safe2choose

Ẹrọ ìṣirò Oyún

Ní kété tí wọ́n bá ti fì̀dí oyún náà múlẹ̀ àti kí ó tó ṣe ìpinnu kankan nípa ìṣẹ́yún, ó ṣe pàtàkì láti mọ ọjọ́ orí oyún - iye ìgbà oyún náà ní ọ̀sẹ̀.

A wà níbí láti ṣe àtilẹyìn fún ọ ní gbogbo ìlànà yíì.

Ní safe2choose, a pèsè àlàyé tó péye àti àtìlẹ́yìn láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ kí o le la ìrìn àjò ìsẹ́yún rẹ kọjá. Àwọn ohun èlò wa wà láti fún ọ ní agbára pẹ̀lú ìmọ̀ àti ìgboyà tí o nílò láti ṣe àsàyàn tí o ́dára jùlọ fún ipò rẹ.

Ìdí tí ìfídí-múlẹ̀ oyún àti ọjọ́ orí oyún ṣe pàtàkì

Bóyá o bá pinnu láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú oyún rẹ tàbí o fẹ́ fòpin si, ìfídí-múlẹ̀ iye ìgbà tí oyun náà jẹ́ ṣe pàtàkì gan-an fún àwọn ìdí wọ̀nyí:

Illustration of hands holding a positive pregnancy test with two lines. The background is light blue, evoking a feeling of surprise or anticipation.
Light blue square with white checkmark and turquoise hand icon pointing at it, symbolizing making informed decisions.

O lè ṣe àwọn ipinnu tó dá lórí ìmọ̀ tó péye.

Ìfídí-múlẹ̀ oyún rẹ àti ìmọ̀ iye ìgbà tí o ti lọ nínú oyun ma ràn ọ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó dá lórí ìmọ̀ tó péye àti láti ṣe ètò bó ṣe yẹ.

Light blue heart icon with a darker blue medical cross overlay, symbolizing safety, health, and medical assistance.

Ààbò àti ìlera

Àwọn oríṣìíríṣìí ọ̀na ìṣẹ́yún ni a ṣàpèjúwe fún àwọn oríṣìíríṣìí ìpele ti oyún. Mìí mọ iye ọ̀sẹ̀ ti oyún yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ mọ ọ̀nà tí ó ní aàbò tí ó sì múnádóko jùlọ láti lò.

Light blue house icon with white checkmark and smaller teal speech bubble with lines, representing legalities and local accessibility.

Àwọn òfin àti wíwọlé ti agbegbè

Ànfààní ìṣẹ́yún kò wà bákan náà kárí ayé. Ní àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn agbègbè kan, wọ́n gba ìṣẹ́yún láàyè ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdiwọ̀n lórí ọjọ́ orí oyún nàá, àti pé àwọn ọ̀nà kan ní ó wà fún àwọn ọ̀sẹ̀ kan nínú óyún.

Chat icon with heart symbol representing safe abortion guidance, emphasizing that accurate information helps reduce anxiety and prepares emotionally.

Ìlera ọkàn àti ìmúrasílẹ̀ ní ìmòlára.

Níní ìmọ̀ tó péye ṣe ìrànlọ́wọ́ láti dínkù ìbànújẹ àti láti mú o wà ní ìgbáradì fún àwon ìgbésẹ̀ tó kàn ní ìmólara rẹ.

NB: Fìdí oyún rẹ múlẹ̀ pẹ̀lú àyẹ̀wò oyún tó dájú.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpàdánù osù rẹ jẹ́ àmì oyún, àwọn ohun mìíràn, yàtọ̀ sí oyún, lè mú kí osù rẹ pẹ́ tàbí ki o pàdánù rẹ. Ìdí nì yíì tí o fi yẹ kí o jẹ́risí oyún pẹ̀lu àyẹ̀wò oyún tí o gbẹ́kẹ̀lé ṣáájú lílo ìṣirò oyún. Àyẹwò oyún ní ilé tàbí ìbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ olupesè ìtọ́jú ìlera rẹ le fún ọ ní àlàyé tó pé tí o nílò.

Kò yẹ kí o kọ́ lo àwọn òògùn ìṣẹ́yún tí o kò bá tì jẹ́risí oyún náà pẹ̀lu àyẹ̀wò tí o gbẹ́kẹ̀lé àti pé ko mọ iye ìgbà tí oyún náà jẹ́.

Illustration in three parts showing a urine test in a hand, a gloved hand holding a blood test, and another gloved hand holding an ultrasound device.
Ìfídí-múlẹ̀ oyún ní kíákíá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti ṣe àwọn ìgbésẹ̀ tó tọ́ fún ìlera rẹ àti láti ṣàwárí àwọn àṣàyàn rẹ.

