Oríṣi Ìṣẹ́yún onísẹ́ abẹ

Iṣẹyun Ile-iwosan

oríṣiríṣi ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ tí a lè ṣe ní oríṣi ọ̀sẹ̀ tí oyún jẹ́ ni ó wà. Ojú ewé yìí sàlàyé ìlànà kọ̀ọ̀kan.

Kí ni Ìṣẹ́yún onísẹ́ abẹ?

1/ Ìtumọ̀ ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ

Ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ jẹ́ ọ̀nà aláìléwu ti ó sì dara jùlọ fún iru ọ̀nà ìṣẹ́yún tí ó yàn, tàbí ìsàkóso oyún wíwálé, tí a sì má n ṣe ní ilé ìwòsàn nípasẹ̀ akọ́sẹ́mọsẹ́ alábójútó ètò ìlera. [1]

Lákòkò ìgbà tí ètò yìí bá ń lọ, oníṣègùn yóò lọ irinṣẹ́ fi la enu ọ̀nà ilé ọmọ díẹ̀díẹ̀, lẹ́yìn náà yoo wá lo ọ̀nà ìrètí yọ oyún náà láti inú ilé omo. Ó ṣeéṣe kí obìnrin náà ó ni ìrírí pajá-pajá lakoko náà, ó sì le jẹ́ pé yóò ma sun ẹ̀jẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ lẹ́yìn náà [2]

2/ Oríṣi ọ̀nà tí a lè gbà ṣẹ́yún pẹ̀lú ìṣe abẹ

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà tí a le fi ṣe ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ ló wà, ìwọ sì lè yàn níbẹ̀, ó sì má ń níṣe pẹ̀lú oṣù tí oyún bá wà. Nítorí àyípadà má ń wà nínú àsìkò tí oyún yóó fi wá nínú fún oríṣiríṣi ọ̀nà ìṣẹ́yún, ìpinnu náà le dá lórí agbègbè tí o wà, wíwà ohun èlò àti olùpèsè àti èyí tí ó bá wù ọ́ [1], [2]

  • Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA) jẹ́ ọ̀nà tí a ń gbà yọ nǹkan tó wà nínú ilé ọmọ, a sì má ń lòó fún oyún tí kò ju ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sì mẹ́rìnlá lọ lọ́pọ̀ ìgbà
  • Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ iná (EVA) jẹ́ ọ̀nà tí a ń gbà yọ nǹkan tó wà nínú ilé ọmọ, a sì má ń lòó fún oyún tí kò ju ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀dógún lọ
  • A má ń lo ètò líla ẹnu ilé ọmọ àti yíyọ gbogbo nǹkan tó wà nínú ilé ọmọ fún oyún tí ó ti kọjá ọ̀sẹ̀ mẹ́rìnlá
  • Lọ́pọ̀ ìgbà bí a bá ṣẹ́yún nípa fífa ìrọbí a má ń lòó fún oyún tó ti kọjá oṣù mẹ́rìndínlógún.
  • Líla ẹnu ilé ọmọ àti ìmúláradá jẹ́ ètò ìṣẹ́yún ìgbà àtijọ́ tí a sì ti fi ètò yíyọ nǹkan tó wà nínú ilé ọmọ, ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọwọ́yí (MVA), ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ iná (EVA) àti ètò líla ẹnu ilé ọmọ (D&E) rọ́pò rẹ̀.

Safe2choose fi ọwọ́ sí MVA fún oyún tí ó wà ní oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù mẹ́ta ẹ̀kejì, wọ́n sì pèsè àlàyé tó péye lórí àwọn ètò yìí.

