Ìdaniloju ati Isiro Oyun

Báwo lo ṣe máa ṣírò ọ̀ṣẹ̀ oyún rẹ?

Ṣíṣírò àkókò ìlóyún rẹ ṣe pàtàkì láì bìkítà bóyá o fẹ́ ṣẹ́ oyún náà tàbí o fẹ́ fi sílẹ̀.

Tí o bá pinnu láti ṣé oyún náà, iye ọ̀sẹ̀ tí oyún náà jẹ́ ni yòò sọ àwọn ọ̀nà ìṣẹ́yún tí o wà fún ọ.

Tí o bá sì pinnu láti fi oyún náà sílè, èyí yòò jẹ́kí agbèbí rẹ tàbí dókítà rẹ mọ́ bí oyún náà bá ń dàgbà ní ọ̀nà tó tọ́. Ní lọ́kàn pé oyún má ń tó ọ̀sẹ̀ méjìdínlógójì sí méjìlélógójì láti ọjọ́ àkókò tí o ṣe nǹkan oṣù gbẹ̀yìn. [1]

Ọ̀nà tí o rọrùn jùlọ láti ṣírò ọ̀sẹ̀ tí oyún rẹ́ jẹ́ ni láti máa ka ọ̀sẹ̀ àti ọjọ́, bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ àkókò tí o rí nǹkan oṣù rẹ gbẹ̀yìn.

O ṣe pàtàkì láti kà láti ọjọ́ àkókò nǹkan oṣù rẹ tó súnmọ́ jùlọ, nítorípé nípa èyí a lè ṣírò ìgbátí ẹyin náà jáde tí o sì di ọmọ. [2]

Kíyèsí àwọn àṣìṣe tí o wọ́pọ̀, máṣe ṣírò nípa:

– kíkà láti àkókò tí o kò ti rí nǹkan oṣù rẹ mọ́;

– kíkà láti ọjọ́ tí o ní ìbálòpọ̀

– kíkà láti ọjọ́ tí o lérò pé o lóyún.

Tí o bá nílò ìrànlọ́wọ́ láti ṣírò ọ̀sẹ̀ tí oyún rẹ jẹ́.

Ṣírò

Mú ọjọ́ àkókò tí o rí nǹkan oṣù rẹ gbẹ̀yìn níbí:

Tí o kòbá ní àkọsílẹ̀ tí o mọ́yán lórí nípa nǹkan oṣù rẹ tàbí o kò lè rántí ìgbàtí o níí gbẹ̀yìn, rántí ohun tí o ń ṣe lọ́wọ́ ní àkókò tí o ríi gbẹ̀yìn. Níbo lọ wà? Ta ni ó wà pèlú rẹ? Èyí nígbàmíràn yóò rán ọ lọ́wọ́ láti rántí ìgbàtí o rí nǹkan oṣù rẹ gbẹ̀yìn. [3]

Àwọn ọ̀nà mìíràn láti fẹsẹ̀ oyún múlẹ̀

1) Àyẹ̀wò ìtọ̀:Àyèwò yìí wọ́pọ̀ gidigidi, a sì máa ṣe àwárí àwọn hòmónùù nínú ìtọ̀. Láti rí èsì tó péye, o ní láti ṣe àyèwò yí láàríín ọ̀sẹ̀ méjì tàbí jùbelọ lẹ́yìn ìbálòpọ̀ tí kò ní ìdáàbòbò.

– Àǹfààní: kò gbówólórí àti wípé ó ṣé dá ṣe nílé.

– Àléébù: Kìí báni ṣírò ọ̀sẹ̀ tí oyún jẹ́.

2) Àyèwò ẹ̀jẹ̀:Irúfé méjì àyèwò ẹ̀jẹ̀ yí ló wa: àyèwò agbára (a máa ṣe àwárí àwọn hòmónùù nínú ẹ̀jẹ̀) àti àyèwò iye (a máa wọn iye àwọn hòmónùù)

– Àǹfààní: Ó lè tètè ṣe àwárí oyún ju àyèwò ìtọ̀ lọ àti wípé ìgbàmíràn ó le sọ ọ̀sẹ̀ tí oyún náà jẹ́ (tí ó bá jẹ́ ti iye)

– Àléébù: Ó gbówó lórí, onímò nípa ìlera ni ó sì gbọ́dọ̀ ṣètò rẹ̀.

3) Àyẹ̀wo ilé ọmọ:Àyèwò yí wúlò nígbàtí oyún bá ti pé ọ̀sẹ̀ mẹ́rin tàbí jùbẹ́ẹ̀lọ, bíbẹ̀kọ́ kò ní rí ohunkóhun. Pàápàá jùlọ ó lè ṣe àǹfààní bí ìwọ kò bá rántí ìgbà tí ó ṣe nǹkan oṣù rẹ gbẹ̀yìn.

