Ṣe àṣàrò ọsẹ ìdáhùn oyun:
Mímọ iye ọsẹ tí o ti lọ nínú oyun rẹ jẹ pàtàkì nítorí pé ó ní ipa lórí àwọn ọnà tí a lè gba ṣíṣe oyun. Sise isiro ose oyun rorun, ìyẹn ni safe2choose ti ṣẹdá Irìnṣẹ Ìṣirò Ọjọ Ìbí tó dájú láti lò.
A á mọ pé idojuko oyun ti a ko seto fun jẹ nkan tó lè fa ìdààmú àti àníyàn púpọ. Ní safe2choose, a fúnni ní ìròyìn àti ìtìlẹyìn tó peye láti ràn ẹ lọ ní irin ajo iseyun re. Àwọn ohun elo wa wa láti fún ọ ní ọgbọn àti igboya tó peye láti ṣe ipinnu tó dára jù fún ipo rẹ.
AWON IPINNU TO DA LORI IMO
Ìmòye nípa àwọn ìpele oyun àti àwọn àṣàyàn tó wà, pẹlú ìṣẹyún ṣe pàtàkì jùlọ láti ṣe àwọn ìpinnu tó ni imọ nípa ìlera ẹyà ara rẹ.
safe2choose ko se idaniloju lilo oogun iseyun lai se pe, o ti se ayewo oyun pelu ayewo ti o se gbekele, o si ti mo bi oyun naa ti dagba si.
Ààmi oyun lè yàtọ láti ọdọ ẹni kan sí elòmíràn, kò sì dajú pe yóò ṣèlẹ nígbà kan náà tàbí pẹlú agbara tó dọgba. Eyi ni àwọn ààmi ìbẹrẹ oyun tó wọpọ tí ó yẹ kó wà ní ìrántí bí ẹ bá fura pé ẹ lè jẹ ẹni tó lóyun:
Rántí pé àwọn ààmì wọnyí lè jẹ fún àwọn ìdí míràn, bí àwọn àrùn tàbí ǹkan oṣù tí ńbọ. Ẹ lè jẹ ẹni tó lóyun láìní gbogbo àwọn ààmì wọnyí tàbí láìsí wọn rárá.
Bí ọjọ tí ẹ n reti nkan osu re bá kọjá ọsẹ kan tàbí ju bẹẹ lọ, o lè lóyun. Ṣùgbọn àwọn iṣoro ìlera tàbí àwọn nkan osu ti ko se deedee lè jẹ ìdí náà.
Ìríra ní omu: Àwọn ìyípadà nínu homoni ní ìbẹrẹ oyun lè mú kí omu rẹ wú ki o si kán.
Ẹ lè ní Ìfarapa inu pẹlú tàbí láìsí ìrunu, tí wọn sábà máa ń pè ní aisan òwúrò, tí ó sábà ń bẹrẹ ní oṣù kan tàbí méjì lẹyìn ti o ba loyun.
Ẹ lè fe too ju bo se ye lo
ko ma re ni tàbí àìlera èyíkéyìí lè jẹ ààmi ìbẹrẹ oyun.
Tí ẹ kò bá rí nkan osu yín,ti e si ri àwọn ààmi wọnyí ṣe ìdánwò oyun lẹyìn ọsẹ méjì ìbálòpọ láìsí ìdábòbò láti mọ esi to peye júlo.
Nkan osu ti ko wa jẹ ọkan nínú àwọn ààmi ìbẹrẹ oyun tó wọpọ. Ṣùgbọn, Nkan osu ti ko wa tàbí tí ó péjú le ṣẹlẹ fún ọpọ ìdí àìmọ, yàtọ sí oyun.
Diẹ nínú àwọn àṣàyàn tó lè fa aisedede Nkan osu ni:
Aisun
Ailera oorun
Àìlera ìjẹun
Ìyípadà àwọn ara (padà tàbí gíga)
Ìdààmú tàbí iṣẹlẹ tó fa ifarapa
Àyípadà nínú ìdíje ojoojúmọ
Lílò ìmúlò òògùn
Ìbánilẹrọ homoni
Àwọn àìlera ìlera tó wà
Lílò ìdábòbò pajawiri (Oogun ìpalẹmọọmọ òwúrò).
