Ògùn ìsẹ́yún tàbí Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀ro aláfọwọ́yí: èwo ni ó dára fún mi?
Ní tábìlì yìí, à ń ṣe àfiwé láàrin àwọn àǹfààní àti àléébù ìsẹ́yún pẹ̀lú Ògùn àti yíyọ oyún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí(Ọlọ́wọ́ tàbí Oníná). Ó sì wà lọ́wọ́ àwọn obìnrin láti pinu èyí tí ó dára jùlọ gẹ́gẹ́bí ìsúná, ààyè, ibùgbé, ọ̀sẹ̀ tí oyún jẹ́ àti ohun tí ó yàn fúnra rẹ̀
Yíyàn ọ̀nà ìṣẹ́yún tí ó dára jù
Ìṣẹ́yún ìṣègùn(MA) tàbí Ìṣẹ́yún pèlú Oògùn
Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀ro aláfọwọ́yí
| Kí ni ìsẹ́yún pẹ̀lú ògùn(ìsẹ́yún oníṣègùn)? | Kí ni ìsẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (Ìṣẹ́yún ní ilé ìwòsàn)? | |
|---|---|---|
| Ìtumọ̀ | ||
| Ìtumọ̀ | Ìsẹ́yún oníṣègùn, tí a máá ń sáábà pè ní ìsẹ́yún pẹ̀lú Ògùn jẹ́ ọ̀nà ìsẹ́yún àìléwu láti f’òpin sí oyún àìfẹ́. Ó dá lórí lílo ògùn láti dẹ́kùn oyún náà kí ó má ba dàgbà tí ó sì mú kí ilé ọmọ kó fún pọ̀, tí se ìrànlọ́wọ́ láti mu oyún náà jade Àṣàyàn àìléwu méjì ló wà fún ìsẹ́yún oníṣègùn tí ìṣègùn fọwọ́ sí:
Safe2choose ń pèsè ìtọ́sọ́nà pẹ̀lú àrídájú lórí bí o se le se ìṣẹ́yún oníṣègùn lọ́wọ́ ara rẹ nípa lílo ọ̀kan nínú àwọn ònà yìí. | Ìsẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí(MVA) jẹ́ ọ̀nà ìsẹ́yún tí kò léwu fún oyún tí ó wà ní oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ pẹ̀lú/tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù mẹ́ta kejì.Oníṣègùn tó kọ́ ṣẹ́ mọ ṣẹ́ ni yó lo èrọ ìṣègùn kan láti ṣe ìfà tó rọrùn tí yó mú ohun tó wà ní ilé ọmọ kúrò. A lè se ìlànà yìí pèlú ọlọ́wọ́ nípa lílo ẹ̀rọ IPAS tàbí pẹ̀lú ẹ̀rọ oníná tí a mọ̀ si ẹ̀rọ aláfọwọ́yí oníná (EVA). Ọ̀nà méjèèjì ni ó da tí a sì fọwọ́ sí. O lè rí àlàyé tó péye àti bi ìlànà náà ti ń sisẹ́, ohun láti retí, àti àwọn àlàyé pàtàkì, lórí "ojúìwé ìlànà sí ìṣẹ́yún aìléwu pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí(MVA)" |
| Àwọn àǹfààní àti àwọn àléébù ìṣẹ́yún pẹ̀lú oògùn (ìṣẹ́yún onìṣègùn) | Àwọn àǹfààní àti àwọn àléébù ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀ro aláfọwọ́yí (ìṣẹ́yún pẹ̀lú ìlànà ) | |
|---|---|---|
| Ìmúnádoko | ||
| Ìmúnádoko | Ìlànà lílo Mifepristone àti Misoprostol múnádóko ní ìdá márùúndínlọ́gọ̀rùún nínú ọgọ́rùún. Ìlànà lílo Misoprostol múnádóko ní ìdá márùúndínlàádọ́rùn si mẹ́tàléníàádọ́rùn nínú ọgọ́rùún | MVA múnádóko ní ìdá méjìdínlọ́gọ̀rùún sí mọ́kàndínlọ́gọ̀rùún nínú ọgọ́rùún |
| Ààbò | ||
| Ààbò | Kò léwu | Kò léwu |
| Àyẹ̀wò oyún | ||
| Àyẹ̀wò oyún | Fìdí oyún múlẹ̀ kí o tó lo ògùn yìí Kò nìlò Unltrasoundi | O nílò àyẹ̀wò ara,ilé ìwòsàn rẹ le ní kí o se ultrasoundi |
| Òdiwọ̀n ọjọ́ orí oyún | ||
