Rírí àtìlẹyìn Ìgbaninímọ̀ràn ní ìgbà tí ó bá fẹ́ sẹ́yún

Abortion Counseling

Nítorí pé àwọn èèyàn máa ń tàbùkù oyún ṣíṣẹ́, ó máa ń nira láti béèrè fún àlàyé tí o fẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàyé ti kò fẹsẹ̀múlẹ̀ ni ó sì gbòde kan. Àwọn olùdáninímọ̀ràn wà tí ó pegedé nínú ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó wà nílẹ̀ láti ọjọ́ ajé sí ọjọ́ ẹtì láti pèsè àkọ̀tun àlàyé kíkún yálà ní orí méèlì tàbí láti fọ̀rọ̀wérọ̀ lójúkorojú lórí ẹ̀rọ ayélujára láti lè ríi dájú pé ewukéwu ò kàn ọ́.

email counseling icon

Ìdáninímọ̀ràn orí méèlì

Ó lè fi méèlì ránṣẹ́ sí wa lórí info@safe2choose.org nígbàkigbà. Àwọn olùgbaninímọ̀ràn wa máa ń ṣíṣẹ́ láti ọjọ́ ajé títí di ọjọ́ ẹtì, wọn ó sì dá ọ lóhùn ní kíákíá.

FI MÉÈLÌ RÁNṢẸ́ SÍWA


live chat counseling icon

Ìdáninímọ̀ràn pẹ̀lú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí ayélujára

Tí ó bá wù ọ́ láti fọ̀rọ̀wérọ̀ lórí oyún ṣíṣẹ́ rẹ kí o sì rí àtìlẹyìn fún ètò yìí, àwọn olùgbaninímọ̀ràn wà wà nílẹ̀ láti ọjọ́ ajé títí di ọjọ́ etì. Àpèrè wa wà káríayé, a sì ní àwọn olùgbaninímọ̀ràn ní agbègbè àkókò tí ó yàtọ̀. Nítorí náà, àsìkò ìdáhùn yóò yàtọ̀. Tí àwọn olùgbaninímọ̀ràn wa ò bá sí ní orí ẹ̀rọ ayélujára ní àsìkò tí ó fẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀, jọ̀wọ́ gbìyànjú nígbà mìíràn tàbí kí o fi méèlì sọwọ́ sí info@safe2choose.org. A ó dáhùn gbogbo ìbéèrè

BẸ̀RẸ̀ ÌFỌ̀RỌ̀WÉRỌ̀


chatbot counseling icon

Ìdáninímọ̀ràn pẹ̀lú ẹ̀rọ ìfọ̀rọ̀wérọ̀

A ti ṣe àgbékalẹ̀ ẹ̀rọ tí yóò ṣe ìtọ́sọ́nà fún ọ nípa lílo àpèrè wa lórí ẹ̀rọ ayélujára tí yóò sì bi ọ́ ní àwọn ìbéèrè tí ó yẹ láti mọ ipò rẹ kí o tó bá olùgbaninímọ̀ràn sọ̀rọ̀. Ẹ̀rọ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wa máa ń ṣe àtìlẹyìn nípa dídáhùn àwọn ìbéèrè rẹ nígbà tí a ò bá sí lórí afẹ́fẹ́. Tí o bá sì fẹ́ bá èèyàn sọ̀rọ̀, jọ̀wọ́ lo ẹ̀ya ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí ayélujára wa ní àsìkò mìíràn tàbí kí ó fi méèlì ṣọwọ́ sí info@safe2choose.org.

BÁ Ẹ̀RỌ ÌFỌ̀RỌ̀WÉRỌ̀ WA SỌ̀RỌ̀

Kí ni àwọn olùgbaninímọ̀ràn Safe2choose máa ń ṣe?

Ó máa ń nira fún àwọn obìnrin láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣẹ́yún nítorí bíótilẹ̀jẹ́pé ìdámẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún (25%) oyún ní wọ́n máa ń ṣẹ́ ní àgbáyé, àwọn èèyàn ṣì máa ń tàbùkù oyún ṣíṣẹ́. A wà ní sẹpẹ́ nígbà gbogbo láti tọ ọ sọ́nà láti lè yan ìlànà tí ó dára jù fún ọ àti láti bá ọ gbaradì fún ìlànà kílànà tí o bá yàn.

