Lílo cytotec fún ìṣẹ́yún: Gbogbo ohun tí o nílò láti mọ̀

Oríṣiríṣi ògùn ìṣẹ́yún ló wà ní ọjà, wíwà rẹ̀ sìí pé oríṣiríṣi káàkiri àgbáyé. Cytotec wà lára àwọn tí ó gbajúmò jùlọ nínú ògùn yìí. Bóyá ó kàn ọ́ bí cytotec ṣe ń ṣíṣe, ìdíyelé, ìwọ̀n lílò tàbí ibi tóó ti ríi, a ní ìrètí wípé ìtọ́sọ́nà yìí yíò wúlò. Bí o bá ní ìbéèrè síi, jọ̀wọ́ kàn sí ọ̀kan lára àwọn olùbánidámọ̀ràn wa pẹ̀lú meèlì tàbí àpótí ìbánisọ̀rọ̀ ojúkojú, inú wọn yóò sì dùn láti rán ọ́ lọ́wọ́

Kí ni ògùn ìṣẹ́yún cytotec?

image of cytotec pill packaging

Photo credit: Cytotec. Flickr

image of hexagonal cytotec pill

Photo credit: Cytotec. Flickr

image of circular cytotec pill

Photo credit: Cytotec. Flickr


Cytotec jẹ́ ògùn tí à ń lò fún ìṣẹ́yún oyún tó ti pé ọ̀sẹ̀ mẹ̀talá. O jẹ́ ògùn prostaglandin, tí ó túmọ̀ ó ń fa rírọ̀ àti lílanu ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ àti ìhámọ́ ilé ọmọ nígbà tí o bá lòó nínú oyún. Ilé iṣẹ́ olóògùn Pfizer ló ń ṣeé. [1]

Báwo ni cytotec ṣe ń ṣiṣẹ́ fún oyún ṣíṣẹ́

Cytotec ń ṣiṣẹ́ nípa rírọ̀ àti lílanu ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ. Ó sì tún jé kí ilé ọmọ há. Gbogbo ìṣe yìí yóò ṣe ìrànwọ́ láti yọ oyún náà kúrò. Lọ́pọ̀ ìgbà yóò bẹ̀rẹ̀ ìṣe ní wákàtí kan lẹ́yìn tí o ti lòó ṣùgbọ́n ó lè gbà jù bẹ́ẹ̀ lọ. [2]

Kí ni ìwọ̀n ìlò cytotec

Lọ́pọ̀ ìgbà cytotec má ń wá ní ìwọ̀n igba míkírógírámù. Ìdiwọ̀n lílò rẹ̀ síi má ń wá ní ìbámu pẹ̀lú ipò tí oyún bá wà.

Fún oyún tí kò ju ọ̀sẹ̀ mẹ́sàán lọ, òdiwọ̀n cytotec jẹ́ ìlọ́po méjì ẹgbẹ̀rún míkírógírámù (àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ egbèjọ míkírógírámù tàbí ìwọ̀n mẹ́jọ)

Fún oyún tó wà láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́sàán sì mẹ̀talá ìdiwọ̀n ìlò cytotec jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta ẹgbẹ̀rin míkírógírámù (àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀wá lé ní irinwó míkírógírámù tàbí ìwọ̀n méjìlá). [3]

Kí ni òdiwọ̀n lílo cytotec fún oyún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà?

Fún oyún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà tàbí tí kò tíì tó oṣù mẹ́fà, ìdiwọ̀n ìlò cytotec jẹ́ ìlọ́po méjì ẹgbẹ̀rin míkírógírámù (àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ egbèjọ míkírógírámù tàbí ìwọ̀n mẹ́jo). Nígbà mìíràn a le gbani níyànjú kí á ní èlé míkírógírámù ẹgbẹ̀rún (ìwọ̀n mẹ́rin) síi ní ọwọ́ fún ìlò. [3]

Kí ni òdiwọ̀n lílo cytotec fún oyún tí kò tó ọ̀sẹ̀ mẹ́sàán?

