Ògùn ìsẹ́yún tàbí ẹ̀ro aláfọwọ́yí: èwo ni ó dára fún mi?

MA Vs MVA

Ní tábìlì yìí, à ń ṣe ìfiwéra láàrin àwọn àǹfààní àti àléébù ìsẹ́yún pẹ̀lú Ògùn àti yíyọ oyún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí(Ọlọ́wọ́ tàbí Oníná). safe2choose fọwọ́ sí àwọn ọ̀nà méjì tí kò léwu yìí láàrin ọ̀sẹ̀ mẹ̀talá àkókò oyún, ó sì wà lọ́wọ́ àwọn obìnrin láti pinu èyí tí ó dára jùlọ gẹ́gẹ́bí ìsúná, wíwà, ọ̀sẹ̀ tí oyún jẹ́ àti ohun tí ó yàn fúnra rẹ̀

Choosing the best method of abortion

Ìṣẹ́yún onìṣègùn(MA) tàbí Ìṣẹ́yún pèlú Oògùn Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀ro aláfọwọ́yí
Kí ni ìsẹ́yún pẹ̀lú ògùn(ìsẹ́yún oníṣègùn)? Kí ni ìsẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (Ìsẹ́yún onísé abẹ)?
Ìtumọ̀ Ìsẹ́yún oníṣègùn(tí a máá ń sáábà pè ní ìsẹ́yún pẹ̀lú Ògùn) jẹ́ ọ̀nà ìsẹ́yún àìléwu èyítí obìnrin á lo ògùn nílé láti ṣẹ́ oyún àìfẹ́.
Ètò àìléwu méjì ló wà fún ìsẹ́yún oníṣègùn: Lílo Mifepristone pẹ̀lú Misoprostol, tabi lílo Misoprostol nìkan. safe2choose fọwọ́ sí àwọn ọ̀nà ìsẹ́yún oníṣègùn yí fún oyún tí ó ti tó ọ̀sẹ̀ mẹ̀talá [1], a sì lè rí àwọn àlàyé rè níbí.
Ìsẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí(MVA) jẹ́ ọ̀nà ìsẹ́yún tí kò léwu fún oyún tí ó wà ní oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ pẹ̀lú/tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù mẹ́ta kejì títí dé ọ̀sẹ̀ kẹrìnlá*. (*Iye ọ̀sẹ̀ tí oyún gbọ́dọ̀ jẹ́ fún MVA dálè ilé ìwòsàn àti onímò nípa ètò ìlera tí ó ń ṣe ètò náà). [3]Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ iná jẹ́ ọ̀nà aláìléwu EVA ó sì fẹ́ fara pẹ́ ọ̀nà MVA. A lè lo EVA fún oyún tó wà ní oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́, àti /tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù mẹ́ta èkejì. Ìyàtọ̀ àkọ́kọ́ láàárín EVA àti MVA ni pé iná ni à ń lò láti fi ṣe irinṣẹ́ tí a ó fi yọ oyún. Nítorípé EVA nílò iná, ó le má wà níbi tí àwọn ohun àmúlò kò tíì wọ́pọ̀.

Akọ́sẹ́mọsẹ́ ní ilé ìwòsàn ni ó lè ṣe MVA àti EVA. O lè rí àlàyé nípa ètò náà níbí.