– Àǹfààní: yíó ṣe ìṣirò ọ̀sẹ̀ tí oyún jẹ́ ní déédéé, àti pé a lè tún lòó láti ṣe ìdánimọ̀ oyún ectopic tàbí oyún tí kò ṣeé ṣe.

– Àléébù: Ó gbówó lórí, onímò nípa ìlera ni ó sì gbọ́dọ̀ṣètò rẹ [4]

Yíyan ọ̀nà ìṣẹ́yún tí ó dára pẹ̀lú ọ̀ṣẹ̀ oyún

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà tí a le fi ṣe ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ ló wà, ìwọ sì lè yàn níbẹ̀, ó sì má ń níṣe pẹ̀lú oṣù tí oyún bá wà. Nítorí àyípadà má ń wà nínú àsìkò tí oyún yóó fi wá nínú fún oríṣiríṣi ọ̀nà ìṣẹ́yún, ìpinnu náà le dá lórí agbègbè tí o wà, wíwà ohun èlò àti olùpèsè àti èyí tí ó bá wù ọ́

the abortion method for each gestational age

Ìṣẹ́yún Pẹ̀lú Ògùn jẹ ìlànà ti a má ń gba ṣẹ́yún títí di ọ̀sẹ̀ kẹ̀talá.

Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA) jẹ́ ọ̀nà tí a ń gbà yọ nǹkan tó wà nínú ilé ọmọ, a sì má ń lòó fún oyún tí kò ju ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sì mẹ́rìnlá lọ lọ́pọ̀ ìgbà.

Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ iná (EVA)jẹ́ ọ̀nà tí a ń gbà yọ nǹkan tó wà nínú ilé ọmọ, a sì má ń lòó fún oyún tí kò ju ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀dógún lọ

-A má ń lo ètò líla ẹnu ilé ọmọ àti yíyọ gbogbo nǹkan tó wà nínú ilé ọmọ fún oyún tí ó ti kọjá ọ̀sẹ̀ mẹ́rìnlá

– Lọ́pọ̀ ìgbà bí a bá ṣẹ́yún nípa fífa ìrọbí a má ń lòó fún oyún tó ti kọjá oṣù mẹ́rìndínlógún.

Líla ẹnu ilé ọmọ àti ìmúláradájẹ́ ètò ìṣẹ́yún ìgbà àtijọ́ tí a sì ti fi ètò yíyọ nǹkan tó wà nínú ilé ọmọ, ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA), ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ iná (EVA) àti ètò líla ẹnu ilé ọmọ (D&E) rọ́pò rẹ̀. [1], [5]

safe2choose fi ọwọ́ sí ìsẹ́yún oníṣègùn(MA tàbí ìsẹ́yún pẹ̀lú ògùn) tàbí ìsẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA)fún oyún tí ó wà ní oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù mẹ́ta ẹ̀kejì.

kàn síwa

Àwọn òǹkọwé:

Nípa ikọ̀ safe2choose àti àwọn olùrànlọ́wọ́ akọ́ṣẹ́mọsẹ́ ni carafem, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìmòràn Ìgbìmò Àpapò lórí ètò Owó fún Ìṣẹ́yún (NAF) ní ọdún 2020.

Ìjọba orílè-èdè gbogboògbò lọ́rí ìsẹ́yún jẹ́ ẹgbẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ abánisẹ́yún ní Àríwá Amẹ́ríkà

carafem ń pèsè ètò ìṣẹ́yún àti ìfètò sọ́mọ bíbí tí ó rọrùn tí ó sì dájú kí àwọn ènìyàn le ṣàkóso iye àti àyè tó wà láàárín àwọn ọmọ wọn

[1] World Health Organization. Safe abortion: technical and policy guidance for health systems. Retrieved from: https://apps.who.int/iris/bitstream/handle/10665/70914/;jsessionid=B7AEEBE4F34809D869F73B1ABA7F6221?sequence=1

[2] Megan Wainwright, Christopher J Colvin, Alison Swartz & Natalie Leon. Self-management of medical abortion: a qualitative evidence synthesis. Retrieved from: https://www.tandfonline.com/doi/pdf/10.1016/j.rhm.2016.06.008?needAccess=true

[3] Healthline. Tests Used to Confirm Pregnancy. Retrieved from: https://www.healthline.com/health/pregnancy/tests

[4] WebMd. Pregnancy Tests. Retrieved from: https://www.webmd.com/baby/guide/pregnancy-tests#1

[5] Ipas. Clinical Updates in Reproductive Health. 2019. Retrieved from: https://ipas.azureedge.net/files/CURHE19-aprilClinicalUpdatesInReproductiveHealth.pdf

Safe Abortion with Pills Options