Bí o ṣe lè fi Misoprostol ṣẹ́ oyún

Iṣẹyun pẹlu Ilana Misoprostol

A lè ṣe ìṣẹ́yún oníṣègùn pẹ̀lú Mifepristone àti Misoprostol ní sísẹ̀ n tẹ̀lé. Ojú ewé yìí ṣàlàyé bí a ṣe lè lo Misoprostol nìkan láti ṣẹ́yún pẹ̀lú ògùn. Tí o kò bá ní Mifepristone, jọ̀wọ́ wo ìtọ́sọ́nà yìí.

Kí o tó bẹ̀rẹ̀

Lílo Misoprostol a máa múnádóko dáradára (80-85%) [1, 2] láti yọ oyún tí ó ti pé ọ̀sẹ̀ mẹ́tàlá tàbí tí kò tí tó bẹ́ẹ̀

Rántí wípé àlàyé yìí wúlò fún ṣíṣẹ́ oyún ọsẹ mẹ́tàlá tàbí èyítí kò tó béè tí o bá kà láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí o rí nǹkan oṣù rẹ gbẹ̀yìn [1, 2, 3]. Nítorí a kò kọ́ wa láti ràn ọ́ lọwo fún oyún tó ju ọ̀sẹ̀ mẹ́tàlá lọ, a ó ṣe akitiyan láti kàn sí wa

Láti mọ̀ boya ọ̀nà yìí kò léwu fún ọ, a gbà ó níyànjú láti ka abala ìṣáájú nípa ìgbà tí kò tọ́ láti lo ògùn ìṣẹ́yún. Tí kò bá dá o lójú wípé ètò yìí tọ́ fún ọ, kàn sí wa.

Ìwọ̀n ìlò Misoprostol fún oyún ṣíṣẹ́

Wàá nílò ẹyọ Misoprostol méjìlá

Ti ó bá nira láti rí ẹyọ méjìlá, o lè lo ẹyọ mẹ́jọ ògùn Misoprostol ṣùgbọ́n ó le má ṣiṣẹ́ bó tí yẹ, o sì ní láti kàn sí àwọn olùbánidámọ̀ràn wa.
Tí oyún rẹ bá ti tó ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sí mẹ́tàlá, a gbà ọ́ níyànjú gidi gidi láti lo ẹyọ Misoprostol méjìlá.

Ó yẹ kí ẹyọ kàn jẹ́ igba mcg. [7]

Tí àwọn oògùn tí ò ń rí bá ní ìwọ̀n ìlò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ míkírómílígíràmù, wàá nílò láti tún ìsirò iye ìwọ̀n ṣe kí o ba lè lo ìwọ̀n tí ó tọ́ [8]

Tí o bá ní ìbéèrè kankan, jọwọ́ má ṣe sàfira láti kàn sí wa. A wà níhìn-ín láti ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ìrìnàjò ìṣẹ́yún rẹ

Bí o ṣe lè lo mifepristone ati misoprostol fún ìṣẹ́yún àìléwu

àwọn atọ́ka àìlera kò ní pé bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ìgbàtí o bá lo Misoprostol; nítorínà, yan àsìkò tí ó pé ìwọ àti iṣẹ́ re. tí o wà nílé láì níṣẹ́

protocol-medical-abortion-misoprostol-only

Ìgbésẹ̀ Kínní: Lo ibuprofen egbèrin mílígíràmù

Ìgbésẹ yìí ò pa dandan àmọ́ a gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn kí o ṣé. Ibuprofen a máa dín inú rírun kù, a sì ma ràn ọ́ lọ́wọ́ láti bójútó àwọn àìlera tí ó le jẹyọ [9]. Rántí wípé ibuprofen ṣe é lò láti ìbẹ̀rẹ̀ ètò náà títí dé òpin àti lẹ́yìn ètò náà tí o bá nílò rẹ̀. Àwọn obìnrin tí ibuprofen àti àwọn NSAID ò bá lára mu le yẹ àwọn ìbéèrè òrèkóòrè wa wò fún ìmọ̀ràn lórí àwọn ọ̀nà míràn tí a lè gbà tọ́jú ìrora

Tí o bá ní ògùn èébì, o lè lòó ní àkọ́kọ́ yìí

Dúró fún wákàtí kan

Ìgbésẹ̀ kejì: Fi Misoprostol mẹ̀ẹ́rin sábẹ́ ahọ́n fún ọgbọ́n ìṣẹ́jú.

Ó ṣe pàtàkì kí ògùn náà wà lábẹ́ ahọ́n rẹ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú kí ó báa lè wọnú ara lo. Lẹ́yìn ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, o lè mu omi láti ṣan ẹnu rẹ àti láti gbé ògùn náà mi [1]

Tí o bá bì láàárín ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tí Misoprostol náà wà lábẹ́ ahọ́n rẹ, ó ṣeé ṣe kó má ṣiṣẹ́. Tí èyí bá ṣẹlẹ̀ ó ṣe pàtàkì láti tún ìgbésẹ̀ kejì gbé.

Tí o bá bì lẹ́yìn tí o ògùn náà ti wà lábẹ́ ahọ́n rẹ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, o kò ní láti tún ìgbésẹ̀ kejì gbé nítori àwọn ògùn náà ti wa nínú àgò ara rẹ.