3/ Lílo ògùn tí kìí jẹ́ ká fura fún ìṣẹ́yún ìṣe abẹ

Oríṣiríṣi ògùn tí kìí jẹ́ ká fura tí a lè lo fún ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ ló wà, oṣù tí oyún bá sì wà ni yóò sọ ọ̀nà tí a ó lò, àti wíwà àwọn olùṣàkóso ògùn náà ní ilé ìwòsàn. Oríṣi ọ̀nà tí ó ṣeé ṣe láti fi lo ògùn yìí ni ìwọ̀nyí [3]:

  • Ògùn ìbílẹ̀ tí kìí jẹ́ ká fura: Èyí ni ògùn tí kìí jẹ́ ká fura tó wọ́pọ̀ jùlọ fún ṣíṣẹ́yún pẹ̀lú ìṣe abẹ. Ó jẹ́ ògùn tí kìí jẹ́ kí ẹ̀yà ara ṣiṣẹ́, tí a má ń gún pẹ̀lú abẹ́rẹ́ sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ kí ó le rọrùn nígbàtí a bá ń ṣe é. Ojú obìnrin náà yóò wà ní lílà yóò sì mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀
  • Ògùn ìfọ̀kànbalẹ̀ níwọ̀ntunwọ̀nsì: Èyí ni ògùn tí kìí jẹ́ kí a fura tí à ń darí tààrà sínú iṣan, ó sì má ń jẹ́ kí mímọ ohun tó ń lọ lágòó ara obìnrin náà ó dín kù díẹ̀ díẹ̀. Yóò máa dáhùn sí ọ̀rọ̀ ẹnu lóòrèkóòrè.
  • Ògùn ìfọ̀kànbalẹ̀ tí ó jinlẹ̀: Èyí ni ògùn tí kìí jẹ́ kí a fura tí à ń darí tààrà sínú iṣan, ó sì má ń jẹ́ kí mímọ ohun tó ń lọ lágòó ara obìnrin náà ó dín kù díẹ̀ díẹ̀. Yóò máa dáhùn sí ọ̀rọ̀ ẹnu lóòrèkóòrè.
  • Ògùn gbogboogbò tí kìí jẹ́ ká fura: Èyí le lo àkójọpọ̀ gígùn pẹ̀lú abẹ́rẹ́ tàbí fífa àwọn ògùn tí kìí jẹ́ ka fura símú. Kì yóò dáhùn sí ọ̀rọ̀ ẹnu.

Kí ni ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọ̀wọọ́yí (MVA)?

Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ aláfọ̀wọọ́yí jẹ́ ọ̀nà aláìléwu tí a fi ń ṣẹ́yún tí ó bá wà ní oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́, àti /tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù mẹ́ta èkejì títí yóò fi dé ọ̀sẹ̀ kẹrìnlá [2]. Ilé ìwòsàn pẹ̀lú alábòójútó ìlera pípé tí ó ń ṣe ètò náà ni yóò sọ ìgbà tí oyún ti kọjá èyítí MVA le ṣe.

Alábòójútó tí ó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ ni ó má ń ṣe MVA ní ilé ìwòsàn.

Nígbàtí ètò náà bá ń lọ, oníṣègùn yóò lo àwọn irinṣẹ́ bíi ẹ̀rọ afaǹkan tí kìí pariwo láti fi yọ oyún náà láti ilé ọmọ [2]. Lọ́pọ̀ ìgbà a má ń ṣe ètò yìí nípa lílo ògùn ìbílẹ̀ tí kìí jẹ́ ká fura, èyí má ń lo ìṣẹ́jú márùn-ún sí mẹ́wàá. Ó ṣeé ṣe kí obìnrin náà ó rí ìrírí inú rírun nígbàtí a bá ń ṣe ètò yìí, ó sì lè máa sun ẹ̀jẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ lẹ́yìn náà. O lè rí àlàyé síi níbí.

Kí ni ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ iná (EVA) abortion ?

Ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ iná jẹ́ ọ̀nà aláìléwu, ó sì fẹ́ fara pẹ́ ọ̀nà MVA. A lè lo EVA fún oyún tó wà ní oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́, àti /tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù mẹ́ta èkejì. Alábòójútó akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni ó má ń ṣe EVA ní ilé ìwòsàn.