Àwọn ìdí wọnyí lè yàtọ láti àwọn iyípadà homoni tó kéré sí àwọn ìṣòro ìlera tó pọ. Nítorí náà, ó ṣeé pataki kí o ṣe ìdánwò oyun láti jẹ kó dájú pé o ní oyún tàbí o kò ní.
Bí ẹ bá ní amenorrhea, tí ó túmọ sí airi Nkan osu fún oṣù mẹta tàbí ju bẹẹ lọ, a gba o nimoran kí o tọjú ìlera rẹ, kí o sì lọ bá onímọ ìlera rẹ fún ìtọju ìlera.
ÀYẸWÒ OYÚN TÓ ṢE GBẸKẸLÉ
Ìmọ nípa bí o ṣe lè jẹ ẹni tó lóyun láìpẹ ràn é lowo láti tọjú ìlera rẹ àti láti ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Kí o tó tẹsíwájú, ó ṣe pàtàkì láti fìdí rẹ múlẹ pé o ní oyun pẹlú ayewo tó se gbẹkẹlé.
Ẹ lè ṣe ayewo oyun ní ilé, tó o lè rà ní ile elegbogi, ilé ìtajà, tàbí ní ilé ìwòsàn, tàbí ẹ lè lọ sí odo dókítà fún ayewo tó péye jù lọ.
Ẹ lè ti gbọ nípa àwọn ayewo oyun tí a ṣe ní ilé tó lò àwọn ohun tó dájú bíi ọti kikan, shampulu, tàbí bilisi, ṣùgbọn àwọn ayewo wọnyí kò se gbẹkẹlé.
Èèyàn lè ṣe ayewo ilé tí kò bá lè ra ti elegbogi, tí kò fẹ kí ẹlòmíràn mọ pé ó ń ṣe ayewo, tàbí tí kò sì lè dúró de ayewo tó peye. Awon eniyan sọ pé ayewo ilé yìí ń ṣiṣẹ nípa ìbáṣepọ kemikali tó wà láàárín àwọn ohun elo náà àti homoni tó ń jẹ hCG,
ti ara rẹ ń ṣe nígbà tí o bá lóyun Ṣùgbọn, kò sí ẹrí tó dájú pé àwọn ayewo wọnyí ń ṣiṣẹ.
Ọnà tó dájú jùlọ láti mọ pé o ní oyun ni láti se ayewo oyun gidi, bíi ayewo ẹjẹ tàbí ayewo ito.
Àwọn ọnà mẹta tó ṣe gbẹkẹlé ló wà láti fìdí oyun múlẹ. Nípa ìpinnu rẹ, o lè fẹ ọkan nínú wọn ju mìíràn lọ.
Ayewo ito jẹ ọnà tó wọpọ àti tó gbooro láti fìdí oyun múlẹ. Ayewo ito ń ṣàyẹwò ìfarahàn homoni oyun nínú ito. Ó rọọrun láti lò. Ó ṣe pàtàkì kí o rántí pé gbogbo Ayewo ito fún oyun ní àkókò pàtàkì tí wọn yẹ kí a ka wọn. Fún púpọ nínú wọn, ó jẹ ìsẹjú mẹta sí márùn-ún. Bí wọn bá joko fún wákàtí, wọn lè fi abajade àìtọ han, nítori náà ó dájú pé kí o wo "àkókò kìka" lórí kítì àwọn ayewo oyun kí o sì kà wọn ní àkókò tí o dájú.
Benefits
Àṣàyàn ti ko ni idiyele àti tó rọrùn láti rí. A sábà máa ń ta Irú Ayewo ito yìí nínú kítì tí ó wà ní ilé ìwòsàn tó wà nítòsí rẹ.
Abajade náà jẹ lẹsẹkẹsẹ. Ó máa gba ìsẹjú diẹ láti ní abajade ayewo.
Ó fúnni ní abajade tó rọrùn, tó je beeni, tàbí beekọ.
Àwọn ayewo wọnyí sábà máa ń jẹ pé o lè lò wọn láìsí ìṣòro, Ka gbogbo ìtọsọnà nígbà tí o bá ṣí kítì náà.