| Òdiwọ̀n ọjọ́ orí oyún | O lè lo ògùn ìṣẹ́yún ní gbà kígbà ipele oyún. Sùgbọ́n, iye ìwọ̀n ògùn tí o nílò, irú ìtọ́jú, àti àwọn eewu tí ó wà níbẹ̀ le yàtọ̀ gẹ́gẹ́bí oyún náà ti dàgbà sí. Fún oyún tí ó tó ọ̀sẹ̀ mẹ́tàlá,o lè lo ògùn ìṣẹ́yún ní aìléwu nínú ilé, olóyún náà sì le bojútó ìṣẹ́yún náà,o lè wo àwọn fídíò wa lórí ọ̀nà bí a se lè ṣé láti kọ́ ìmọ̀ si. Fún oyún tó ju ọ̀sẹ̀ mẹ́tàlá lọ, ìṣẹ́yún onísègùn nílò ìtọ́jú àrà ọ̀tọ̀ àti ọ̀nà míìràn. Jọ̀wọ́, kàn sí ẹgbẹ́ olùgbani-ni-̀mọ̀ràn wa fún àtìlẹ́yìn. Láti mọ̀ b́i oyún náà ti dàgbà sí, lo ẹ̀rọ ìṣirò oyún wa. | O le se Ìsẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA) títí dé ọ̀sẹ̀ kẹrìnlá oyún nígbàtí o sì le lo ẹ̀rọ aláfọwọ́yí oníná (EVA) títí dé ọ̀sẹ̀ kẹrìndínlógún oyún Àkíyèsi: òdiwọ̀n ojó orí fún lílo ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA) le yàtọ̀ sí ra gẹ́gẹ́bí ilé ìwòsàn àti onísègùn tí yó ṣe isé náà Láti mọ̀ b́i oyún náà ti dàgbà sí, ṣàbẹ̀wò si ojúewé ẹ̀rọ ìṣirò oyún wa. |
| Ibi | ||
| Ibi | Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ògùn le selẹ̀ ní oríṣìíríṣìí ibi, èyí tí ó dá lórí bí oyún náà ti dàgbà sí àti ìlera ẹni nàá. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ó má ń wáyé ní ìkọ̀kọ̀ ilé wọn, tàbí ibikíbi tí wọ́n ti wà ní aìléwu tí ó sì rọrùn.Nígbà míìràn, ìṣẹ́yún onísègùn le wáyé ní bi tí ońisègùn ti pèsè, níbití ẹni náà ma dúró fún ìgbà díẹ̀ kí dókítà, nọ́ọ̀sì, tàbí ẹnikejì le ma yẹ̀ wọ́n wo títí tí ìlànà náa ̀yó fi parí | A má ń ṣeé ìlànà náà ní ọ́fìsì dókìtà, ilé ìtọ́jú kékeré tàbí ilé ìwòsàn. A lè se irú àwọn ẹ̀rọ aláfọwọ́yí yìí ní ilé ilera, o sì nilò láti sùn ibẹ̀ mọ́jú |
| Ta ló le ṣe é | ||
| Ta ló le ṣe é | o lè ṣàkóso rẹ̀ fúnra rẹ, èyí túmọ̀ sí pé obìnrin tó lóyún, ọ̀mọ̀bìnrin tàbí ènìyàn tó lóyún le ṣé fúnra ra wọn. Òṣìṣẹ́ iṣ̀ègùn tàbí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera àdúgbò le ṣé | A lè pèsè rẹ̀ ní ọ̀nà aìléwu láti ọwọ́ ońisègùn, àwọn nọ́ọ̀sì onímọ̀, àwọn agbẹ̀bí nọ́ọ̀sì, àwọn aṣáájú ìtọ́jú (PAs) àti ẹlòmíràn tí wọ́n ti kọ́ ẹ̀kọ́ tó yẹ |
| À̀kókò | ||
| À̀kókò | Iye àkókò tí o fi máa ṣẹ́yún pèlú oògùn le jẹ́ ọjọ́ díẹ̀ sí ọ̀sẹ̀ díẹ̀ | Àkókò tí a ó fi ṣe MVA kò ju ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ |
| Ohun tó le jẹyọ | ||
| Ohun tó le jẹyọ | Leyin ti o ti lo ogun iseyun, inu le ma run ki eje si ma da ni kete ti o di ogbon (30) iseju sugbon o le to wakati merinlelogun ki o to bere. Inu rirun to le je oun ti o wopo. O le lo ogun irora ninu gbogbo ilana yi. Eje na le dabi nkan osu re tabi ki o ju be lo, o si le ma wa ko tun lo fun ose meji tabi ju be lo. Ohun to le jeyo miran ti o le ni leyin ti o lo ogun naa ni igbe gbuuru, ife lati bi, eebi, oyi