Gbogbogbò
Safe2choose (safe2choose.org) ni ó ni tí ó sì ń ṣàkóso Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí. Ìwé yìí ń ṣàkóso ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ ìkápá náà safe2choose.org àti olùpèsè iṣẹ́ inú rẹ̀ (Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù). Wíwọlé sí àti lílo Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí àti àlàyé- àwọn àwòrán, ọ̀rọ̀ àti àwọn fídíò-, àti àwọn iṣẹ́ – pẹ̀lú ìmọ̀ràn ati ìmọ̀ràn orí afẹ́fẹ́ tí ó wà nípasẹ̀ Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí (làpapọ̀ èyítí à ń pè ní, àwọn iṣẹ́/àwọn iṣẹ́ ìgbaninímọ̀ràn) lórí Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí.
Nípa lílo àwọn ètò ìdáninímọ̀ràn wa lórí tàbí nípasẹ̀ Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí, ò ń fọwọ́ sí gbogbo àwọn ìlànà àti òfin tó rọ̀ mọ́ọ, èyítí a lè yípadà láti ìgbà dé ìgbà. Ó yẹ kí o ṣàyẹ̀wò ojú -ewé yìí láti ṣe àkíyèsí èyíkèyí àwọn ìyípadà tí a lè ṣe sí àwọn òfin ìṣe náà. Ó le má ṣeé ṣe fún wa láti fún ọ ní àkíyèsí sílẹ̀ nípa àyípadà tí a ṣe lórí Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí tàbí àwọn òfin àwọn ìṣe rẹ.
A ní ẹ̀tọ́ láti yọ kúrò tàbí láti tún àwọn ìṣe ṣe láìsí àkíyèsí. Òfin kò mú wa tí Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí kò bá ṣiṣẹ́ fún ìdí kan tàbí òmíràn. Láti ìgbà dé ìgbà, a lè má gbà ọ́ láàyè láti wọ àwọn ojú-ewé kan lórí tàbí gbogbo Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí lápapọ̀.
Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí le ní ìjápọ̀ si àwọn Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù míràn (“àwọn Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù tí a sopọ̀” náà), tí kò sí ní ìṣàkóso Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yii. Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí kò ní agbára lórí àwọn Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù tí a sopọ̀ náà, kò sì ṣe ìdúró fún wọn tàbí fún wàhálà tàbí ewu tí ó le jẹyọ tí o bá lò wọ́n. Ohun tí o bá lo àwọn Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù tí a sopọ̀ náà fún yóó wà lábẹ́ òfin àti ìlànà ìṣe Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù náà.
Ìlànà ìpamọ̀
Ìlànà ìpamọ̀ wa, èyítí ó so bí a ó ṣe lo ohun tí a mọ̀ nípa rẹ, ní a lè rí safe2choose.org/yo/privacy-policy. Nípa lílo Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí, o fọwọ́ síi pé kí á lo ohun tí a mọ̀ nípa rẹ o sì fún wa ní ìdánilójú wípé gbogbo ohun tí o sọ fún wa jẹ́ òtítọ́.