Nígbàtí ètò náà bá ń lo, oníṣègùn yóò lo àwọn irinṣẹ́ bíi ẹ̀rọ afaǹkan oníná fi yọ oyún náà láti ilé ọmọ.

Ìyàtọ̀ àkọ́kọ́ láàárín EVA àti MVA ni pé iná ni à ń lò láti fi ṣe irinṣẹ́ tí a ó fi yọ oyún. Nítorípé EVA nílò iná, ó le má wà níbi tí àwọn ohun àmúlò kò tíì wọ́pọ̀. Níbi tí ó bá wà, àwọn oníṣègùn le lo ọ̀nà EVA bí oyún ṣe ń lé síi lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sí méjìlá nítorí ó gba àwọn oníṣègùn láàyè láti ṣe ètò yìí kíákíá ju ti MVA lọ. Nípa bẹ́ẹ̀ yóò dín àkókò tí ètò náà yóò gbà fún obìnrin náà kù. Ìyàtọ̀ ńlá míràn ni pé EVA ní ṣe pẹ̀lú ariwo nítorí ó ń lo iná. [2]

Ki ní ètò ìṣẹ́yún líla ẹnu ilé ọmọ àti yíyọ gbogbi nǹkan tó wà nínú rẹ̀?

ètò líla ẹnu ilé ọmọ àti yíyọ gbogbi nǹkan tó wà nínú rẹ̀ (D&E) jẹ́ ọ̀nà aláìléwu tí a ń gbà ṣẹ́yún tí kò tíì ju ọ̀sẹ̀ mẹ́rìnlá lọ. Wíwà D&E dá lórí òfin tàbí ìhámọ́ tí ó de oyún ṣíṣẹ́ ni gbogbo àgbàlá ayé. Ní ibòmíràn D&E le wà fún àwọn obìnrin tó wù láti ṣẹ́yún, ó sì le má wà fún obìnrin tí kò bá fẹ́ ṣẹ́yún fún ìdí ìlera kan pàtó. O lè rí àlàyé nípa ìhámọ́ oyún ṣíṣẹ́ lágbègbè kọ̀ọ̀kan níbí.

Fún D&E, a má ń lo àwọn ohun èlò tí a fi ń la ẹnu ilé ọmọ láti jẹ́kí ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ rọ́. A má ń sábà lo àwọn ohun èlò yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí tàbí ọjọ́ gan-an kí a tó ṣe ètò náà. Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn yoo wá lọ àkójọpọ̀ irinṣẹ́ àti EVA láti fi yọ oyún náà. A lè lo ẹ̀rọ àyẹ̀wò inú nínú ètò náà. Oṣù tí oyún jẹ́ ni yóò wá so bóyá a lè lo ohun tí kìí jẹ́ ká fura ti ìbílè tàbí ògùn ìfọ̀kànbalẹ̀ láti lè dín ìnira kù fún obìnrin náà. [2], [3]

Kí ni líla ẹnu ilé ọmọ àti ìmúláradá (D&C)?

Dilation & Curettage jẹ́ ọ̀nà ìgbà àtijọ́ tí a fi ń ṣe ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ tí a sì ti fi ọ̀nà ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ rọ́pò rẹ̀. A kò gbà ọ́ níyànjú láti lo ọ̀nà yí mọ́.

Nígbàtí a bá ń ṣe D&C, a má ń la ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ, lẹ́yìn naa, a ó lo irinṣẹ́ ìmúláradá tí a fi ń dán ògiri ilé ọmọ láti fi yọ oyún náà. Ewu ìnira pò níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìrora nígbà tí a bá ń ṣe D&C tí a bá fi wé ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ. Fún ìdí èyí, àjọ ìlera àgbáyé (WHO) gbani níyànjú pé kí a fi ìṣẹ́yún pẹ̀lú ẹ̀rọ, D&E tàbí ìṣẹ́yún pẹ̀lú ògùn rọ́pò D&C nígbà tó bá ṣeé ṣe. [2], [3]

