Bí ose le rí oògùn ìsẹ́yún dá lé orílẹ̀ èdè tí o bá wà. Bí o bá sọ fún wa ní orílè èdè tí o wà, ó ṣeé ṣe kí á fún ọ ní àwọn ọ̀nà tí o le gbà rí oògùn ìsẹ́yún àti bí o ṣe le sẹ́yún láì léwu. Kàn sí wa kí á le ṣàlàyé bí óò ṣe sẹ́yún láì léwu.
Tí o bá ń gbèrò láti wá oògùn ìsẹ́yún lágbègbè rẹ, àwọn òtítọ́ kan wà tí ó ṣe pàtàkì tí yóò wù wá láti pín pẹ̀lú rẹ.
Nígbà mìíràn, wíwá oògùn lágbègbè má ń le díè, nítorí o kò lè sọ bí ó ṣe dára tó tàbí èyí tí ó jé gidi. Ó tún máń gbé owó lórí. Ní ìsàlè ni àwọn ìmọ̀ràn tí o nílò tí o bá ń oògùn ìsẹ́yún.
Wíwá Mifepristone lágbègbè
Tí o bá gbìyànjú láti wá Mifepristone lágbègbè, o lè ní àwọn ìṣòro kọ̀ọ̀kan. A máń lo Mifepristone fún oyún sísẹ́ tàbí oyún wíwálẹ̀. A kò fi orúkọ rẹ̀ sílè ní àwọn ìlú mìíràn, pàápàá jùlo ibi tí ìsẹ́yún kò ti tọ́ sí òfin. Nítorí ìdí èyí, ó ṣeé ṣe kí ó nira láti ríi ní ilé iṣẹ́ olóògùn gan. [1]
Èyí túmọ̀ sí pé iye ìgbà tí o bá wá Mifepristone ní ọjà agbègbè ó ṣeé ṣe kí ó má rí gidi
Kò sí ọ̀nà tí àwa tàbí ìwọ yóò fi mọ̀ bóyá gidi ni nípa wíwò, nítorí, oríṣiríṣi ẹ̀yà ni ó wà, àti ìrísí àti ìwọ̀n. Ọ̀nà kan tí afi le mọ̀ bóyá gidi ni kòju tí Mifepristone náà bá sì wà nínú páálí tí ó báa wá lọ, tí ó bá jé èyí, yẹ ìgbà tí yóò kọjá àkókò wò. [2]
Tí o bá rí Mifepristone, rántí pé oníṣègùn ni yóò júwe lílọ Mifepristone, àti pé ó nílò igba mílígírámù (mg) kan láti le parí oyún sísẹ́. [3]
Nígbà míràn ìwọ̀n (mg) oògùn tí o bá rí le yàtọ̀, fún ìdí èyí o nílò láti ṣírò iye ìwọ̀n tí óò lò, fún àpẹẹrẹ, tí o bá rí oògùn ìwọ̀n:
– Mílígírámù mẹ́wàá, wàá nílò oògùn ogún láti le pé iye ìwọ̀n igba.
– Àádọ́ta mílígírámù, wàá nílò oògùn mẹ́rin láti le pé iye ìwọ̀n igba mg.
– Ọgọ́rùn-ún mílígírámù, wàá nílò oògùn méjì láti le pé iye ìwọ̀n igba mg.
– àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
Wíwà Misoprostol lágbègbè
Misoprostol rọrùn láti rí ní àwọn ìlú kan nítorí ó ní ìforúkosílẹ̀ fún ọgbẹ́ inú àti fún ìrọbí tàbí fún ẹ̀jẹ̀ tí kò dá lẹ́yìn ọmọ bíbí. Ní àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn o lè rà á ní ilé ìtajà òògùn láì ní ètò oníṣègùn. [4]
Misoprostol ní oríṣiríṣi orúkọ. Ní ìgbà mìíràn wàá rí òògùn yìí lábé àwọn orúkọ wọ̀nyí: Cytotec, Cyprostol, Misotrol, Prostokos, Vagiprost, Misotac, Mizoprotol, Misofar, Isovent, Kontrac, Cytopan, Noprostol, Gastrul, Chromalux, Asotec, Cyrux, Cytil, Misoprolen, Mibetec, Cytomis, Miclofenac, Misoclo, Misofen, Misogon, Alsoben, Misel, Sintec, Gastrotec, Cystol, Gastec, Cirotec, Gistol, Misoplus, Zitotec, Prestakind, Misoprost, Cytolog, GMisoprostol, Mirolut, Gymiso, Oxaprost
A lè sọ fún ọ pé kí o lo òògùn tí ó ní Misoprostol pelu Diclofenac níwọ̀n ìgbà tí ìwọ̀n ìlò Misoprostol bá jẹ́ igba mílígírámù. Òògùn náà máń wà ní àwọn orúkọ wọ̀nyí, Oxaprost 75 àti Arthrotec. Fún ìbéèrè nípa bí óò ṣe lòó, wo abala ìbéèrè òrèkóòrè kí o sì kàn sí wa tí o bá nílò wá.