Àwọn olùdáninímọ̀ràn àti iṣẹ́ ìdáninímọ̀ràn
Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù náà gbà ọ́ láàyè láti bá àwọn olùgbani-ní-mọ̀ràn, àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ìlera àti àwọn oníṣẹ̀gùn tàbí ẹlòmíràn tí ó kójú òṣùwọ̀n (àwọn tí à ń pè ní olùgbani-ní-mọ̀ràn) láti pèsè ètò ìdáninímọ̀ràn, àlàyé àti ìmọ̀ràn lórí ìṣẹ́yún oníṣẹ̀gùn. Jọ̀wọ́ níi lọ́kàn pé ètò ìdáninímọ̀ràn yìi kìí ṣe ìmọ̀ràn oníṣẹ̀gùn tó dántọ́ tàbí ètò ìlera tó dángájíá kò sì le rọ́pò àwọn ìmọ̀ràn tàbí ètò ìlera àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n elẹ̀tọ́ ìlera tí ó yẹ láti pèsè àwọn ìmọ̀ràn àti ẹ̀tọ́ náà ní ṣàkání òfin agbègbè rẹ. Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù náà kò forúkọ sílẹ̀ bíi elẹ̀tọ́ ìlera tàbí ilé ìwòsàn lábẹ́ òfin agbègbè kankan, a kò ṣe asọjú tàbí ìdúró fún àwọn iṣẹ́ wa a kò sì tó kọ ògùn kankan tàbí ìtọ́jú. O kò ní láti mú Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù náà tàbí àwọn olùgbani-ní-mọ̀ràn wa gẹ́gẹ́bí ilé ìwòsàn, olùwòsàn tàbí oníṣẹ̀gùn.
Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí kìí ṣe fún ìmọ̀ àìsàn, ògùn kíkọ tàbí ìtọ́jú tí ó yẹ fún ọ, kí o sì má fọkàn sí ìmọ̀ràn kìmọ̀ràn náà tí Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí bá pèsè fún ọ.
Àwọn ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn lórí Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù náà kàn ń ṣe ìdúró fún ìbéèrè ojúkojú pẹ̀lú elétò ìlera tí ó forúkọsílẹ̀ tàbí èyítí ó ní ìwé ìkọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àmọ́ àwọn ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn náà kìí ṣe ìrọ́pò fún àyẹ̀wò ojúkojú àti/tàbí àkókò àyèwò pẹ̀lú akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elẹ̀tọ́ ìlera tí ó ní ìwé ẹ̀rí.
Síwájú síi, o ní láti wá ìmọ̀ràn nípa síṣe ìpàdé ojúkojú pẹ̀lú akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ìlera tí ó ní ìwé ẹ̀rí nígbàgbogbo kí o tó tèsíwájú pẹ̀lú ìṣẹ́yún oníṣẹ̀gùn tàbí kí o tó yan ọ̀nà ìṣẹ́yún míràn. Àwọn ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn náà yó kàn pèsè àwọn àlàyé tí ó wà ní gbangba nípa oríṣiríṣi àṣàyàn ìṣẹ́yún oníṣẹ̀gùn kìí síì pèsè àfojúsùn tàbí ìmọ̀ràn lórí èyítí o dára fún ọ nínú àwọn àṣàyàn náà.
O kò gbọdò ṣe àìbọ̀wọ̀, yàgò fún tàbí dúró kí o tó gba ìmọ̀ràn oníṣẹ̀gùn lọ́wọ́ oníṣẹ̀gùn tàbí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ìlera nípa ìpàdé ojúkojú, nítorí ìmọ̀ràn tàbí àlàyé tí o gbà láti ọ̀dọ̀ wa.
Ní gbogbo ìgbà, o ní láti rí àwọn elétò ìlera tí ó forúkọsílẹ̀ ní sàkání rẹ kí o tó lo ògùn tàbí gba ìtọ́jú kankan.
Àwọn Èwọ̀
O kò gbọdọ̀ ṣi Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí lò. O kò ní: dáràn tàbí fọwọ́ sí iṣẹ́ ọ̀daràn: Ṣe àkóràn tàbí gbé kòkòrò, trojan, aràn, bóòmbù ọpọlọ tàbí ohunkóhun tí ó ní ìrira, tí ó le ba ẹ̀rọ jẹ́, ní ìgbédínà ìgbẹkẹ̀lé tàbí ní ọ̀nà àìtọ́ tàbí ọ̀nà tó burú jáì; tọwọ́ bọ Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù náà; ba àkọsílẹ̀ wa jẹ́; fa ìbínú fún àwọn olùmúlò míràn; tẹ ẹ̀tọ́ elòmíràn mọ́lẹ̀; fi ìkéde ọjà tí a kò rán ọ ránṣẹ́, èyítí a mọ̀ sí “spam”; tàbí gbìyànjú láti fa wàhálà sí àwọn ohun èlò ayélujára ti tàbí èyítí a fi wọ àpèrí yìí. Síṣe lòdì sí ìgbékalè yìí máa jámọ́ ìwà ọ̀daràn, Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí yó fi ẹjọ́ ìṣẹlòdì náà sun àwọn eleto òfin tí ó tọ́, a ó sì fi ọ́ hàn sí wọn.