Fún oyún tí kò tó ọ̀sẹ̀ mẹ́sàán, òdiwọ̀n cytotec jẹ́ ìlọ́po méjì ẹgbẹ̀rún míkírógírámù (àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ egbèjọ míkírógírámù tàbí ìwọ̀n mẹ́jọ) Nígbà mìíràn a le gbani níyànjú kí á ní èlé míkírógírámù ẹgbẹ̀rún (ìwọ̀n mẹ́rin) síi ní ọwọ́ fún ìlò [3]

Kí ni ìwọ̀n ìlò cytotec fún oyún ọ̀sẹ̀ mẹ́sàán sí mẹ̀talá?

Fún oyún ọ̀sẹ̀ mẹ́sàán sí mẹ̀talá, ìdiwọ̀n ìlò rẹ̀ jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta ẹgbẹ̀rin míkírógírámù (àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ egbèjìlá tàbí ìwọ̀n méjìlá). [3]

Èló ni cytotec?

Iye owó cytotec má ń sábà kéré, ṣùgbọ́n yóò yàtọ̀ láti agbègbè kan dé òmíràn. Orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan ní oríṣiríṣi òfin lórí ìṣẹ́yún, èyí sì lè fa ìyàtọ̀ láàárín iye owó cytotec. Ó ṣeé ṣe pé ní orílẹ̀ èdè tí òfin kò fi àyè gba oyún ṣíṣẹ́, iye owó cytotec láì jẹ́ pé oníṣègùn ni ó kọọ́ le gara tàbí kí ó wọ́n.

Àwọn àjọ kan wà tí wọ́n má ń fúnni láwọn oògùn yìí , o lè wo àpèrè Women on Web àti Women Help Women fún àlàyé lórí bí o ṣe lè rí oògùn yìí gbà. [4]

Bí a ṣe ń lo cytotec

Safe2choose gbani níyànjú láti lo cytotec lábẹ́ ahọ́n tàbí fífi sì ìsàlẹ̀ ahọ́n. Ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti lọ ògùn cytotec ni kí á fi sábẹ́ ahọ́n, kí a sì jẹ́ kí ògùn náà o yòrò níbẹ̀ fún ọgbọ́n ìṣẹ́jú, lẹ́yìn ọgbọ́n ìṣẹ́jú a lè gbé èyí bá kù mì pẹ̀lú omi.

Lẹ́yìn wákàtí mẹ́ta tí o ti lo cytotec àkọ́kọ́ (ẹgbẹ̀rin míkírógírámù), kí o lo èyí tí ó tèlée gẹ́gẹ́ bí o ti lo tàkọ́kọ́ náà. Bí ètò bá fihàn pé kí o lòó lẹ́lẹ́ẹ̀kẹta, kí o lòó lẹ́yìn wákàtí mẹ́ta tí o ti lo ìkejì [3]

Kí ni àwọn àbájáde cytotec

Nígbàtí o bá lo cytotec fún oyún ṣíṣẹ́, àwọn àbájáde tí ó le ṣẹlẹ̀ ni pé yóò fa inú rírun ati sísun ẹ̀jẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo àbájáde wọ̀nyí, ó ṣeé ṣe kí o ní ìrírí wọ̀nyí: inu rírun, èébì, ìgbé gbuuru, ibà ati òtútù.

Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn àmì yí ma ń dópin láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún. [4]

Báwo ni ògùn oyún ṣíṣẹ́ cytotec ṣe ri

Tábúlẹ̀tì cytotec igba míkírógírámù kéré, ó funfun, ẹ̀yà oníhàmẹ́fà sì ni. Ilà wà ní àárín rẹ̀, a sì kọ “searle” àti/tàbí “1461” síi lára. [5]

Ọ̀nà àti rí ògùn ìṣẹ́yún cytotec

Wíwà ògùn ìṣẹ́yún cytotec má ń yàtò láti agbègbè kan dé òmíràn. Cytotec tún má ń ṣiṣẹ́ fún ọgbẹ́ inú nítorínà, a lè ríi lórí igbá láì jẹ́ pé oníṣègùn kọọ́ sílè. Tí irú èyí bá ṣẹlẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ògùn náà wá nítòsí ògùn inú ilé olóògùn tó wà ní agbègbè rẹ. Bí o kò bá rí níbẹ̀, o ṣeé ṣe kó jẹ́ pé o nílò ìdarí ní ilé olóògùn náà.

