Letrozole jẹ oògùn tí a ti ṣe ìwádìí nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí apá kan ọ̀nà ìṣẹ́yún oníṣègùn, ní pàtàkì ní àwọn ibi tí mifepristone kò ti sí. Bíi ti mifepristone, a lè lo letrozole pẹ̀lú misoprostol láti fòpin sí oyún ní ìbẹ̀rẹ̀. Letrozole jẹ́ irú oògùn tí a ńpè ní aromatase inhibitor. Ó ń ṣiṣẹ́ nípa sísọ àwọn ìpele estrogen sílẹ̀, èyí tí ó ń nípa lórí bí hormone progesterone ṣe ń ṣiṣẹ́, èyí sì ń ṣèrànwọ́ láti dá oyún dúró láti dàgbà.
Ní ìbámu pẹ̀lú Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO), àdàpọ̀ letrozole (10 mg tí a mu lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́ fún ọjọ́ mẹ́ta) tí a sì tún fi misoprostol (800 micrograms tí a gbé sí abẹ́ ahọ́n ní ọjọ́ kẹrin) jẹ́ ààbò àti ọ̀nà tí ó múnádoko fún ìṣẹ́yún oníṣègùn títí di ọ̀sẹ̀ méjìlá ti oyún. Àwọn ìwádìí fi hàn pé ọ̀nà yìí lè ṣiṣẹ́ dáadáa, pàápàá nígbà tí wọ́n bá fi wé lílo misoprostol nìkan. Àmọ́, Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé a nílò ìwádìí síwájú sí i láti mọ bí ó ṣe léwu tó àti bó ṣe múnádoko tó nígbà tó bá yá nínú oyún, àti bí ó ṣe dàbí àdàpọ̀ mifepristone àti misoprostol tí wọ́n sábà máa ń lò