O le se ni ikoko ninu ile
Disadvantages
Ọpọ Ayewo ito kò ràn é lọ wo láti ṣe iṣiro iye ọsẹ oyun.
Diẹ nínú ayewo ito lè fi ìṣirò ọsẹ oyun hàn, ṣùgbọn èyí kì í ṣe abajade tó se gbẹkẹlé jùlọ. A gba o ni yanju pé kí o ṣe iṣiro ọjọ ori oyun rẹ nípasẹ ìṣirò ọsẹ láti ọjọ tí o ṣe nkan osu tó re kẹhìn tàbí láti lò ero isiro oyun wa fún iṣirò to rọrùn.
O lè ní abajade àìtọ (àbájáde tó jẹ "àìlẹmọ") bí a kò bá lò ó dáadáa. Látàrí ìdí yìí, a gba o ni yanju pé kí o ṣe ìdánwò yìí ní ọsẹ méjì tàbí ju bẹẹ lọ lẹyìn ìbálòpọ láìsí ìdábòbò.
Nígbà tí oyun bá ṣẹlẹ, àwọn ẹyà ara máa ń ṣe homoni kan tí a ń pè ní HCG, èyí ni homoni tí a lè rí nínú ìdánwò omi ẹjẹ tàbí ẹjẹ. Nípa mímú èyí pé homoni oyun lè gba ọsẹ méjì káàkiri láti farahàn nínú ara, fún abajade tó péye, ó ṣe pàtàkì láti ṣe:
Ayewo ito: Ṣe ní ọsẹ méjì lẹyìn ìbálòpọ láìsí ìdábòbò tàbí ọsẹ kini si keji lẹyìn tí ìgbàwọ rẹ bá jẹ ní ìdádúró. Ìdánwò ṣáájú àkókò yìí lè fi han abajade àìtọ.
Ayewo ẹjẹ: A lè ṣe é ní ẹkùnrérẹ ní àkókò tó kù díẹ, tí ó sì máa jẹ abajade tó dájú.
Nípa Ayewo (ultrasound), ó sábà máa ń dára kí a ṣe é lẹyìn ọsẹ mẹrin tàbí sí i.Nítorí pé ṣáájú ọsẹ mẹrin, ó lè má rorun láti rí oyun tàbí mọ bí ó ṣe ń lọ. Bí a bá ṣe ultrasound ní àkókò tó ya jú, ó lè fi àìdánilójú han nítorí pé kò ní fi nkankan hàn.
Ṣíṣàbẹwò sí oyun tí ẹni kì í fẹ lè jẹ àkókò tí ó nira àti ìbáwí lọnà kan, ṣùgbọn ó ṣe pàtàkì láti mọ pé o ní àṣàyàn. O lè yan láti tẹsíwájú pẹlú oyun kí o sì di òbí, tẹsíwájú pẹlú ètò fún ìtọka ọmọ, tàbí rò nípa ṣíṣe ìgbẹyàwó oyun (abortion). Gbogbo àṣàyàn yìí ní àwùjọ àti ìṣòro rẹ, tí ó sì lè ní ipa tó yatọ nígbéyìn rẹ, nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti yan ohun tó bá èrò rẹ lọ.
Bí o bá ń rò nípa ṣíṣe oyun, àwọn ìgbésẹ tó ṣe pàtàkì lẹyìn ìdájọ oyun ni wọnyí:
Nípa mímu àwọn ìgbésẹ wọnyí ṣe, o lè ní ìmọ tó dájú àti agbára láti pinnu ohun tó tọ jù fún ara rẹ.
Mímọ iye ọsẹ tí o ti lọ nínú oyun rẹ jẹ pàtàkì nítorí pé ó ní ipa lórí àwọn ọnà tí a lè gba ṣíṣe oyun. Sise isiro ose oyun rorun, ìyẹn ni safe2choose ti ṣẹdá Irìnṣẹ Ìṣirò Ọjọ Ìbí tó dájú láti lò.
Orisiirisii ona lo wa si iseyun,bi lilo oogun(oogun Iseyun) tabi sise ninu ile iwosan Ṣàwárí àwọn ọnà wọnyí àti bí o ṣe lè rí ìtọju Iseyun fún yíyan tó dara fún ara rẹ.