A kò ní dáhùn fún ìpàdánù tàbí ìbàjẹ́ tí wàhálà alápìńká, kòkòrò tàbí àwọn ohun èlò ìmọ̀ ẹ̀rọ tí ó léwu tí ó sì le ṣe àkóbá fún ẹ̀rọ ayélujára rẹ tàbí àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ nípa lílo Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí tàbí gbígba ohun èlò láti orí Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù sí orí ẹ̀rọ ayélujára rẹ tàbí àwọn Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù tí ó sopọ̀ mọ́ọ.
Nkàn Ìní Ọpọlọ, Àkọsílẹ̀ inú ẹ̀rọ àti Àkọsílẹ̀
Ẹ̀tọ́ lórí àkọsílẹ̀ inú ẹ̀rọ àti àkọsílẹ̀ (tí ó fi mọ́ àwọn àwòràn) tí a pesè fún ọ nípasẹ̀ Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí jẹ́ nkàn ìní Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí tàbí ti àwọn olùṣẹ̀tọ̀ rẹ̀, a sì ti fi òfin dèé káàkiri àgbáyé. Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù náà àti àwọn olùṣẹ̀tọ̀ rẹ̀ ti tọ́jú àwọn ẹ̀tọ̀ náà. O lè tọ́jú, ṣe itẹ̀jáde tàbí fi àwọn àkọsílẹ̀ náà hàn fún ìlò tìrẹ nìkan. A kò gbà ọ́ láàyè láti tẹ̀jáde, yípadà, pín kiri tàbí wá ọ̀nà míràn láti tún àwọn àkọsílẹ̀ àbí àwọn abala kan nínú àwọn àkọsílẹ̀ wa kọ lọ́nà kọnà tàbí ohunkóhun tí o bá rí lórí Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí, o kò sìle lo èyíkèyí nínú àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí fún ìṣòwò tàbí ilé iṣẹ́ ìṣòwò.
Àwọn Òfin àti Ìlànà ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn Orí Afẹ́fẹ́
Ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn náà jẹ́ ètò tí à ń pèsè lórí afẹ́fẹ́ fún àwọn obìnrin tí wọ́n ń gbèrò láti ṣe ìṣẹ́yún oníṣẹ̀gùn tàbí tí wọ́n ní ìbéèrè lórí ìṣẹ́yún oníṣẹ̀gùn. Ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn náà fọwọ́sí àdéhùn àgbáyé lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lórí ẹ̀tọ́ ìwàláyé, ìlera, àlàyé, àsírí, àti ànfàní lórí ìtẹ̀síwájú sáyẹ̀nsì tí a bọ̀wọ̀ fún. Àwọn ìlànà wònyí wà fún ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn wa:
• Àlàyé àti ìmọ̀ nìkan là ń pèsè lórí ìṣẹ́yún oníṣẹ̀gùn tí kò léwu fún àwọn obìnrin tí ó wù láti ṣé oyún wọn, kò sì yẹ kí á ka àwọn iṣẹ́ wa sí èyí tó ń gbani níyànjú láti ṣẹ́yún tàbí tí ó ń gbé ìṣẹ́yún láruge.
• A kìí pèsè ògùn tàbí àwọn ohun èlò ìṣẹ́yún oníṣẹ̀gùn.