Ìṣẹ́yún onìṣègùn(MA) tàbí Ìṣẹ́yún pèlú Oògùn Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀ro aláfọwọ́yí
Àwọn àǹfààní àti àwọn àléébù ìṣẹ́yún pẹ̀lú oògùn (ìṣẹ́yún onìṣègùn) [1], [2] Àwọn àǹfààní àti àwọn àléébù ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀ro aláfọwọ́yí (MVA tàbí Ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ ) [3], [4]
Ó múnádóko Ó múnádóko pèlú ìpín márùúndínlọ́gọ̀rùún nínú ọgọ́rùún Ó múnádóko pèlú ìpín mọ́kàndínlọ́gọ̀rùún nínú ọgọ́rùún
Ewu Kò léwu Kò léwu
Àyẹ̀wò oyún Kò nílò ayẹ̀wò ilé ọmọ Ò nílò ayẹ̀wò ilé ọmọ láti mọ ọjọ́-orí oyún
Ọjọ́ oyún Ó ṣeé lò fún oyún tó ti tó òsẹ̀ mẹ̀talá
Láti mọ̀ síi nípa ọjọ́-orí oyún rẹ, bẹ ojú-ewé dánilójú àti Ìsirò Oyún wò.
O ṣe lo fun oyun to ti to osẹ mẹ́rìnlá
Láti mọ̀ síi nípa ọjọ́-orí oyún rẹ, bẹ ojú-ewé Ìdaniloju ati Isiro Oyun wo.
Ibi Ó ṣeé ṣe ní kọ́lọ́fín ilé tàbí ibikíbi tí ó bá tẹ́ obìnrin lọ́rùn A má ń ṣeé ní àgó ìwòsàn tàbí ilé ìwòsàn
Ta ló le ṣe é Obìnrin náà le seé fúnra rẹ̀ A nílò akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn láti ṣeé
À̀kókò Iye àkókò tí o fi máa ṣẹ́yún pèlú oògùn le jẹ́ ọjọ́ díẹ̀ sí ọ̀sẹ̀ díẹ̀ Àkókò tí a ó fi ṣe MVA kò ju ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ
Ohun tó le jẹyọ Ẹ̀jẹ̀ le máa dà, kó máa wá, kó máa lọ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́jì tàbí jù béè lọ.
Inù rírun le máa wá, kó máa lọ fún bíi ọ̀sẹ̀ méjì
Lọ́pọ̀ ìgbà ẹ̀jẹ̀ dídá rẹ̀ kò tó ti MA, kò sì kí ń dà ju ọ̀sẹ̀ kan sí méjì lọ.
Lọ́pọ̀ ìgbà inú rírun rẹ̀ kò tó ti MA, kò sì kí ń run ni ju ọ̀sẹ̀ kan sí méjì lọ.
Ewu Àwọn ohun tó le jẹyọ jẹ́: ìsun ẹ̀jẹ̀ tó lágbára, àkóràn, ìtẹ̀síwájú oyún, àti oyún tí kò ṣẹ́ tán. Àwọn ohun tí ó le jẹyọ jẹ́: ẹ̀jẹ̀ dídá gidi, àkóràn, ìjàmbá sí ilé ọmọ àti àwọn ẹ̀yà tó sún mọ́, oyún tí kò ṣẹ́ tán, oyún tí kò ṣẹ́, ati ikú
Iye MA ò gbówó lórí tó MVA nítorípé ó níí ṣe pẹ̀lú rìra ògùn. Kò nílò àyẹ̀wò ilé ọmọ tó tún gbówó lórí. Dédé iye owó MA le yàtò gedegbe nítorí ibi tí o wà àti bóyá àwọn ògùn náà wà lórí igbá ní ilé olóògùntàbí kò sí, tàbí ó ṣeé rà nípasẹ̀ ètò oníṣègùn nìkan. MVA gbówó lórí ju MA lọ nítorípé MVA nílò àwọn àyẹ̀wò kan (bíi àyẹ̀wò ilé ọmọ) àti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí yóò ṣeé. Dédé iye owó MVA le yàtò gedegbe nítorí ibi tí o wà àti bóyá òfin fi àyè sílè fún oyún ṣíṣẹ́
Ìtọ́jú lẹ́yìn Ìṣẹ́yún A gbà ọ níyànjú láti máa lọ sí ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí o bá parí láti ríi dájú pé MA náà jẹ́ àṣeyọrí. Kí àwọn obìnrin kàn sí ilé
ìwòsàn wọn tí wọ́n bá ní ìrírí: ìsun ẹ̀jẹ̀ tó lágbára, ibà, ara ríro gidi, atọ́ka àkóràn tàbí oyún tí kò ṣẹ́.
Àyẹ̀wò ìtó máa fihàn wípé o kò lóyún lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́rin sí mẹ́fà tí ìṣẹ́yún náà bá jẹ́ àṣeyọrí.
O lè rí àlàyé síi nípa ìtọ́jú ìlera lẹ́yìn ìṣẹ́yún olóògùn níbí.
A má ń dábàá pé kí o lo sí ilé ìwòsàn nígbà míràn àmọ́ kò pa dandan.
Kí àwọn obìnrin kàn sí ilé ìwòsàn wọn tí wọ́n bá ní ìrírí: ìsun ẹ̀jẹ̀ tó lágbára, ibà, ara ríro gidi, atọ́ka àkóràn tàbí oyún tí kò ṣẹ́.
Àyẹ̀wò ìtó máa fihàn wípé o kò lóyún lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì sí mẹ́ta lẹ́yìn ìṣẹ́yún náà.
Ní gbogbo ìgbà, àwọn obìnrin le padà sí iṣẹ́ òjọ́ wọn lẹ́yìn ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ tí ara wọn bá gbà á
O lè rí àlàyé síi nípa ìtọ́jú ìlera lẹ́yìn ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí níbí.
Ìtọ́jú Ìdènà Oyún A lè bẹ̀rẹ̀ ogunlọ́gọ̀ ọ̀nà ìdènà oyún ní kété tí a bá parí ìṣẹ́yún olóògùn, àmọ́ a kò le ṣe ti òrùka ojú ara àti IUD
Láti wá ọ̀nà ìdènà oyún tí ó wù ọ, lo www.findmymethod.org
A lè bẹ̀rẹ̀ ogunlọ́gọ̀ ọ̀nà ìdènà oyún ní kété tí a bá parí ìṣẹ́yún olóògùn, àmọ́ a kò le ṣe ti òrùka ojú ara àti IUD.
Láti wá ọ̀nà ìdènà oyún tí ó wù ọ, lo www.findmymethod.org

