Oríṣìríṣi Ìtọ́jú ìṣẹ́yún / Ìṣéyún nínú ilé Ìwòsàn
Ìṣéyún nínú ilé Ìwòsàn jẹ́ ìlànà ìṣègùn tí a ń lò fún ìṣẹ́yún tàbí tọ́jú oyún tí ó wálẹ̀. A máa ń pè é ní Ìṣẹ́yún pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ (surgical abortion) tàbí ìṣẹ́yún pẹ̀lú ìlànà (procedural abortion), tí wọ́n tún lè tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí orúkọ ọ̀nà tí a lò, bíi ìṣẹ́yún àfàmọ́ra agbára afẹ́fẹ́ (aspiration abortion).
GBOGBO OHUN TI O NILO LATI MỌ
Kí ni Ìṣẹ́yún nínú ilé Ìwòsàn?
Ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn jẹ́ Ìlànà Ìṣègùn tó ń lo irin iṣẹ́ tàbí ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ láti fòpin sí oyún tàbí tọ́jú oyún tí ó wálẹ̀. Àwọn olùpèsè ìlera tó kọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni yí ó ṣe nínú kílíníkì tàbí ilé ìwòsàn.
Ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn jẹ́ ìlànà tí a ń ṣe ní kílíníkì tàbí ilé ìwòsàn láti ọwọ́ àwọn olùpèsè ìtọ́jú ìlera tí ó kọ́ṣẹ́mọṣẹ́. Àwọn ìlànà yí jẹ́ aláìléwu ti ó sì dára jùlọ ní ìdá mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ààbò àti ìrírí le yàtọ̀ gẹ́gẹ́bí irú ọ̀nà pàtó tí a lò àti bí oyún náà sì ti dàgbà sí.
Ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ lílo òògùn tàbí ọ̀nà ìṣègùn láti ṣí ọ̀nạ̀ ilé ọmọ sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀ (tí à ń pè ní Dilation). Ní kété tí ọ̀nà ilé ọmọ bá ti ṣí sílẹ̀, a ó yọ oyún náà kúrò nínú ilé ọmọ nípa ẹ̀rọ afẹ́fẹ́, ohun èlò iṣẹ́ abẹ, tàbí ìfàsílẹ̀ ìrọbí láti parí ìyọkúrò náà.
Àwọn ìlànà míràn ma ń yá kíá, a sì le parí rẹ̀ lórí ipele ìtọ́jú aláìníbẹ̀wò, nígbàtí àwọn míràn le nílò kí ènìyàn náà dúró sí kílíníkì tàbí ilé ìwòsàn fún àbojútó àti ìmúpadàbọ̀sípò, pàápàá jùlọ ní àwọn ipele tí ó tẹ̀lé ìlóyún.
Kíni àwọn oríṣìríṣi ọ̀nà ti ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn?
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà tí a le fi ṣe ìṣẹ́yún ninu ile iwosan ló wà, ìwọ sì lè yàn níbẹ̀, ó sì má ń níṣe pẹ̀lú oṣù tí oyún bá wà. Nítorí àyípadà má ń wà nínú àsìkò tí oyún yóó fi wá nínú fún oríṣiríṣi ọ̀nà ìṣẹ́yún, ìpinnu náà le dá lórí agbègbè tí o wà, wíwà ohun èlò àti olùpèsè àti èyí tí ó bá wù ọ́.
ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ aláfọwọ́yí (MVA) jẹ́ ọ̀nà tí a ń gbà yọ nǹkan tó wà nínú ilé ọmọ, a sì má ń lòó fún oyún tí kò ju ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sì mẹ́rìnlá lọ lọ́pọ̀ ìgbà.
Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ oníná (EVA) jẹ́ ọ̀nà tí a ń gbà yọ nǹkan tó wà nínú ilé ọmọ, a sì má ń lòó fún oyún tí kò ju ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀dógún lọ
A má ń lo ètò líla ẹnu ilé ọmọ àti yíyọ gbogbo nǹkan tó wà nínú ilé ọmọ fún oyún tí ó ti kọjá ọ̀sẹ̀ mẹ́rìnlá
Lọ́pọ̀ ìgbà bí a bá ṣẹ́yún nípa fífa ìrọbí a má ń lòó fún oyún tó ti kọjá oṣù mẹ́rìndínlógún.