Kí ni ṣíṣẹ́ oyún bí ìrọbí

Níbi tí ó bá wà, ṣíṣẹ́ oyún bí ìrọbí jẹ́ ọ̀nà tí a le lò nígbàtí oyún bá wà ní oṣù mẹ́ta èkejì tàbí ẹ̀kẹta rẹ̀ (lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́rìndínlógún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ). Nígbàmíràn, ṣíṣẹ́ oyún bí ìrọbí jẹ́ àṣàyàn fún oyún tí a yàn láti ṣe, ṣùgbọ́n a má ń sábà lòó nígbàtí ìlera ìyá tàbí ọmọ bá wà nínú ewu tí oyún ṣíṣẹ́ sì jẹ́ ọ̀nà àbáyọ.
Àwọn ìtọ́kasí fún èyí má ń yàtọ̀ lọpọlọpọ gẹ́gẹ́bí ìhámọ́ àti òfin agbègbè tí o bá wà.

Ọ̀nà yí má ń ṣe bí ìrọbí, nípa lílo ògùn láti fa líla ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ àti fífún ilé ọmọ fún oyún ṣíṣẹ́. Nítorípé ọ̀nà oyún ṣíṣẹ́ yìí má ń wáyé nígbàtí oyún bá ti ń pé, a má ń ṣeé nílé ìwòsàn níbi tí a lè ti mójútó obìnrin náà fún àkókò tí ètò náà yóò gbà. Lọ́pọ̀ ìgbà kò nílò kí a lo irinṣẹ́ ìṣe abẹ àmọ́ a má ń sábà lo ìṣe abẹ tí a bá nílò rẹ̀. Ọ̀nà ìṣẹ́yún tó ti pẹ́ yìí kò wọ́pọ̀ tó D&E, nítorí ó má ń pẹ́ kí ó tó parí. [2]

Èló ni ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ

Iye owó ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ má ń yàtọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ gẹ́gẹ́ bíi: àgbègbè tí o wà, wíwà àwọn ohun èlò ìṣẹ́yún, ibi tí a ó ti ṣẹ́yún (ilé ìwòsàn) àti oṣù tí oyún wà.

Ṣé ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ kò léwu?

Ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ kò léwu bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn bá ṣeé. Àwọn ilé ìwòsàn tí ó ń ṣe ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ gbọ́dọ̀ tèlé gbèdẹ́ke àti àwọn ètò tí àwọn àjọ àgbègbè fi lélẹ̀ àti /tàbí ètò fún ìṣẹ́yún aláìléwu tí àjọ ìlera àgbáyé (WHO) ti ṣètò. [2]

Ó yẹ kí àwọn ètò yí sọ̀rọ̀ nípa (ṣùgbọ́n kìí ṣe èyí nìkan):

  • Tani ó le ṣètò ìṣẹ́yún
  • ìṣàkóso ògùn
  • ṣíṣe ìtọ́jú ohun èlò
  • ìṣàkóso gbogbo ìdọ̀tí àyíká
  • ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìṣẹ́ ṣíṣe àwọn alábòójútó ìlera
  • àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

Àwọn obìnrin tó fẹ́ ṣẹ́yún gbọ́dọ̀ ríi dájú pé ilé ìwòsàn tí wọ́n yàn ń lo ọ̀nà ìṣẹ́yún tí kò léwu tí a sì ti fi ọwọ́ sí

Agbára ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ tó ìdá mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ìdá ọgọ́rùn-ún [1]

Kí ni àwọn ewu àti ìnira tí a gbọ́dọ̀ fiyèsí nínú ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ?