Àwọn òǹkọwé:

Ńipasẹ̀ ikọ̀ safe2choose àti àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní carafem, ní ìbámu pẹ̀lú ìmòràn Ìgbìmò Àpapò lórí ètò Owó fún Ìṣẹ́yún(NAF) ní ọdún 2020, ìmọ̀ràn àjọ Ipas ní ọdún 2019 àti ìmọ̀ràn WHO ní ọdún 2012

Ìjọba orílè-èdè gbogboògbò lọ́rí ìsẹ́yún jẹ́ ẹgbẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ abánisẹ́yún ní Àríwá Amẹ́ríkà

carafem ń pèsè ètò ìṣẹ́yún àti ìfètò sọ́mọ bíbí tí ó rọrùn tí ó sì dájú kí àwọn ènìyàn le ṣàkóso iye àti àyè tó wà láàárín àwọn ọmọ wọn

Ipas jẹ́ àgbárí òkèèré kan ṣoṣo tí ó gbájúmọ́ fífi ètò sí oyún ṣíṣẹ́ tí kò léwu àti ìbójútó èlà mágboyín

WHO jẹ́ abẹ̀wẹ̀ alámọ̀já ti Àjọ Àgbáyé tó wà lákoso ìlera àwùjọ ẹ̀dá káríayé

[1] National Abortion Federation (NAF). Clinical Policy Guidelines for Abortion Care. 2020. Retrieved from: https://5aa1b2xfmfh2e2mk03kk8rsx-wpengine.netdna-ssl.com/wp-content/uploads/2020_cpgs_final.pdf

[2] Gynuity. Providing medical abortion in low-resource settings An Introductory Guidebook. Second Edition. 2009. Retrieved from: https://gynuity.org/assets/resources/clinguide_maguide2nd_edition_en.pdf

[3] World Health Organization (WHO). Safe abortion: technical and policy guidance for health systems, second edition. 2012. Retrieved from: https://apps.who.int/iris/bitstream/handle/10665/70914/9789241548434_eng.pdf;jsessionid=F77B761669FC579124C1E9CA2CC3CFDB?sequence=1

[4] Ipas. Clinical Updates in Reproductive Health. 2019. Retrieved from: https://ipas.azureedge.net/files/CURHE19-april-ClinicalUpdatesInReproductiveHealth.pdf

Safe Abortion with Pills Options