Mọ ìsirò iye ìgbà tí oyún rẹ jẹ́

Láti ṣírò iye ọ̀sẹ̀ tí oyún jẹ́, ka iye ọ̀sẹ̀ àti ọjọ́ láti ọjọ́ àkọ́kọ́ ìbẹ̀rẹ̀ oṣù rẹ tó kẹ́yìn (LMP). Ó ṣe pàtàkì láti bẹ̀rẹ̀ kíkà láti ọjọ́ yẹn torí pé yí ó ràn é lọ́wọ́ láti ṣe àṣàrò ìgbà tí ẹyin náà ti jáde àti ìdàpọ̀.

A hand holding a cellphone displaying a menstrual tracker, illustrating period tracking and reproductive health monitoring.

Ọ̀nà tó dáa jùlọ láti mọ iye ìgbà tí oyún jẹ́:

Mọ ọjọ́ náà gangan tí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù rẹ tó kẹ́yìn bẹ̀rẹ̀;

Ṣe àṣàrò ọjọ́ tó súnmọ́ jùlọ tí o bá rántí ọjọ́ tí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù rẹ tó kẹ́yìn bẹ̀rẹ̀,

Lò ọ̀nà míìràn ti o bá rántí oṣù náà tàbí bóyá ó jẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ tàbí ìparí oṣù náà.

Se àfíyèsí pẹ̀lú àwọn àsise tí ó wọ́pọ̀ wònyí; má se ìṣirò nípa

kíkà láti ìgbà tí o pàdánù osù rẹ;

kíkà láti ọjọ́ tí o se ìbálòpọ̀; àti

kíkà láti ọjọ́ tí o rò pé o ti lóyún

Ẹ̀rọ ìṣirò Oyún

Tí o bá nílò ìrànwọ́ láti ṣe ìṣirò àwọn ọ̀sẹ̀ oyún, lo irinṣẹ́ ìṣirò oyún wa. Yan ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù rẹ tó kẹ́yìn bẹ̀rẹ̀, kí o bẹ̀rẹ̀

Bí o ṣe le lo ẹ̀rọ ìṣirò oyún.

Yíyan àwọn ọ̀nà ìṣẹ́yún gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí oyún.

0

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà aláìléwu ló wà láti ṣẹ́yún, àti pé ọ̀nà tí o yàn sábà máa ń dá lórí iye ọ̀sẹ̀ tí oyún náà jẹ́. Nígbà míràn, a lèé lo àwọn ọ̀nà oríṣìíríṣìí ní àwọn àkókò kańnà ní oyún kan. Àṣàyàn rẹ lè dá lórí ibi tí ò ń gbé, àwọn irinṣẹ́ tàbí ohun èlò tí ó wà, àti ohun tí o fẹ́ tàbí ti dókítà rẹ dábàá.

Oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìṣẹ́yún ni o wà ní ìbámu pẹ̀lú ọjọ́ orí oyún:

Three circles on light background, two large light blue overlapping and a smaller dark blue above, representing safe medical abortion at home below 13 weeks.

Ìṣẹ́yún pẹ̀lú òògùn tàbí ìṣẹ́yún ìṣègùn (MA)

Ìṣẹ́yún pẹ̀lú òògùn tàbí ìṣẹ́yún ìṣègùn (MA) lè di ṣíṣe láìléwu nílé tí kò tó ọ̀sẹ̀ 13 lóyún. Fún àwọn oyún tó ju ọ̀sẹ̀ mẹ́tàlá 13 lọ,ó nílò àkíyèsi pàtàkì àti àwọn ìṣọ́ra, àti pé a dábàá pé kí a ṣe ìṣẹ́yún náà ní ilé-ìwòsàn kan.

Stylized blue fire hydrant icon representing Manual Vacuum Aspiration (MVA), a safe abortion method for pregnancies up to 14 weeks.

Ìfẹ́ òfo pèlú ọwọ́ (MVA)

Ìfẹ́ òfo pèlú ọwọ́ (MVA) jẹ́ irú ìfọ̀sún inú ile ọmọ ni ọsẹ̀ kẹrìnlá 14 ti oyun. Onímọ̀ ìlera tí ó kọ́sẹ́mọsẹ́ ni yíò se ní ilé ìwòsàn tàbí ibi ìṣègùn.

Teal fire hydrant icon tilted right on light blue background, symbolizing Electric Vacuum Aspiration (EVA) abortion method.