Bí ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ ṣe jẹ́ aláìléwu tó, àwọn ewu díẹ̀ sọ mọ́ ètò náà bíi: ìsun ẹ̀jẹ̀, àkóràn, ìpalára fún ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ àti àwọn ẹ̀yà tó wà láyìíká rẹ̀, oyún tí kò ṣe tán, oyún tó ń dàgbà síi àti ikú

Àwọn ewu yìí kò ní pò tó bá jẹ́ pé akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn ló ṣeé, ṣùgbọ́n ó se pàtàkì fún ọ láti mọ̀ nígbàtí o bá gbà láti ṣe ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ. [2]

Kí ni àwọn àbájáde tí ó le jẹyọ lẹ́yìn ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ?

Gbogbo ọ̀nà àti ètò ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ má ń ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ṣe pẹ̀lú inú rírun tí ó lágbára tí obìnrin má ń ní ìrírí rẹ̀ nínú ètò yìí. Nígbà gbogbo inú rírun má ń tètè dínkù lẹ́yìnwà, àmọ́ fún àwọn obìnrin míràn inú rírun le máa wà déédéé fún ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ díẹ̀.

A má ń lo abẹ́rẹ́ tó má poró ìrora tó wà láyíká ibi tí a tí ṣe iṣẹ́ abẹ, eléyìí jẹ́ ohun ti a má ń lò fún iṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ , èyí kò sì ní jẹ́kí àwọn ẹ̀yà tó wà láyìíká ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ ṣeé gbé láti le fún obìnrin náà ní ìrọ̀rùn nínú ètò náà. [2]

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin yóò ní ìrírí ìsun ẹ̀jẹ̀ àti inú rírun nígbà tí a bá ń ṣe ìṣẹ́yún iṣẹ́ abẹ àti lẹ́yìn ìgbà tí a bá ṣeé tán. ó tún wọ́pọ̀ pe kí wọ́n ní oríṣiríṣi ìrírí lẹ́yìn ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ, gbogbo èyí kò jẹ́ tuntun, bí obìnrin náà bá sì rò pé òún nílò ìrànlọ̀wọ́ síi, kí ó béèrè fún ìrànlọ̀wọ́ olùbánidámọ̀ràn. [2]

Ǹjẹ́ ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ nira?

Ìrora tí ó wọ́pọ̀ jù nínú ìṣe abẹ ni inú rírun tí ó jinlẹ̀ tí obìnrin náà ń làkọjá nígbà ìṣẹ́yún naa. Lọ́pọ̀ ìgbà inú rírun náà yóò tètè dínkù, ṣùgbọ́n fún àwọn kan, inú rírun náà le máa wá kó máa lọ fún ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ díẹ̀. Ìjìnlẹ̀ ìrora náà má ń dá lé oṣù tì oyún bá wà àti bí obìnrin náà ṣe le gba ìrora mọ́ra, torí gbogbo ènìyàn ló má ń rí ìrírí ìrora lótọ̀ọ̀tọ̀. [2]

Ìtọ́jú lẹ́yìn ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ àti ọ̀nà ìfètò sọ́mọ bíbí

Lẹ́yìn ìṣẹ́yún oníṣẹ́ abẹ aláìléwu, a má ń dá obìnrin lábàá kí ó máa bẹ ilé ìwòsàn wò lóòrèkóòrè, bí eléyìí kò tilẹ̀ pa dandan, ó yẹ kí obìnrin kọ̀ọ̀kan gbó ìmọ̀ràn alábòójútó ìlera rẹ̀.

Kò sí iye àkókò kan pàtó tí obìnrin ní láti fi dúró tí yóò fi máa ṣe àwọn ìṣẹ́ pàtó bíi: ìwẹ̀ wíwẹ̀, eré ìdárayá, ìbálòpọ̀ tàbí wíwọ àwòtẹ́lẹ́ nǹkan oṣù tí ó má ń wọ ojú ara. Lápapò, a gbáà ní ìmọ̀ràn pé títí tí ẹ̀jẹ̀ náà yóò fi dá lẹ́yìn oyún ṣíṣẹ́ náà, kí obìnrin náà ṣọ́ra láti máa ki àwọn nǹkan bíi àwòtẹ́lẹ́ nǹkan oṣù tí ó má ń wọ ojú ara lọ, agolo nǹkan oṣù tí má ń wọ ojú ara lọ, kí wọ́n sí ṣọ́ra fún iṣẹ́ alágbára. Obìnrin kọ̀ọ̀kan le padà sí iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ tí agbára rẹ̀ bá gbẹ, obìnrin a sì máa yàtọ̀ síra.