• Òfin agbègbè àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan ni ó n se àbojútó ìṣẹ́yún oníṣẹ̀gùn kí o sì tó yàn láti ṣe ìṣẹ́yún ìṣègùn ríi wípé o ti ka àwọn òfin tí ó jọ mọ agbègbè rẹ ó sì ti yé ọ. O lè rí àkójọpọ̀ àwọn òfin agbègbè níbí. A pèsè àlàyé yìí fún ìmọ̀ rẹ, a sì lè má soó dọ̀tun. A kò ṣe ìsojú fún pìpéyé rẹ̀, àlàyé yìí kò sì lè dúró fún ìmọ̀ràn ti òfin. O sì tún mọ̀ bẹ́ẹ̀ni o gbà wípé Ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn náà tí Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí ń pèsè jẹ́ èyítí ó kárí ayé, kò sì ṣeé ṣe fún wa láti jẹ́ kí o mọ̀ nípa àwọn òfin agbègbè rẹ nígbàtí a bá ń gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn àti wípé nígbàmíràn àlàyé tí Ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn náà Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí pèsè le má bá òfin agbègbè rẹ tàbí ìmọ̀ràn ìlera rẹ lọ. Tí èyí bá ṣẹlè, ó ṣe pàtàkí fún ọ láti wo àlàyé tí àwọn olùgbani-ní-mọ̀ràn wa pèsè ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà ìjọba orílẹ̀ ẹ̀dẹ̀ rẹ àti ti àwọn elétò ìlera kí o sì tẹ̀lé àwọn òfin àti ìlànà náà.
• Ojúṣe rẹ ni láti mọ ìhámọ́ òfin tí ó bá wà lórí ìráàyè sí àlàyé lórí ìṣẹ́yún oníṣẹ̀gùn lábẹ́ àwọn òfin tí ó ní ṣe pẹ̀lú rẹ. Òfin kò ní de Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù náà fún ohun tí ó bá tẹ̀lée pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹjọ́ tàbí ọ̀rọ̀ òfin látàrí lílo ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn tí a pèsè lórí Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí.
• Wàá béèrè àwọn ìbéèrè rẹ lọ́wọ́ olùgbani-ní-mọ̀ràn wa nípa fífi ọwọ́ sí fóòmù tí ó wà ní abala “Kàn sí wa àti/tàbí ìtàkurọ̀sọ ààyè” lórí ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí.
• Tí o bá ń lo abala “Kàn sí wa” lórí ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí, o ní láti pèsè àpò ìfìwèráńṣẹ́ rẹ kí àwọn olùgbani-ní-mọ̀ràn wa le pèsè àlàyé tí ó pé lórí ìbéèrè rẹ nípa fífí ìwé ráńṣẹ́ sí ẹ.
• A pèsè abala “Kàn sí wa àti Ìbánisọ̀rọ̀ lóri afẹ́fẹ́” náà lórí olùgbani-ní-mọ̀ràn yìí fún àwọn obìnrin tí wọ́n ti pilè yàn láti wá àlàyé lórí ìṣẹ́yún oníṣẹ̀gùn, o kò sì gbọdọ̀ sìí lò.
• O kò ní sanwó láti lo ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn orí Afẹ́fẹ́ nígbàkúùgbà.
• Ó jẹ́ dandan láti parí ìtàkurọ̀sọ orí afẹ́fẹ́ pẹ̀lú àwọn olùgbani-ní-mọ̀ràn wa kí o tó rí àyè sí ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn wa.
• Ojúṣe rẹ ni láti pèsè àlàyé tí ó péye tí ó sì tọ́ nípa ìlera rẹ. Fífi nkàn pamọ́ fún wa le dènà àti gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn tí ó yẹ.
