àwọn iṣẹ́ wa kó.

Illustration of two women talking: one, a safe2choose counselor, with curly hair in teal floral dress, the other with long black hair in yellow floral dress sharing real stories from the community

Even though I was still very apprehensive, I decided to trust them and share my despair. To my surprise, I was warmly welcomed by the counselors and received all the guidance I needed.

I reached out here because I was desperate and didn’t know who to turn to. I had been searching on Google and found this wonderful team. Even though I was still very apprehensive, I decided to trust them and share my despair. To my surprise, I was warmly welcomed by the counselors and received all the guidance I needed. I was quickly referred to the appropriate place, where I was also treated with great care, and I was able to have my abortion in about a week. It was a very positive experience, with kind support and without judgment.

Anonymous, Bùràsílì

Age: 40, October 2025

I don’t feel ready to have another baby. They inserted a copper IUD incorrectly, and I got pregnant.


I decided to have an abortion because I don’t feel ready to have another baby. They inserted a copper IUD incorrectly, and I got pregnant. My baby was born six months ago, I had postpartum depression, and it’s still hard to feel like I’m doing things right. I don’t think a new baby deserves all the stress from work, a small child, and a complicated relationship. The baby’s father didn’t want the pregnancy either.
After the abortion, I felt very guilty. I’m still sad about what happened because I tried to take care of myself and this still happened. I didn’t know what to do or where to go because abortion is illegal in my country. I found this page, and they helped me a lot and gave me contacts to make this a safe process, especially because I had the IUD and that complicated things.
If you’re in a similar situation, the best thing is to talk about it and cry as much as you need to let the grief out. I don’t think this is easy for anyone, especially if you’re a first-time mom.
Also, it’s better to be well informed about contraceptive methods and their side effects... I learned that you have to visit several doctors to get different opinions and inform yourself better. The copper IUD was inserted at my public health provider very soon after my C-section and didn’t protect me for even six months, and it caused this situation that I will never forget.

Anonymous, Bolivia

Age: 30, October 2025

In a country where choice is denied, discovering support reaffirmed the belief in personal freedom.

It was amazing to know that even in a country where we are told we have no choice, there are people out there that still believe in a persons right to choose what to do with their life. Keep up the great work!

Anonymous, Kọ́stà Rikà

Age: 29, May 2025

I am very grateful to them. Be sure that they will take good care of you, no matter where you are. You are the one to decide, but you will never be alone.

Fear was the first feeling I had when I found out I was pregnant. But after I contacted safe2choose, they made me feel safe and confident that they would guide me through the process. The process was very private and easy, and the counselors truly gave me the attention I needed. I am very grateful to them. Be sure that they will take good care of you, no matter where you are. You are the one to decide, but you will never be alone.

Anonymous, Mẹ́ksíkò

Age: 28, July 2024

0/0

KÀN SÍ WA.

Ó Dára láti Béèrè fún Àtìlẹ́yìn.

Tí o kò bá rí ohun tí o ń wá tàbí o nílò àtìlẹ́yìn síwájú sii, jọ̀wọ́ kàn sí wa nípasẹ̀ ojú-ewé ìmọ̀ràn àti àwọn ìkànnì tí ó wà. A lè dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ nipa oyún, àwọn àṣàyàn ìṣẹ́yún, tàbí ìtọ́jú ìṣẹ́yún - kàn sí wa!

Nípasẹ̀ ẹgbẹ́ safe2choose àti àwọn amòye alátìlẹ́yìn ní carafem, lórí Ìtọ́sọ́nà Ìtọ́jú Ìṣẹ́yún ti 2022 nípasẹ̀ WHO, Àwọn ìmúdójúìwọ̀n Ilé-ìwòsàn 2023 ní Ìlèra Ìbísí nípasẹ̀ Ipas, àti Àwọn Ìtọ́sọ́nà Àfihàn Ilé-ìwòsàn 2024 fún Ìtọ́jú Ìṣẹ́yún nípasẹ̀ NAF.

safe2choose ní àtìlẹ́yìn nípasẹ̀ Ìgbìmọ̀ Ìmọ̀ràn Ìṣègùn tí a ṣẹ̀dá nípasẹ̀ àwọn amòye asíwájú ní aayé ti ìlera ìbálòpọ̀ àti ìbísí àti àwọn ẹ̀tọ́ (SRHR).

carafem pèsè ìrọ̀rùn àti ìtọ́jú ìṣẹ́yún àti ìf’ètò s’ọ́mọ bíbí kí àwọn ènìyàn le ṣàkóso iye ati àlàfo láàrín àwọn ọmọ wọn.

Ipas jẹ́ àjọ àgbáyé tí ó gbájú mọ́ fífi ànfààní sí ìṣẹ́yún aláìléwu àti ìtọ́jú ìdènà ìbímọ.

WHO - Àjọ Ìlera Àgbáyé - jẹ́ ilé-iṣẹ́ àkànṣe Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ ojúṣe fún ìlera gbogbo ènìyàn àgbáyé.

NAF - National Abortion Federation - jẹ́ ẹgbẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ní USA tí ó ń ṣe àtìlẹ́yìn fún ìtọ́jú ìṣẹ́yún tí ó ní ààbò, tó dá lórí ẹ̀rí àti ẹ̀tọ́ ìbímọ.