Kí o tó kúrò ní ilé ìwòsàn, ó yẹ kí á ṣàlàyé nípa ọ̀nà tí o kò fi ní lóyún. Àwọn ọ̀nà tí o lè gbà tí o kò fi ní lóyún le bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ síbésíbẹ̀, ìjíròrò yẹ kó wáyé nípa obìnrin kọ̀ọ̀kan àti ọ̀nà tí ó yàn. Ó yẹ kí ilé ìwòsàn ó pèsè ibi tí wọn yóò ma pè sí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wọn ní ìbéèrè tàbí ìfiyèsí lẹ́yìn oyún ṣíṣẹ́. [2]

Ìdí tí obìnrin fi gbọ́dọ̀ wá àkíyèsí ilé ìwòsàn nìwọ̀nyí:

  • Sísun ẹ̀jẹ̀ gidigidi (rírẹ àwọtẹ́lẹ̀ nǹkan oṣù méjì ní wákàtí kan fún wákàtí méjì léraléra tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ)
  • Ibà (ìgbóná gidigidi) tí ó ju wákàtí mẹ́rin lélógún lọ lẹ́yìn ètò náà
  • Ìnira eegun ìdí tí ó burú gidi
  • Àmì oyún yóò ma farahàn síwájú síi (èébì, ọmú rírọ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ) [2]

Láti wá ọ̀nà tí kò fi ní lóyún tó bójúmu tí ó sì wù ọ́ kàn sí www.findmymethod.org

Àwọn òǹkọ̀wé:

nípasẹ̀ ikọ̀ safe2choose àti àwọn ọ̀mọ̀ràn ní carafem, ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Ipas ní ọdún 2019 àti ìmọ̀ràn WHO ní ọdún 2012

carafem ń pèsè ètò ìṣẹ́yún àti ìfètò sọ́mọ bíbí tí ó rọrùn tí ó sì dájú kí àwọn ènìyàn le ṣàkóso iye àti àyè tó wà láàárín àwọn ọmọ wọn.

Ipas jẹ́ àgbárí òkèèré kan ṣoṣo tí ó gbájúmọ́ fífi ètò sí oyún ṣíṣẹ́ tí kò léwu àti ìbójútó èlà mágboyín.

WHO jẹ́ abẹ̀wẹ̀ alámọ̀já ti Àjọ Àgbáyé tó wà lákoso ìlera àwùjọ ẹ̀dá káríayé.

[1] Weitz, T. A., Taylor, D., Desai, S., Upadhyay, U. D., Waldman, J., Battistelli, M. F., & Drey, E. A. (2013). Safety of aspiration abortion performed by nurse practitioners, certified nurse midwives, and physician assistants under a California legal waiver. American Journal of Public Health, 103(3), 454-461. Retrieved from: https://www.ncbi.nlm.nih.gov/pmc/articles/PMC3673521/

[2] World Health Organization (WHO). Safe abortion: technical and policy guidance for health systems, second edition. 2012. Retrieved from: https://apps.who.int/iris/bitstream/handle/10665/70914/9789241548434_eng.pdf;jsessionid=F77B761669FC579124C1E9CA2CC3CFDB?sequence=1

[3] Ipas. Clinical Updates in Reproductive Health. 2019. Retrieved from: https://ipas.azureedge.net/files/CURHE19-april-ClinicalUpdatesInReproductiveHealth.pdf

Safe Abortion with Pills Options

Download resources


download pdf icon Manual Vacuum Aspiration PDF

Check out the Manual Vacuum Aspiration video