oju, inu rirun, ori fifo,iba tabi otutu. Awon wonyi yi o lo leyin wakati merinlelogun leyin ti o lo iwon ogun misoprostol to kehin. | Ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ní ìjẹ̀ ẹ̀jẹ̀ àti ìrora ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà àti lẹ́yìn ìṣẹ̀ abọ́ṣọ́nù (vacuum aspiration). Àwọn ààmì wọ̀nyí máa ń dínkù lẹ́yìn àwọn ọjọ́ díẹ̀, ṣùgbọ́n ó lè gba ọ̀sẹ̀ 1 sí 2 kí ìjẹ̀ ẹ̀jẹ̀, ìjẹ̀pẹ̀lẹ̀ (spotting), àti ìrora parí patapata. |
| Ewu | ||
| Ewu | Àwọn ohun tó le jẹyọ jẹ́: ìsun ẹ̀jẹ̀ tó lágbára, àkóràn, ìtẹ̀síwájú oyún, àti oyún tí kò ṣẹ́ tán. | Àwọn ohun tí ó le jẹyọ jẹ́: ẹ̀jẹ̀ dídá gidi, àkóràn, ìjàmbá sí ilé ọmọ àti àwọn ẹ̀yà tó sún mọ́, oyún tí kò ṣẹ́ tán, oyún tí kò ṣẹ́, ati ikú |
| Iye | ||
| Iye | MA ò gbówó lórí tó MVA nítorípé ó níí ṣe pẹ̀lú rìra ògùn. Kò nílò àyẹ̀wò ilé ọmọ tó tún gbówó lórí. Dédé iye owó MA le yàtò gedegbe nítorí ibi tí o wà àti bóyá àwọn ògùn náà wà lórí igbá ní ilé olóògùntàbí kò sí, tàbí ó ṣeé rà nípasẹ̀ ètò oníṣègùn nìkan. | MVA gbówó lórí ju MA lọ nítorípé MVA nílò àwọn àyẹ̀wò kan (bíi àyẹ̀wò ilé ọmọ) àti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí yóò ṣeé. Dédé iye owó MVA le yàtò gedegbe nítorí ibi tí o wà àti bóyá òfin fi àyè sílè fún oyún ṣíṣẹ́ |
| Ìtọ́jú lẹ́yìn Ìṣẹ́yún | ||
| Ìtọ́jú lẹ́yìn Ìṣẹ́yún | A gbà ọ́ níyànjú láti sàbẹ̀wò sí ilé ìwòsàn láti ri dájú pé ìṣẹ́yún náà jẹ́ àṣeyọ́rí sùgbọ́n gbogbo ìgbà kọ́ni o nílò láti lọ. Kàn sí àwọn alábojútó rẹ tí o bá ní àwón àmì ìkìlọ̀ kankan bi ẹ̀jẹ̀ dídà, ibà, ìrora nla, àmì àkóràn tàbí tí o bá rò wípé o sì lóyún. Àyẹ̀wò ìtọ̀ fún oyún yẹ kó gbé èṣì tó lòdì jáde láàrín ọ̀sẹ̀ mẹ́rin sí márùn lẹ́yìn ìṣẹ́yún pẹ̀lú ògùn. ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ma ń pàdà sí ẹnu iṣẹ́ wọn nígbà tí wọ́n bá rò pé ó yẹ. o lè rí àlàyé sii lórí ìtọ́jú lẹ́yìn ìṣẹ́yún lórí ojúewé ìṣẹ́yún pèlú ògùn wa tàbí ní ojúewé àwọn ìbéèrè tí wọ́n béèrè lọ́pọ̀ ìgbà | Àbẹ̀wò sáábà ma ń tẹ̀lé ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn sùgbọ́n ki ṣe dandan. kí àwọn eniyan kàn sí ilé ìwòsàn wọn tí wọ́n bá ní ìrírí, ẹ̀jẹ̀ dídà, ibà, ìrora tó le, àmì àkóràn tàbí oyún náà sì ń tẹ̀síwájú. Àyẹ̀wò ìtọ̀ fún oyún yẹ kó gbé èṣì tó lòdì wá lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́rin sí márùn ti ìlànà náà. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ma ń pàdà sí ẹnu iṣẹ́ wọn nígbà tí wọ́n bá setán lẹ́yìn ìṣẹ́yún nínú ilé ìwòsàn. O lè rí àlàyé sii lórí ìtọ́jú lẹ́yìn ìṣẹ́yún lẹ́yìn ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí lórí ojúewé "ìtọ́sọ́nà sí ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí aìléwu" tàbí ní ojúewé àwọn ìbéèrè tí wọ́n béèrè lọ́pọ̀ ìgbà |