Tí ó bá jẹ́ Misoprostol nìkan lo fẹ́ lò láti fi ṣẹ́yún, wọ́n máa ní kí o lo mẹ́jọ sí méjìlá lápapọ̀, gẹ́gẹ́bí iye ọ̀sẹ̀ tí oyún rẹ́ jẹ́. Tí ó bá ṣeé ṣe, ó dára kí o ní méjìlá lọ́wọ́
Ó dára púpò láti wá oògùn yìí nínú páálí tí ó báa wá, ṣùgbọ́n bí èyí kò bá ṣeé ṣe, ríi dájú pé o yẹ oògùn náà wò. Fowó kàń kí o ríi pé kò yòrò kí o sì wòó bóyá àwọn oògùn náà jọ ara wọn. Ríi dájú pé o wo ọjọ́ tí yóò bàjé bí ó bá wà nínú páálí tí ó báa wá.
Kí o tó wá òògùn náà lágbègbè rẹ, jọ̀wọ́ kàà kí o sì mọ̀ nípa àwọn òfin tí ó somọ́ oyún ṣíṣẹ́, gbogbo ìbéèrè tí ó jọ mọ́ gbígba ètò láti owó òṣìṣẹ́ ìlera tí ati forúkọ rẹ̀ sílè lágbègbè rẹ kí o tó rà tàbí lo òògùn ìsẹ́yún náà. Safe2choose kì yóò ṣe ìdúró fún irúfẹ́ ìrúfin kankan.
Fún àkójọ òṣìṣẹ́ ìlera àti ilé ìwòsàn tí ó ń sẹ́ oyún tí a kójọpọ̀ fún ẹjọ́ rẹ, jọ̀wọ́ kàn sí wa.Jọ̀wọ́ wòó fínnífínní kí o tó yan òṣìṣẹ́ tàbí ilé ìwòsàn kankan. A pèsè àlàyé yìí fún ìrọ̀rùn rẹ, àwa ò sì tíì wádìí rẹ̀ fúnra wa. Àwa kò ní ṣe ìdúró fún òtítọ́ tàbí dídára àlàyé náà.
Ètò nípa lílo òògùn náà
Nígbà tí o bá ń wá òògùn náà níbikíbi tí o bá wà, bóyá ọjà ni, ilé olóògùn ni tàbí oníṣègùn rẹ fún àpẹẹrẹ, o lè máa gba ètò tí kò jọra wọn lórí bí óò se lo òògùn náà.
Ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ń tajà ni kò kẹ́kọ̀ọ́ dáradára tí wọn kò sì tún ní àlàyé tí ó tọ́ lóri bí wọ́n ṣe ń lọ òògùn ìsẹ́yún láti pa owó, kìí ṣe láti ti obìnrin lẹ́yìn. Kí o tó lo òògùn ìsẹ́yún náà, kí o ríi dájú pé ò ń tẹ̀lé àwọn ètò tó tọ́ nípa wíwò ètò orí afẹ́fẹ́ lóri sísẹ́ oyún pelu Mifepristone àti Misoprostol tàbí pẹ̀lú Misoprostol nìkan tàbí kí o ko ìwé sí àwọn olùdámọ̀ràn wa kí o sì kàn sí wa.
Wọn le fún ọ ní àlàyé tí kò tọ́ ní ilé ìta òògùn, àwọn oníṣègùn náà sì le fún ọ. Ìhámọ́ oyún sísẹ́ láwùjọ ní àwọn ibìkan ńfa àròsọ àti àlàyé tí kò tọ́ ní agbègbè kọ̀ọ̀kan, láàrín àwọn òṣìṣẹ́ pàápàá.
Ó ṣe pàtàkì láti tẹ̀lẹ́ ètò tí ó tọ́ tí ó sì dá lórí ìmọ̀ ìjìnlè sáyẹ̀nsì tí àjò ìlera gbogboògbò fi owó sí. Tí o bá ti ka àlàyé oríṣiríṣi, kàn sí wa kí á le pa iyèméjì rẹ ré àti láti fún ọ ní àlàyé tí ó tó. [5]
Rántí pé safe2choose wà ní kàlẹ̀ láti ràn ọ lọ́wọ́
Àwọn olùdámọ̀ràn wa kẹ́kọ̀ọ́ gboyè, wọn kò sì fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sọ fún wọn nípa lílo òògùn ìsẹ́yún àti bí wọ́n ṣe ń lòó. A máń tèlé ìlànà ètò àjọ ìlera àgbáyé Bí ó bá ṣe pàtàkì, a lè tọ́ka rẹ sí àjọ tí ó ṣeé fokàń tán tí ó le ràn ó lọ́wọ́ láti rí oògùn ìsẹ́yún, tàbí wá àlàyé ní agbègbè rẹ nípa rẹ̀. [3]
[1] Gynuity. Mifepristone approvals. Retrieved from: https://gynuity.org/assets/resources/mife_by_country_and_year_en.pdf.
[2] IPPF. Registered Mifepristone brands. Retrieved from: https://www.medab.org/advanced-search-multiple-results?country=all&commodity=100&brand=all#multiple-search-result
[3] World Health Organization. Safe abortion: technical and policy guidance for health systems. Retrieved from: https://apps.who.int/iris/bitstream/handle/10665/70914/;jsessionid=B7AEEBE4F34809D869F73B1ABA7F6221?sequence=1
[4] WHO. Essential Medicines List Application Mifepristone–Misoprostol for Medical Abortion. Retrieved from: https://www.who.int/selection_medicines/committees/expert/22/applications/s22.1_mifepristone-misoprostol.pdf?ua=1
[5] Ipas. (2019). Clinical Updates in Reproductive Health. L. Castleman & N. Kapp (Eds.). Chapel Hill, NC: Ipas. Retrieved from: https://www.ipas.org/wp-content/uploads/2023/09/Ipas-Clinical-Updates-in-Reproductive-Health-CURHE23b.pdf