Líla ẹnu ilé ọmọ àti ìmúláradá jẹ́ ètò ìṣẹ́yún ìgbà àtijọ́ tí a sì ti fi ètò yíyọ nǹkan tó wà nínú ilé ọmọ, ìṣẹ́yún pẹ̀lú àfàmọ́ra agbára afẹ́fẹ́ àti ètò líla ẹnu ilé ọmọ (D&E) rọ́pò rẹ̀.
Wo àti kí o ṣe ìgbàsílẹ̀ àwòrán àlàyé wa nípa àwọn ọ̀nà ìṣẹ́yún tó yẹ fún ipele ọjọ́ orí oyún kọ̀ọ́kan
Kí ni ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ oníná (EVA) ?
Ṣawari alayeTọju alaye
Ki ní ètò ìṣẹ́yún líla ẹnu ilé ọmọ àti yíyọ gbogbi nǹkan tó wà nínú rẹ̀?
Ṣawari alayeTọju alaye
Kí ni ìṣẹ́yún bí ìrọbí?
Ṣawari alayeTọju alaye
kini iseyun Líla ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ ati Ìyọkúrò (D&C)?
AtijọṢawari alayeTọju alaye
AILEWU ATI MUNADOKO
Ṣé ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn jẹ́ àìléwu?
Ìṣẹ́yún ninu ile iwosan kò léwu bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn bá ṣeé.
Àwọn ilé ìwòsàn tí ó ń ṣe ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn gbọ́dọ̀ tèlé ìlànà ìgbédéke ìṣègùn tó dá lórí àwọn ìlànà ti orílẹ̀-èdè àti ìlànà àgbáláyé, bi ti ìlànà ìtọ́jú ìlera ti àjọ ìlera àgbáyé (WHO) àti àlayé kílíníkì ti Ipas
Àwọn ìlànà yí wà láti ri dájú pé ààbò àti ìtọ́jú tó péye wà nípa:
- Tani ó le ṣètò ìṣẹ́yún
- ìṣàkóso òògùn ìṣẹ́yún
- ṣíṣe ìtọ́jú àti ìpamọ́ ohun èlò
- ìṣàkóso gbogbo ìdọ̀tí ìṣègùn
- ìdánilẹ́kọ̀ọ́, àti àgbéyẹ̀wò àwọn òsìsẹ́ ìtọ́jú ìlera
Àwọn ti tó fẹ́ se iṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn gbọ́dọ̀ ríi dájú pé ilé ìwòsàn tí wọ́n yàn ń lo ọ̀nà ìṣẹ́yún tí kò léwu, ọ̀nà tí a fi ọwọ́ sí ti wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà ìṣègùn tó dáńgájíá láti dábòbò ìlera rẹ àti àgọ́ ara rẹ.
ÀWỌN EWU ÀTI ÀMÌ ÌKÌLỌ̀
Kí ni àwọn ewu àti ìnira tí a gbọ́dọ̀ fiyèsí nínú ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn?
Tí a bá ṣe láti ọwọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n onísẹ́ ìlera ní ilé iṣẹ́ tí a fọwọ́ sí tí o sì ní ààyè sí àwọn irinṣẹ́ tí ó yẹ, ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn jẹ́ àìléwu tí kò sì ní ewu tó pọ̀. Fún àpẹẹrẹ, ìṣẹ́yún pẹ̀lú àfàmọ́ra agbára afẹ́fẹ́ múnádóko ó sì jẹ́ àìléwu, pẹ̀lú ìwọ̀n àṣeyọrí tí ó ju ìdá méjì-dín-lọ́gọ́rùn sí mọ́kàndínlọ́gọ́rùn ti àwọn iye ewu kò tó ìdá kan nínú ọgọ́rùn. Bí ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn ṣe jẹ́ aláìléwu tó, àwọn ewu díẹ̀ sọ mọ́ ètò náà bíi: ìsun ẹ̀jẹ̀, àkóràn, ìpalára fún ilé ọmọ àti àwọn ẹ̀yà tó wà láyìíká rẹ̀, oyún tí kò ṣe tán, oyún tó ń dàgbà síi àti ikú.
Púpọ̀ nínú àwọ́n eewu wònyí kò la ti ẹ̀mí lọ a sì le tọ́jú rẹ̀. Ìdí nì yí tí ó fi jé wípé àkíyèsi àwọn ààmì ìkìlọ̀ ṣe pàtàkì.