Ó tún ṣe pàtàkì láti mọ àwọn ètò òfin nípa Iseyun níbi tí o ń gbé, nítorí pé ó lè yàtọ níbikíbi.
Olutirasandi ko nilo lẹhin iṣẹyun oogun kan. Lakoko ti o le jẹri nigbakan pe ilana naa ṣaṣeyọri, nigbati o ba ṣe ni kutukutu, o tun le ṣafihan ẹjẹ tabi àsopọ ninu ile-ile, eyiti o jẹ deede ni awọn ọsẹ diẹ akọkọ. Diẹ ninu awọn olupese ilera le daba awọn ilana afikun, gẹgẹbi afẹfẹ igbale (MVA) tabi curettage (D&C), ti o da lori eyi, paapaa ti wọn ko ba wulo.
Olutirasandi jẹ pataki nikan ti awọn ami ti awọn ilolu ba wa, gẹgẹbi ẹjẹ ti o wuwo tabi ikolu, tabi ti ibakcdun ba wa pe ilana naa kuna. Ti ohun gbogbo ba lọ bi o ti ṣe yẹ, ọna ti o rọrun julọ lati jẹrisi iṣẹyun naa jẹ aṣeyọri ni nipa gbigbe idanwo oyun ile ni bii ọsẹ mẹrin si marun lẹhin lilo awọn oogun naa.
Àwọn ìròyìn tuntun àti àwọn àròkọ búlọ̀ọ̀gì tuntun
Màa tẹ̀síwájú pẹ̀lú àwọn ìdàgbàsókè tuntun, ìròyìn, àti àlàyé pẹ̀lú safe2choose. Láti àwọn ìlọsíwájú nínú ìlera ìbímọ sí àwọn ìkìlọ̀ pàtàkì àti àwọn ìtàn láti inú àwùjọ wa, Ojú-ìwé Àwọn Àròkọ wa máa ń jẹ́ kí o mọ gbogbo àlàyé tuntun àti ìfaramọ́ pẹ̀lú àlàyé tuntun.
Àtìlẹyìn Ìmòràn Ìṣéyún ailewu
A ń pèsè ìròyìn tó dá lórí ẹrí nípa ìṣéyún tó dáàbò bò. Ìṣẹ ìmòràn wa tó ṣàdédé jẹ ẹni kìíní, aládàbò, rọrùn, àti láìsí ìdájọ. A ń dúró de ìfiranṣẹ rẹ!

Nipasẹ ẹgbẹ safe2choose ati awọn amoye atilẹyin ni carafem, da lori Itọsọna Itọju Ìṣẹyún 2022 nipasẹ WHO, Awọn imudojuiwọn Ile-iwosan 2023 ni Ilera Ibisi nipasẹ Ipas, ati Awọn Itọsọna Afihan Ile-iwosan 2024 fun Itọju Abortion nipasẹ NAF.
safe2choose ni atilẹyin nipasẹ Igbimọ Imọran Iṣoogun ti a ṣẹda nipasẹ awọn amoye asiwaju ni aaye ti ilera ibalopọ ati ilera ibisi ati awọn ẹtọ (SRHR).
carafem pèsè ìtọjú ìṣẹyún tí ó rọrùn tí ó sì jẹ akọṣẹmọṣẹ àti fetosomobibi kí àwọn ènìyàn lè ṣàkóso iye náà kí wọn sì fi aye saarin omo won.
Ipas jẹ àjọ àgbáyé tí ó gbájú mọ fífẹ ànfààní sí ìṣẹyún aláìléwu àti ìtọjú ìdènà ìbímọ.
WHO - Àjọ Ìlera Àgbáyé - jẹ ilé-iṣẹ àkànṣe Àjọ Ìparapọ Àwọn Orílẹ-èdè tí ó jẹ ojúṣe fún ìlera gbogbo ènìyàn àgbáyé.
NAF - National Abortion Federation - jẹ ẹgbẹ akọṣẹmọṣẹ ní USA tí ó ń ṣe àtìlẹyìn fún ìtọjú ìṣẹyún tí ó ní ààbò, tó dá lórí ẹrí àti ẹtọ ìbímọ.