Wọn ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Cytotec wà ni àwọn orílẹ̀-èdè yìí [7]:

Armenia, Australia, Azerbaijan, Belgium, Belize, Benin, Bolivia, Burkina Faso, Cambodia, Cameroon, Cape Verde, China, Cote d’Ivoire, Dem. Rep. of Congo, Dominican Republic, Ecuador, Egypt, El Salvador, Gabon, Gambia, Georgia, Ghana, Guatemala, Guinea, Guyana, Haiti, Indonesia, Kenya, Kyrgyzstan, Lebanon, Lithuania, Malawi, Mali, Mexico, Morocco, Myanmar, Niger, Nigeria, Paraguay, Peru, Rwanda, Sierra Leone, South Africa, Thailand, Togo, Tunisia, Turkey, Uganda, United Kingdom, United States, Uzbekistan, Zambia

Ojú ewé Káyélujára yìí náà leè ṣe ìrànlọ́wọ́ láti ṣe àwári Cytotec ní àgbègbè rẹ. [6]

Ò sì tún le kàn sí àwọn olùgbaninímọ̀ràn wa, wọn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ri ògùn náà rà lọ́wọ́ olùtaja tó ṣe fọkàn tán ní àgbègbè rẹ.

Àwọn Ònkọ̀wé:

Ńipasè ikọ safe2choose àti àwọn ọ̀mọ̀ràn ní carafem, ní ìbámu pẹ̀lú Ìmọ̀ràn ìgbìmò ìjọba àpapọ̀ lórí ètò ìsẹ́yún (NAF) ní ọdún 2020, ìmọ̀ràn Ipas ní ọdún 2019.

Ìjọba orílè-èdè gbogboògbò lọ́rí ìsẹ́yún jẹ́ ẹgbẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ abánisẹ́yún ní Àríwá Amẹ́ríkà.

carafem ń pèse ètò ìsẹ́yún àti ìfètò sọ́mọ bíbí tí ó rọrùn tí ó sì dájú kí àwọn ènìyàn le ṣàkóso iye àti àyè tí ó wà láàrin àwọn ọmọ wọn.

Ipas jẹ́ àgbárí òkèèré kan ṣoṣo tí ó gbájúmọ́ fífi ètò sí oyún ṣíṣẹ́ tí kò léwu àti ìbójútó èlà mágboyún.

[1] Uptodate. Misoprostol as a single agent for medical termination of pregnancy. Retrieved from: https://www.uptodate.com/contents/misoprostol-as-a-single-agent-for-medical-termination-of-pregnancy?search=cytotec&source=search_result&selectedTitle=2~117&usage_type=default&display_rank=1#H2428459676

[2] Allen R, O’Brien BM. Uses of misoprostol in obstetrics and gynecology. Rev Obstet Gynecol. 2009;2(3):159–168. Retrieved from: https://www.ncbi.nlm.nih.gov/pmc/articles/PMC2760893/

[3] Ipas. (2019). Clinical Updates in Reproductive Health. L. Castleman & N. Kapp (Eds.). Chapel Hill, NC: Ipas. Retrieved from: https://ipas.azureedge.net/files/CURHE19-april-ClinicalUpdatesInReproductiveHealth.pdf

[4] Uptodate. Misoprostol: drug information. Retrieved from: https://www.uptodate.com/contents/misoprostol-drug-information?search=cytotec&source=panel_search_result&selectedTitle=1~117&usage_type=panel&kp_tab=drug_general&display_rank=1#F197173

[5] WebMD. Drugs and medications: cytotec. Retrieved from: https://www.webmd.com/drugs/2/drug-1786/cytotec-oral/details

[6] Women On Waves. Map Countries. Retrieved from: https://www.womenonwaves.org/en/map/country

[7] IPPF. Medical Abortion Commodities Database. Retrieved from: https://www.medab.org/advanced-search-multiple