Tí o bá ní ìrírí àwọn ààmì tàbí ààmì àìsàn wọ̀nyí, wá ìtọ́jú ìṣègùn lẹ́ṣẹ̀kẹṣẹ̀
ẹ̀jẹ̀ tí ó wúwo tàbí ìsun ẹ̀jẹ̀ (kíkún páádì méjì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, fún wákàtí kan, fún àwọn wákàtí méjì ní ọ̀nà kan tàbí díẹ̀ sii);
- •
ibà (tí ó ju 38 ° C tàbí 100.4 ° F) fún ẃakàtí mẹ́rin-lé-lógún lẹ́hìn ìlànà náà (ó le ṣe àfihàn àkóràn);
- •
Ìrora gidi tí ń lágbára síi ní ìbàdí tàbí ìkánra inú, tí kò dínkù lẹ́hìn tí o lo òògùn ìrora; àti
- •
Àmì oyún yóò ma farahàn síwájú síi (èébì, ọmú rírọ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ)
- •
Àmì oyún yóò ma farahàn síwájú síi (èébì, ọmú rírọ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ)
ÀWỌN ÀBÁYỌRÍ TÍ O WỌ́PỌ̀
Kí ni àwọn àbájáde tí ó le jẹyọ lẹ́yìn ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn?
Ọ̀pọlọ̀pọ̀ ènìyàn ma ń ní ìmọ̀lára ìrora inú tí ó lágbára àti ìrírí ìṣàn ẹ̀jẹ̀ ní gbà tí wọ́n bá n ṣe ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn, pàápàa ́jùlọ nígbàtí ọ̀nà ilé ọmọ bá ṣí sílẹ̀ (tí ó ti sị́) àti nígbà ìlànà náa.̀ Ìrora inú yíì le dínkù lẹ́hìn tí ìṣẹ́yún náà bá parí, sùgbọ́n ó jẹ́ oun tí ó ṣe déédée ́tí ìrora inú àti ìṣàn ẹ̀jẹ̀ le wáyé fún ọjọ́ tàbi ọ̀ṣẹ̀ díẹ̀. Tí o bá lo misoprostol láti ṣí ọ̀nà ilé ọmo, ó le fa àwọn àbájàde kọ̀ọ̀kan bi ìrírí èèbì, èèbì, ìgbẹ́ gbuuru, ibà tàbí òtútù.
Òògùn ìtùnú ìrora ìbílẹ̀ ni a ṣáábà ma ń lò láti mú kí ìrora dínkù ní agbègbè ọ̀nà ilé ọmọ. Èyí ma n ́jẹ́ kí ìlànà náà rọrùn kí ó sì mú ìrora kúrò.
Ó jẹ́ oun tó ṣe déédéé láti ní orísị̀ríṣi ìrírí ìmọ́lara lẹ́hìn náà. Àwọn míràn ma ní ìtùnú, ẹlòmíràn ma ń ní ìbànújẹ́ ọkàn tàbí àpapọ̀ méjèèjì. Tí o bá nílò ìrànlọ́wọ́ tàbí ò ń wá ẹni tí o le bá sọ̀rọ̀, ó dára láti <counselingLink>kàn sí wa fún ìrànlọ́wọ́.</counselingLink>
ÀWỌN Ọ̀NÀ ÌṢÀKÓSỌ ÌRORA
Ǹjẹ́ ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn nira?
Ọ̀pọlọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ma ń ní ìrora tàbí ìrora inú nígbà tí wọ́n n ṣe ìlànà ìṣẹ́yún pẹ̀lú àfámọra agbára afẹ́fẹ́ tàbí ìṣéyún pẹ̀lu ́iṣẹ́ abẹ. Fún ọ̀pọlọ̀pọ̀, ìrora inú náà ma ń tètè dínkù lẹ́hìn náà sùgbọ́n àwọn ènìyàn míràn le ní ìrora inú tí ó wá tí ó sì ń lọ fún ọjọ́ díẹ̀ sí ọ̀sẹ̀ díẹ̀. Ìrora yìí ṣáábà ma ń ṣẹlẹ̀ nítorípé ọ̀nà ilé ọmọ náà ṣí sílẹ̀ tí ilé ọmọ sì ń fún pọ̀.
Tí ènìyàn bá ṣe ní ìrírí ìrora si dá lórí bí oyún náà ti dàgbà sí, agbára àti faramọ́ ìrora gẹ́gẹ́bí ọlọ́dani, bóyá ó ti bímọ tẹ́lẹ̀ rí tàbí o ń bẹ̀rù. Gbogbo ènìyàn ló ń ní ìrírí ìrora ní ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Àwọn ọ̀nà ìṣákoso ìrora gbudọ̀ wà. O lè gba òògùn ṣáájú tàbí nígbà tí o bá ń ṣe ìlànà yìí, kí o sì mú lọ sí ilé láti lò tó bá yá tí o bá nílò rẹ̀.