| Ìtọ́jú Ìdènà Oyún | ||
| Ìtọ́jú Ìdènà Oyún | O lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọlọpọ̀ irú ọ̀nà ìdènà oyún lẹ́yìn ìṣẹ́yún. Láti wá ọ̀nà ìdènà oyún tí ó yẹ, lọ findmymethod.org | Gbogbo irú ọ̀nà ìdènà oyún le bẹ̀rẹ̀ ní kété lẹ́yìn ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí Láti wá ọ̀nà ìdènà oyún tí ó yẹ, lọ findmymethod.org |
Àwọn ìbéèrè tí wọ́n sábà máa ń béèrè lọ́pọ̀ ìgbà
Rárá o, bí wọ́n bá lo àwọn ọ̀nà tí wọ́n fọwọ́ sí, kò séwu rárá láti ṣẹ́yún. Àwọn ìṣẹ́yún tí wọ́n fi ògùn ṣe àti àwọn ìṣẹ́yún tí wọ́n ń ṣe nínú ilé ìwòsàn bíi ìṣẹ́yún pẹ̀lú Ẹ̀rọ Afẹ́fẹ́ Aláfọwọ́yí (MVA) múnádoko, kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ yọrí sí àwọn ìṣòro líle (nǹkan bí ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀ràn) yọrí sí ìsòro líle. Kódà, Oyún ṣíṣẹ́ kò léwu ju ọ̀pọ̀ ìtọ́jú tí wọ́n sábà máa ń fúnni lọ, títí kan ìbí ọmọ.
Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) sọ pé ìṣẹ́yún kò ní ààbò tàbí jẹ́ ewu kìkì nígbà tí ẹnì kan tí kò ní ìmọ̀ tó tọ́ bá ṣe é tàbí ní ibi tí wọn kò ti tẹ̀lé ìlànà ìṣègùn. Àjọ Ìlera Àgbáyé ń ṣètìlẹyìn fún ìṣẹ́yún tí àwọn èèyàn fúnra wọn ń ṣe pẹ̀lú oògùn nígbà tí àlàyé tó péye bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó. safe2choose ń fúnni ní ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé fún àwọn ọ̀nà méjèèjì.
Gẹ́gẹ́bí ìlànà ìṣègùn kankan,sùgbọ́n wọn kò wọ́pọ̀ àti pé ó rọrùn láti tọ́jú. Díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tí wọ́n lè ní ni oyún tí wọ́n ṣẹ́ tí kòpé, ìsun ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ gan-an, tàbí kí oògùn má ṣe wọ́n lára. Ó ṣe pàtàkì láti mọ àwọn ìkìlọ̀ àti ìgbà tó yẹ kéèyàn wá ìrànlọ́wọ́. Wo ìtọ́nisọ́nà wa tàbí kàn sí ẹgbẹ́ àtìlẹ́yìn wa fún àlàyé díẹ̀ sii.
Orisun:
[1] "Ìlànà ìtọ́jú ìṣẹ́yún". Àjọ Ìlera Àgbáyé, 2022, iris.who.int/handle/10665/349316 Tí a gbà wọlé ní Oṣù Keje ọdún 2025.
[2] Raymond, E.G., Grimes, D.A. Àkọlé àwòrán "Bí wọ́n ṣe dáàbò bo oyún ṣíṣẹ́ àti ọmọ bíbí tó bófin mu ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà". National Library of Medicine, 2012, Feb;119(2 Pt 1):215-9, pubmed.ncbi.nlm.nih.gov/22270271/ Tí a gbà wọlé ní Oṣù Keje ọdún 2025.
[3] Jackson, E., et al. "Àwọn àtúnṣe ìṣègùn lórí ìlera ìbímọ". Ipas, 2023, www.ipas.org/wp-content/uploads/2023/09/Ipas-Clinical-Updates-in-Reproductive-Health-CURHE23b.pdf Tí a gbà wọlé ní Oṣù Keje ọdún 2025.
Ó dára láti bèèrè fún àtìlẹ́yìn
Má ṣe ṣiyè méjì láti kan sí wa.
Tí o bá nílò àlàyé síi tàbí kò rí ohun tí o n wá, má ṣe ṣiyè méjì láti kan sí wa ní ojúlé ìmọ̀ràn wa àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ wa.
