O ni àṣàyàn tó bá jẹ mọ́ láti ṣẹ́ oyún rẹ.

Ní ọdọọdún, idà ogójì nínú àwọn oyún tí à ń ní jákèjádò àgbáyé ni ó jẹ́ èyí tí a kìí fètò sì (Àjọ Guttmacher). Èyí túmọ̀ sí wípé ní ojoojúmọ́ ni àwọn obìnrin jákèjádò gbogbo àgbáńlá ayé ń kojú oyún àìròtẹ́lẹ́ àti wípé fún ìdí ọlọ́kan ò jọ̀kan wọn a sì pinu láti ṣẹ́yún. Gbogbo obìnrin, láì bìkítà ẹ̀yà, ipò, ẹ́sin tàbí ibikíbi tí wọ́n ń gbé lórílẹ̀ ayé lẹ́tọ̀ọ́ sì àwọn ọ̀nà tí kò léwu.
À ń pèsè àlàyé tó múnádóko nípa ọ̀nà ìṣẹ́yún tí kò mú ewu lọ́wọ́

O ha ní ìbéèrè nípa ọ̀nà tí à ń gbà ṣẹ́yún bí?

Tí o bá ní ìbéèrè nípa àwọn ètò ìṣẹ́yún àti àwọn oògùn ìṣẹ́yún, wo abala àwọn ìbéèrè òrèkóòrè wa. Tí o kò bá rí ìdáhùn sí ìbéèrè rẹ tàbí ó wù ọ́ láti bá wa sọrọ̀ tààrà, jọ̀wọ́ pe ọ̀kan lára àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ gbédègbẹyọ̀ olùbánidámọ̀ràn wa nípasẹ̀ abala Ẹ kàn sí wa tàbí àpótí ìbánisọ̀rọ̀ ojúkojú. A wá níbí láti rán ọ́ lọ́wọ́ àti láti pèsè àlàyé lẹ́kùúnrẹ́rẹ́ lórí ètò ìṣẹ́yún tí kò méwu lọ́wọ́.

Last updated on 20/10/2020