Ẹ̀rọ afọ́fẹ́ eléẹ̀kùtrónìkì (EVA)

Ẹ̀rọ afọ́fẹ́ eléẹ̀kùtrónìkì (EVA) jẹ́ irú ìfọ̀sún inú ile ọmọ ni ọ̀sẹ̀ márùndínlógún 15 ti oyun. Onímọ̀ ìlera tí ó kọ́sẹ́mọsẹ́ ni yíò se ní ilé ìwòsàn tàbí ibi ìṣègùn.

Icon representing dilation and evacuation (D&E) abortion procedure

Ìṣí ìlà ilé ọmọ àti ìyọkúrò (D&E)

Ìṣí ìlà ilé ọmọ àti ìyọkúrò (D&E) ni a máa ń lo lẹ́yìn ọsẹ̀ kẹrìnlá 14 ti oyun. Onímọ̀ ìlera tí ó kọ́sẹ́mọsẹ́ ni yíò se ní ilé ìwòsàn tàbí ibi ìṣègùn.

Dark teal engine with wires icon on light blue background, representing Dilation and Evacuation (D&E) second-trimester abortion method.

Ìmúlẹ̀ oyún

Ìmúlẹ̀ oyún, nígbà tí wọ́n bá lò ó, ni wọ́n sábà máa ń ṣe fún oyún ti o kọjá ọ̀sẹ̀ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n 16 láti ọwọ́ òṣìṣẹ́ ìtọ́jú ìlera tó mọṣẹ́ ní ilé ìwòsàn tàbí ibi ìṣègùn.

OUTDATED
Syringe and medicine vial icon on light blue background, representing induction abortion used in second and third trimester pregnancies.

Dilation àti curettage (D&C)

Dilation àti curettage (D&C) jẹ́ ọ̀nà ìṣẹ́yún tí kò bá ìgbà mu tí wọ́n sì ti rọ́pò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀nà ìfẹ́ inú ọmọ (MVA/EVA) àti ìyípadà àti yíyọ kúrò (1) (5). Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlànà yìí ṣì wà ní ṣíṣe kárí ayé, a dábàá lílo àwọn ọ̀nà ààbò míràn.

Àwọn ìbéèrè tí wọ́n máa ń béèrè lọ́pọ̀ ìgbà lórí ẹ̀rọ ìṣirò oyún

Ẹ̀rọ ìṣirò oyún lè fún ọ ní àròpọ̀ iye ìgbà tí o ti lóyun, ṣùgbọ́n kì í péye ní gbogbo ìgbà. Ó máa ń siṣẹ́ dáradára tí o bá fi àlàyé tó péye sínú rẹ̀, bíi ọjọ́ àkọ́kọ́ tó o rí nǹkan oṣù rẹ kẹ́yìn. Tó bá jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà lo máa ń rí nǹkan oṣù tàbí tó ò mọ̀ bóyá ó máa ń bọ́ sí àkókò kan pàtó, àbájáde rẹ̀ le máa ṣeé gbára lé. Síbẹ̀, ó lè jẹ́ kó o mọ bí oyún tó o ní ṣe jìnnà tó, èyí á sì jẹ́ kó o mọ ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà ṣe ìṣẹ́yún. Tí kò bá dá ẹ lójú, ó máa dáa kó o wá àwọn ọ̀nà míì tó o lè gbà mọ iye ọjọ́ orí oyún rẹ. Jọ̀wọ́ kàn sí wa fún ìrànlọ́wọ́.

Illustration of a thoughtful woman with long hair, wearing a floral yellow top and blue pants. She touches her chin, next to a speech bubble with a question mark.

Gba alàyé ní safe2choose

Màa tẹ̀síwájú pẹ̀lú àwọn ìdàgbàsókè tuntun, ìròyìn, àti àlàyé pẹ̀lú safe2choose. Láti àwọn ìlọsíwájú nínú ìlera ìbímọ sí àwọn ìkìlọ̀ pàtàkì àti àwọn ìtàn láti inú àwùjọ wa, Ojú-ìwé Àwọn Àròkọ wa máa ń jẹ́ kí o mọ gbogbo àlàyé tuntun àti ìfaramọ́ pẹ̀lú àlàyé tuntun.

Kàn si wa.

Ó dára láti bèèrè fún àtìlẹ́yìn.

Tí o kò ba ri ohun tí ò ń wá tàbí o nílò àtilẹyìn síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn si wa nípasẹ̀ ojú-ìwé ìmọ̀ràn àti àwọn ìkànnì tí ó wà. A lè ṣe àtìlẹ́yìn fún ọ pẹ̀lú àwọn ìbéèrè rẹ nípa oyún, àṣàyàn ìṣẹ́yún, tàbí ìtọ́jú lẹ́yìn ìṣẹ́yún - kàn sí wa!