• Láti lo Ìbánisọ̀rọ̀ lóri afẹ́fẹ́ àti ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn wa, o ní láti dìídì fọwọ́ sí gbígba àti lílo ọ̀rọ̀ rẹ gẹ́gẹ́bí ìpamọ́ ètò ìmúlò wa ṣe là sílẹ̀ àti ní ìbámu pẹ̀lú European Union General Data Protection Regulátion (GDPR) àti àwọn òfin agbègbe míràn tí ó jọ mọ́ ìdábòbò àlàyé ti ara ẹni.
• A lè fún àwọn elẹ̀tọ́ ìlera àti àwọn oníṣẹ̀gùn tí ó ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú wa ní àlàyé rẹ kí wọ́n le pèsè ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn tó dántọ́ fún ọ.
• A pèsè àwọn ètò náà lórí “bí ó ṣe rí” láì ṣe ìsojú tàbí ìdúró fún ìpéye àwọn ẹ̀tọ́ wa tàbí àwọn ọ̀nà ìṣẹ́yún oníṣẹ̀gùn wa. A kò ṣe asọjú tàbí ìdúró bó ti wù kó mọ lórí bí ètò ìgbani-ní-mọ̀ràn wa yó ṣe wúlò, péye, tọ́ tàbí bá ohun tí o fẹ́ lọ.
Gbèsè ò kàn wá
Lábé ohunkóhun, ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí kò lè ṣèdúró fún irúfẹ́ àdánù tàbí àkóbá, tí ó fi mọ́ ìjàmbá tàbí ikú, tí ó wáyé látàrí lílo ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí tàbí àwọn ètò wa, àkọsílẹ̀ tí a pín lórí ojú-òpó wẹ́ẹ́bù náà tàbí èyítí àwọn elẹ̀tọ́ ìlera àti àwọn olùgbani-ní-mọ̀ràn wa pín tàbí ìbáṣepọ̀ àwọn olùmúlò ojú-òpó wẹ́ẹ́bù náà, yálà lórí afẹ́fẹ́ tàbí lójú ayé.
Sísopọ̀ mọ́ ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí
O lè ṣe àsopọ̀ mọ́ ojú-ewé àkọ́kàn wa, níwọ̀n ìgbà tí o bá ṣe èyí lọ̀nà tí kò burú tí kò rúfin tí kò sì borúkọ wa jẹ́ tàbí lòó ní ìlòkulò, àmọ́ o kò gbọdọ̀ ṣe àsopọ̀ lọ̀nà tí ó dábàá pé a ní ìbáṣepọ̀, a fọwọ́ síi tàbí a ṣe ìtẹ́wọ́gbà nígbàtí a kò ṣe èyíkèyí nínú rẹ. O kò gbọdọ̀ ṣe àsopọ̀ láti ojú-òpó wẹ́ẹ́bù tí kìí ṣe tìrẹ. O kò gbọdọ̀ kó ojú-òpó wẹ́ẹ́bù náà sórí ojú-òpó wẹ́ẹ́bù míràn bẹ́ẹ̀ni o kò gbọdọ̀ ṣe àsopọ̀ sí abala ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí kankan bí kò ṣe ojú-ewé àkọ́kàn. A ní ẹ̀tọ́ láti yọ àṣẹ àsopọ̀ wa láì so fún ọ.
Ìkìlọ̀ nípa ìní, ààmì orúkọ, àwọn àwòrán àwọn olókìkí, àti ẹ̀tọ́ àtọkànwá tí ẹni kẹta.