Irú òògùn ìtùnú ìrora wo ni wọ́n ma ń lò fún ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn?
Oríṣiríṣi òògùn tí kìí jẹ́ ká nímọ̀lára ìrora tí a lè lo fún ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn ló wà, oṣù tí oyún bá sì wà ni yóò sọ ọ̀nà tí a ó lò, àti wíwà àwọn olùṣàkóso òògùn náà ní ilé ìwòsàn.
Àwọn ọ̀nà òògùn ìtùnú ìrora tí ó wà ni:
Abẹ́rẹ́ òògùn tí kìí jẹ́ ká nímọ̀lára ìrora tí ìbílẹ̀:
Èyí ni òogùn tí kìí jẹ́ ká fura tó wọ́pọ̀ jùlọ fún ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn. Ó jẹ́ òogùn tí kìí jẹ́ kí ẹ̀yà ara ṣiṣẹ́, tí a má ń gún pẹ̀lú abẹ́rẹ́ sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ kí ó le rọrùn nígbàtí a bá ń ṣe é. Ojú obìnrin náà yóò wà ní lílà yóò sì mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ
Ògùn ìfọ̀kànbalẹ̀ níwọ̀ntunwọ̀nsì:
Èyí ni ògùn tí kìí jẹ́ kí a fura tí à ń darí tààrà sínú iṣan, ó sì má ń jẹ́ kí mímọ ohun tó ń lọ lágòó ara obìnrin náà ó dín kù díẹ̀ díẹ̀. Yóò máa dáhùn sí ọ̀rọ̀ ẹnu lóòrèkóòrè.
Ògùn ìfọ̀kànbalẹ̀ tí ó jinlẹ̀:
Èyí ni ògùn tí kìí jẹ́ kí a fura tí à ń darí tààrà sínú iṣan, ó sì má ń jẹ́ kí mímọ ohun tó ń lọ lágòó ara obìnrin náà ó dín kù díẹ̀ díẹ̀. Yóò máa dáhùn sí ọ̀rọ̀ ẹnu lóòrèkóòrè.
Ògùn gbogboogbò tí kìí jẹ́ ká fura:
Èyí le lo àkójọpọ̀ gígùn pẹ̀lú abẹ́rẹ́ tàbí fífa àwọn ògùn tí kìí jẹ́ ka fura símú. Kì yóò dáhùn sí ọ̀rọ̀ ẹnu.
ÌTỌ́JÚ LẸ́YÌN ÌṢẸ́YÚN
Ìtọ́jú lẹ́yìn ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn àti ọ̀nà ìfètò sọ́mọ bíbí
lẹ́hìn ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn, àbẹ̀wò fún ìtèlé ló ṣáábà ma ń tẹ̀le sùgbọ́n kí ṣe dandan, kí ẹnikọ̀ọkan tẹ́tí sí àmọ̀ràn olùpèsè ìtọ́jú ìlera wọn.
Kò sí iye àkókò kan pàtó ti a fi di re mule ninu isegun tí obìnrin ní láti fi dúró tí yóò fi máa ṣe àwọn ìṣẹ́ pàtó bíi: ìwẹ̀ wíwẹ̀, eré ìdárayá, ìbálòpọ̀ tàbí wíwọ àwòtẹ́lẹ́ nǹkan oṣù tí ó má ń wọ ojú ara. Lápapò, a gbáà ní ìmọ̀ràn pé títí tí ẹ̀jẹ̀ náà yóò fi dá lẹ́yìn oyún ṣíṣẹ́ náà, kí obìnrin náà ṣọ́ra láti máa ki àwọn nǹkan bíi àwòtẹ́lẹ́ nǹkan oṣù tí ó má ń wọ ojú ara lọ, agolo nǹkan oṣù tí má ń wọ ojú ara lọ, kí wọ́n sí ṣọ́ra fún iṣẹ́ alágbára. Obìnrin kọ̀ọ̀kan le padà sí iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ tí agbára rẹ̀ bá gbẹ, obìnrin a sì máa yàtọ̀ síra.
Kí o tó kúrò ní ilé ìwòsàn, ó yẹ kí á ṣàlàyé nípa ọ̀nà tí o kò fi ní lóyún. Àwọn ọ̀nà tí o lè gbà tí o kò fi ní lóyún le bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ síbésíbẹ̀, ìjíròrò yẹ kó wáyé nípa obìnrin kọ̀ọ̀kan àti ọ̀nà tí ó yàn. Ó yẹ kí ilé ìwòsàn ó pèsè ibi tí wọn yóò ma pè sí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wọn ní ìbéèrè tàbí ìfiyèsí lẹ́yìn oyún ṣíṣẹ́.