Ṣiṣẹ́ oyún ni ọ̀nà tí kò béwu dé lè fẹ́ pin ni lẹ́mìí tàbí kí ó fẹ́ dojú rú. Ìdáninímọ̀ràn oyún ṣíṣẹ́ yóò gbà ọ́ láyé láti mọ onírúurú ìlànà tí ó lè lò. Àwọn olùgbaninímọ̀ràn wa yóò tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ, wọn yóò sì ṣe àlàyé tí ó bá ipò rẹ mu fún ọ kí o lè baà lè yan ìlànà tí ó dára jù fún ọ.

Níní àtìlẹyìn àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ obìnrin tí ó jẹ́ aláàánú àti olùtọ́jú yóò dín ìmọ̀lára ìdánìkanwà kù, a ó sì fún ọ ní ìtọ́jú àti àkíyèsí tí o nílò láì pẹ̀gàn rẹ.

Ìtọ́kasí àwọn alábáṣepọ̀ wa tí ó wà nílẹ̀

Ní àwọn ìgbà kan, àwọn obìnrin ó lè ṣẹ́yún nílé fúnra rẹ̀, wọn yóò sì lè rí àwọn òògùn ìṣẹ́yún. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, wọn yóò nílò ìdáninímọ̀ràn oyún ṣíṣẹ́ kí wọ́n tó lè rí òògùn tàbí kí wọ́n tó lè rí ìtọ́kasí sí ọ̀dọ̀ olùtọ́jú fún oyún ṣíṣẹ́ ní ilé ìwòsàn tàbí ìtọ́jú lẹ́yìn oyún ṣíṣẹ́.

Ní àwọn irú ìgbà báyìí, àwọn ẹ̀ka wa tí ò ń ṣiṣẹ́ lórí ìbániṣiṣẹ́pọ̀ máa ń ṣiṣẹ́ kárakára láti fi orúkọ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ olùtọ́jú tí ó ṣe é fọkàn tán sínú àkójọpọ̀ détà alárokò. A máa ń ẹẹ̀lé ìlànà tí ó ga kí a tó lè gba àwọn olùtọ́jú tuntun yìí kí á ba à lè ríi dájú pé àwọn obìnrin tí a bá tọ́ka sí wọn kò ní rí ìpalára kankan tí wọn yóò sì pàtàkì àpọ́nlẹ́, ìfọ̀rọ̀roraẹniwò àti ìtọ́jú tí ó péye tí a mọ̀ pé ó tọ́ sí gbogbo obìnrin.

Àwọn olùdáninímọ̀ràn wa

Abortion Counseling team

Àwọn olùdáninímọ̀ràn wa jẹ́ àwọn obìnrin akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nínú ìṣègùn òyìnbó, wọ́n sì wà níkàlẹ̀ nígbà gbogbo láti dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ. Láti baà lè gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn tí ó bá àgbègbè rẹ mu, a máa ń bá àwọn olùgbaninímọ̀ràn tí ó wà ní àwọn ìlú tí ó wà ní oríṣiríṣi kọ́ńtínẹ́ńtì ṣiṣẹ́. A fẹ́ ríi dájú pé a lè dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin lóhùn ìbéèrè wọn pẹ̀lú èdè tí wọ́n ń sọ, àwọn olùgbaninímọ̀ràn wa sì ń sọ ju èdè mẹ́wàá lọ: èdè Gẹ̀ẹ́sì, Faransé, Spanish, Potogí, Hindi, Punjabi, Lárúbáwá, Hebrew, Kiswahili àti Wolof.

Àwọn olùgbaninímọ̀ràn wa sì tún máa ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àtìgbàdégbà láti kọ́ àwọn ohun tí yóò mú kí ìmọ̀ràn wọn túbọ̀ dára síi, láti mọ àwọn mọ̀ nǹkan tuntun nípa ìwádìí lórí àwọn ìlànà oyún ṣíṣẹ́ àti àwọn ìlànà náà, àti láti lè mọ ohun tí wọn yóò ṣe tí nǹkan bá fẹ́ lọ́jú pọ.

Gbogbo ohun tí ó bá sọ fún wa ni ó jẹ́ àṣírí, gbogbo ọ̀rọ̀ tí a bá sì sọ ni a ó parẹ́ ní kété tí o kò bá nílò ìrànlọ́wọ́ wa mọ́.