Àyàfi ibití a bá so wípé kò ríbẹ̀, gbogbo ènìyàn (tí ó fi mọ́ orúko wọn àti àwọn àwòrán), àṣẹ àti àkọsílẹ̀ ẹnìkẹẹ̀ta, ẹ̀tọ́ àti/tàbí àwọn ibi tí ó farahàn lórí àpèrí yìí kò fi ibi kankan ní ìbáṣepọ̀ tàbí sopọ̀ mọ́ ojú-òpó wẹ́ẹ́bù náà, o kò sì gbọdọ̀ gbé ọkàn lé ìwàláàyè ìbáṣepọ̀ bẹ́ẹ̀. Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn tó ni àwọn àṣẹ/àwọn orúkọ tí a fihàn lórí ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí. Tí a bá fi àṣẹ tàbí òrúkọ tí a fihàn lórí ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí, a lòó láti júwe ọjà tàbí iṣẹ́ ni, kò sì sí ìdánilójú wípé ọjà tàbí ẹ̀tọ́ náà gba àṣẹ lọ́wọ́ tàbí ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ojú-òpó wẹ́ẹ́bù wa.
Ìyọ̀nda kúrò nínú wàhálà
O gbà láti gbéja, dáàbòbò àti láti má ṣe kọ ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí, àwọn ọ̀gá ńlá ńlá, àwọn ọ̀gá míràn, àwọn òṣìṣẹ́, àwọn agbaṣẹ́ṣe, àwọn asojú, àti àwọn èyàn wa sínú wàhálà tí ó fi mọ́ àwọn olùgbani-ní-mọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ẹnìkẹẹ̀ta àti gbogbo ohun tí ẹnìkẹẹ̀ta gbà, gbèsè, àkóbá àti/tàbí owó (tí ó fi mọ́ owó ẹjọ́) tí ó wáyé látàrí lílo ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí tàbí ìṣelòdì sí ìlànà ìṣe.
Àwọn Àyípadà
Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí ni ẹ̀tọ́ ní èyítí ó wà ní agbára rẹ nígbàkúùgbà àti láti túnṣe, yọ kúrò tàbí yí àwọn ẹ̀tọ́ àti/ tàbí ojú ìwé tí ó bá wù wọ́n kúrò lórí Ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí padà láì sọ fún ọ.
Àìṣedéédé
Tí abala kan nínú ìlànà ìṣe yìí kò bá ṣeé mú lágbára (tí ó fi mọ́ àwọn ibití a ti wípé gbèsè ò kàn wá) kò lè fa ìpalára fún ìṣedéédé àwọn ìlànà ìṣe tí ó kù. Àwọn ọ̀rọ̀ ìyókù ṣì wà bó ṣe wà. Níwọ̀nba ìgbà tí ọ̀rọ̀ tó kù lẹ́yìn tí a bá yọ abala kan lára rẹ bá ní ìtumọ̀, a ó túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà bí ó ṣe tọ́. Dípò èyí, o gbà wípé a lè tún abala náà ṣe, a sì lè túmọ̀ rẹ ní ọ̀nà tí ó fara jọ ìtumọ̀ àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́bí òfin ṣe gbàá láàyè.
Àwọn Àròyé
À ń siṣẹ́ lórí ìlànà mímú àròyé èyítí a ó lò láti yanjú ìjà tí wọ́n bá kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, jọ̀wọ́ jẹ́ kí á mọ̀ tí o bá ní àròyé tàbí àfikún.
Àmójúkúrò
Tí o kò bá ṣe déédé sí àwọn ìlànà yìí tí a kò sì ṣe nkànkan, a sì ní ẹ̀tọ́ láti lo ẹ̀tọ́ àti àtúnṣe wa nígbà míràn tí o kò bá ṣe déédé sí àwọn ìlànà yìí.
Gbogbo Àdéhùn
Ìlànà Ìṣe tí ó wà lókè yìí jẹ́ gbogbo àdéhùn tó wà láàrín gbogbo ẹgbẹ́, ó sì borí gbogbo àdéhùn káàdéhùn tó bá wà láàrín ìwọ àti ojú-òpó wẹ́ẹ́bù yìí. Àmójúkúrò lórí àwọn ìpèsè ìlànà ìṣe le wáyé tí ó bá wà ní àkọọ́lẹ̀ tí olùdarí ojú-òpó wẹ́ẹ́bù kan bá sì bu ọwọ́ lùú.
