Àwọn ẹ̀rí

Safe Abortion Stories

Lójojúmọ́, àwọn obìnrin ní àgbàlá ayé má ń pinnu láti yọ oyún wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ló ti lo ògùn ìṣẹ́yún tí kò léwu, tí ètò rẹ̀ sì ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nínú ilé wọn.

Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ògùn síì wà ní àrọ́wọ́tó rẹ, ó ṣeé lò ní ìkọ̀kọ̀ àti pé ó rọrùn ju àwọn ọ̀nà ìṣẹ́yún míràn lọ.

Tí o bá ṣẹ́yún pẹ̀lú ògùn tàbí o gba ìrànlọ́wọ́ láti ọwọ́ safe2choose, rántí wípé sísọ ìrírí rẹ ṣe kókó gidigidi fún àwọn obìnrin míràn tí ó fé gbó ẹ̀rí tó dájú àti àtìlẹyìn fún ìpinnu wọn.

Ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ wípé ìṣẹ́yún jẹ́ ohun tí ara ẹni, ìrírí oníkálukú sì yàtò. Sísọ ìrírí rẹ máa gba àkókò péréte o sì le ran obìnrin tí ó ń wá àlàyé nípa isé tí àwọn olùbánidámọ̀ràn wa ń ṣe ní safe2choose.

Lo ìṣẹ́jú díẹ̀ láti so ìrírí àti /tàbí èróngbà rẹ. Lápapò, ẹ jẹ́kí á fihan àgbáyé pé oyún ṣíṣẹ́ kò jẹ́ tuntun, ó sì jẹ́ ipa ayé ẹnikẹ́ni. Lo pẹpẹ yìí láti ṣe ìtànkálẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ àti láti jẹ́kí àwọn obìnrin míràn mọ wípé oyún ṣíṣẹ́ jẹ́ ìpìlẹ̀ ìlera tí wọ́n ní ẹ̀tọ́ sí.

Senegal

Mareme ń gbé ìgbé ayé òmìnira lórí ìpinnu rẹ̀, àmọ́ kí èyí tó ṣẹlẹ̀ ayé rẹ̀ dàbí igbó dídí. Bíi ti Mareme, àwọn obìnrin mọ ìgbàtí ó dára jù láti di ìyá àti ìgbàtí ó dára jù láti yan ipa míràn. Àṣàyàn kan ni oyún ṣíṣẹ́, tí o bá sì fẹ́ mọ̀ síi nípa oríṣi ọ̀nà ìṣẹ́yún tí Àjọ Ìlera Àgbáyé fi ọwọ́ sí, kàn sí: https://safe2choose.org

Watch on Vimeo

South Africa

Ìtàn Ìṣẹ́yún tí àbùkù kò ráyè nínú rẹ̀. ọ̀kan lára wa ni Lizette. Ó mú wa rin ìrìn àjò ìrírí rẹ̀ èyítí gbogbo wa ti ní ìrírí kan tàbí òmíràn nípa rẹ̀. Ohùn rẹ ṣe pàtàkì, so ìtàn rẹ láì fojú hàn tàbí láì dárúkọ rẹ níbí: https://safe2choose.org

Watch on Vimeo

Mú orílè èdè náà