Láti wá ọ̀nà ìdènà oyún tí ó yẹ fún, sàbẹ̀wò sí findmymethod.org
ÀWỌN OHUN ÈLÒ TÍ Ó WÚLÒ
Ṣe ìgbàsílẹ̀ Àwọn ohun èlò:
Àwọn Ìbéérè tí wọ́n maa ń bèèrè lọ́pọ̀ ìgbà lórí ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ afẹ́fẹ́ aláfọwọ́yí (MVA)
Àtìlẹ́yìn Ìmọ̀ràn Ìṣẹ́yún aìléwu
Ó dára láti béèrè fún àtìlẹ́yìn. for Support
A ń pèsè ìròyìn tó dá lórí ẹ̀rí nípa ìṣẹ́yún tó dáàbò bò. Ìṣẹ̀ ìmọ̀ràn wa tó ṣàdédé jẹ́ ẹni kìíní, aládàbò, rọrùn, àti láìsí ìdájọ́. A ń dúró de ìfiranṣẹ́ rẹ!
Nípasẹ̀ ẹgbẹ́ safe2choose àti àwọn amòye alátìlẹ́yìn ní carafem, lórí Ìtọ́sọ́nà Ìtọ́jú Ìṣẹ́yún ti 2022 nípasẹ̀ WHO, Àwọn ìmúdójúìwọ̀n Ilé-ìwòsàn 2023 ní Ìlèra Ìbísí nípasẹ̀ Ipas, àti Àwọn Ìtọ́sọ́nà Àfihàn Ilé-ìwòsàn 2024 fún Ìtọ́jú Ìṣẹ́yún nípasẹ̀ NAF.
safe2choose ní àtìlẹ́yìn nípasẹ̀ Ìgbìmọ̀ Ìmọ̀ràn Ìṣègùn tí a ṣẹ̀dá nípasẹ̀ àwọn amòye asíwájú ní aayé ti ìlera ìbálòpọ̀ àti ìbísí àti àwọn ẹ̀tọ́ (SRHR).
Carafem ń pèsè ìtọ́jú ìṣẹ́yún tó rọrùn àti tó pèsè eré-ọkò tó gbéga, àti ìṣètò ìdílé, kí àwọn ènìyàn lè ṣàkóso nípa iye àti ìpínà àwọn ọmọ wọn.
IPAS jẹ́ àjọ àgbáyé tó dá lé àgbéga ìrísí sí ìṣẹ́yún tó dáàbò bò àti ìtọ́jú ẹ̀dá ìbímọ.
WHO – jẹ́ àjọ pàtàkì kan ní ìsàkóso àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé fún ilé-èrò ìlera àgbáyé.
NAF – Ẹgbẹ Orilẹ̀-èdè fún Ìseyun – jẹ́ àjọ amọ̀ja ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí ń ṣe àtìlẹ́yìn fún ìtọju ìṣètòyà ọmọ tó dá lórí ẹ̀rí àmọ̀ràn tó dájú àti ẹ̀tọ́ ìbí ọmọ.
[1] "Abortion care guideline." World Health Organization, 2022, Retrieved from: srhr.org/abortioncare/.
[2] Jackson, E. "Clinical Updates in Reproductive Health." Ipas, 2023, Retrieved from: www.ipas.org/wp-content/uploads/2023/09/Ipas-Clinical-Updates-in-Reproductive-Health-CURHE23b.pdf Accessed November 2024.
[3] "Clinical Policy Guidelines." National Abortion Federation, 2024, Retrieved from: prochoice.org/providers/quality-standards/.
[4] "Clinical practice handbook for quality abortion care". Geneva: World Health
Organization; 2023. Licence: CC BY-NC-SA 3.0 IGO. Retrieved from: https://iris.who.int/bitstream/handle/10665/369488/9789240075207-eng.pdf?sequence=1
[5] Weitz, T. A., Taylor, D., Desai, S., Upadhyay, U. D., Waldman, J., Battistelli, M. F., & Drey, E. A. (2013). Safety of aspiration abortion performed by nurse practitioners, certified nurse midwives, and physician assistants under a California legal waiver. American Journal of Public Health, 103(3), 454-461. Retrieved from: https://www.ncbi.nlm.nih.gov/pmc/articles/PMC3673521/
