Báwo ni mo ṣe lè rí ìtọ́jú oyún ṣíṣẹ́ tí kò béwu dé?

Ó ṣeé ṣe kì ó ṣòro kí ó sì nira láti lóye àwọn àṣàyàn ọ̀nà ìtọ́jú oyún ṣíṣẹ́. safe2choose wà níhìń láti tọ́ e sọ́nà lórí àwọn àṣàyàn oyún ṣíṣẹ́ – yálà ìṣẹ́yún pẹ̀lú ògùn ni tàbí ìṣẹ́yún ní ilé ìwòsàn. Ikọ̀ olùbánidámọ̀ràn wa le ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yiri ìbójúmu rẹ fún àwọn àṣàyàn yìí àti láti tọ́ka rẹ sí olùpèsè ìṣẹ́yún aláìléwu.

Aboyun Itọju Iṣẹyun

Ṣe oyún ṣíṣẹ́ kò ní ṣe ìpalára fún mi?

Nígbàtí a bá lo ọ̀nà tí ó tọ́, ní ibi tí ó tọ́ àti pẹ̀lú ìmọ̀ tí ó tọ́, oyún ṣíṣẹ́ kìí léwu [1]. Kí o tó bẹ̀rẹ̀ ìlànà ìṣẹ́yún rẹ, wàá nílò láti mọ iye ọ̀sẹ̀ tí oyún rẹ́ dà kí o baà le yan ìlànà oyún ṣíṣẹ́ tí ó tọ́ fún e. O lè lo Ìṣirò Oyún nísàlẹ̀ yìí láti ṣe ìṣirò yìí. Àwọn àmì ìlọ́lùú kan náà sì wà tí o ní láti mọ̀ nítorípé wọ́n le kó ipa nínú yíyẹ ìlànà tí o yàn, àwọn olùbánidámọ̀ràn wa sì le tọ́ ẹ sọ́nà pẹ̀lú àlàyé tí ó bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ.

Ẹ̀RỌ ÌṢIRÒ OYÚN

Ọjọ́ wo ni ó ṣe nǹkan oṣù kẹ́yìn?

Kọ́ bí o ṣe máa ṣe ìṣirò.

Safe Abortion Care

Oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú oògùn

Oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú òògùn jẹ́ ìlànà kan tí ó rọrùn nípa lílo oríṣi òògùn méjì (Mifepristone and Misoprostol) tàbí ẹyọọ̀kan. Òògùn yìí yóò jẹ́ kí ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ fún pọ̀ tí yóò sì ti oyún náà jáde ní ọ̀nà tí ó jọ tí nǹkan oṣù. Ó lè lò tó ọjọ́ díẹ̀ sí ọ̀sẹ̀ díẹ̀, ó sì ṣeé ṣe ní ilé. Ní safe2choose, a máa ń ṣe àtìlẹyìn fún àwọn obìnrin tí ó bá fẹ́ ṣẹ́ oyún fúnra wọn ní ilé pẹ̀lú òògùn nípa fífún wọn ní àwọn ohun ìrànwọ́ àti àlàyé tí ó péye nípa oyún ṣíṣẹ́ náà. Fún ìlànà yìí, a máa ń ṣe àtìlẹyìn fún àwọn obìnrin tí oyún wọn ò ju ọ̀sẹ̀ mẹ́tàlá lọ, a sì máa ń ní kí àwọn tí tiwọn bá ti ju ọ̀sẹ̀ mẹ́tàlá lọ lọ rí àwọn alábáṣepọ̀ wa tí ó wà lágbègbè wọn fún àfikún ìtọ́jú oyún ṣíṣẹ́.

OYÚN ṢÍṢẸ́ PẸ̀LÚ ÒÒGÙN

Oyún ṣíṣẹ́ tí kò béwu dé pẹ̀lú òògùn


get-care-clinic

Oyún ṣíṣẹ́ ní ilé ìwòsàn

Ara oyún ṣíṣẹ́ ní ilé ìwòsàn ni oyún ṣíṣẹ́ ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó tí oníṣègùn ṣe, fífà oyún jáde, oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ àti ìtọ́jú ẹ̀yìn tí oyún bá bọ́. Wọ́n máa ń ṣe eléyìí ní ọ́fíìsì olùtọ́jú tàbí ilé ìwòsàn bí òfin ìlú bá fi ààyè gbà á. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, kò kí n mú ìnira lọ́wọ́ nítorí òògùn adániradúró tí wọ́n máa ń lò, kò sì kí ń ju ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ. Tó bá jẹ́ pé èyí ni ó bá ọ lára mu jù, bá wa sọ̀rọ̀ kí á lè darí rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olùtọ́jú tí ó ṣé fọkàn tán.

OYÚN ṢÍṢẸ́ NÍ ILÉ ÌWÒSÀN

Àwọn ìlànà oyún ṣíṣẹ́ ní ilé ìwòsàn tí kò béwu dé.