Dúró fún wákàtí mẹ́ta

Ìgbésẹ̀ Kẹ́ta: Ṣe ìgbésẹ̀ Keji lẹ́ẹ̀kan sí, kó wa fi Misoprostol mẹ́ẹ̀rin míràn sábẹ́ ahọ́n fún ọgbọ̀n ìṣẹ́júI

Dúró fún wákàtí mẹ́ta

Ìgbésẹ̀ kẹẹ̀rin: Tún ìgbésẹ̀ kejì gbé kí o sì fi Misoprostol mẹ́ẹ̀rin míràn sábẹ́ ahọ́n fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú.

Ẹ̀jẹ̀ dídà má ń sábà bẹ̀rẹ̀ láàrín wákàtí bíi mélòó kan. Tí ó bá ti tó wákàtí mẹ́rìnlélógún tí o lo Misoprostol mẹ́rin àkọ́kọ́ tí ẹ̀jẹ̀ kò sì dá, tí inú rẹ kò sì kóso, kàn sí wa. Máṣẹ lo oògùn míràn mọ́ tí a ó fi jọ yẹ̀ẹ́ wò.

Àwọn atọ́ka àìlera tí a ń retí lẹ́yìn lílo Misoprostol.

Lẹ́yìn tí o bá lo Misoprostol, o máa rí ìrírí ẹ̀jẹ̀ dídà àti inú rírun. Àwọn obìnrin míràn (kìí ṣe gbogbo wọn) yóò yọ ẹ̀jẹ̀ dídì. Kò ṣeé ṣe kí èèyàn mọ ìgbà tí inú rírun yóò bẹ̀rẹ̀ tàbí tí ẹ̀jẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ sí dà, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà a máa bẹ̀rẹ̀ láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìgbàtí o lo Misoprostol àkọ́kọ́, àmọ́ ó le tó ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí síi. [10]

Ẹ̀jẹ̀ tó ye kó dà kò yẹ kó gara ju nǹkan oṣù rẹ lọ, àbí kó fara jọ́. Ó lè máa wá kó máa lọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí o lo ògùn náà. Ó yẹ kí ẹ̀jẹ̀ tó ń dà ati àwọn atọ́ka oyún rẹ máa palẹ̀mọ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan [11]

Fún àwọn obìnrin tí oyún wọn wà ní ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sí mẹ́tàlá, o máa rí àwọn atọ́ka àìlera bíi ẹ̀jẹ̀ dídà àti inú rírun. Ó sì ṣeé ṣe kí o rí ọlẹ̀ inú nígbàtí ó bá já bọ́ sílẹ̀.[1] Lọ́pọ̀ ìgbà ọlẹ̀ náà le dàpò mọ́ ẹ̀jẹ̀ àti ẹ̀jẹ̀ dídì, a kìí sí ì mọ̀ pé ó wà níbè, àmọ́ ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ wípé kò jẹ́ tuntun tí o bá dáa mọ̀. Má bẹ̀rù ó ṣeé yí mọ́ àwọ̀tẹ́lẹ̀ nǹkan oṣù láti jùú dànù tàbí kí o sàn-án dànù sí ilé ìyàgbẹ́.

Rántí wípé ìrírí ìṣẹ́yún kọ̀ọ̀kan yàtò àti wípé àwọn atọ́ka àìlera yàtò láti obìnrin sí obìnrin.

Àwọn atọ́ka oyún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin ló má ń dúró lẹ́yìn bíi ọjọ́ márùn-ún tí wọ́n ti lo Misoprostol. Tí àwọn atọ́ka oyún rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí ní dínkù tí ó sì pòórá lẹ́yìn tí o lo ògùn náà, èyí jẹ́ àmì tí ó dára wípé o kò lóyún mọ́ [12]

Àwọn àìlera tí ó le jẹyọ lẹ́yìn tí o bá lo Misoprostol.

Lẹ́yìn tí a bá lo Misoprostol, àwọn àìlera míràn le jẹyọ lára àwọn obìnrin míràn tí ó le tó wákàtí tàbí ọjọ́ díẹ̀ [13]. Àwọn àìlera tí ó le jẹyọ yìí jé:

  • Ibà
  • Ìgbẹ́ gbuuru
  • Èébì
  • Orí fífọ́
  • Òtútù díẹ̀ díẹ̀
  • Ìṣọ́ra
Side_effects_during_abortion_with_pills_using_misoprostol_only

Ìṣọ́ra

Láti pagidínà ìsun ẹ̀jẹ̀ tí kìí dá àti /tàbí àkóràn, ó ṣe pàtàkì pé ní àwọn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀lé ẹ tàbí tí ẹ̀jẹ̀ dídà náà yóò fi ṣàn díẹ̀ [14], o ní láti ṣọ́ra fún àwọn nǹkan wọ̀nyí:

  • Má ṣe ti nǹkan bọ ojú ara rẹ, tó fi mú àwọ̀tẹ́lẹ̀ tó má ń wọ ojú ara
  • Má ṣe ṣiṣẹ́ alágbára (ère ìdárayá, gbígbé àti títì tàbí fífà nǹkan alágbára, rírìn kọjá àyè tàbí gígun àbágùnkè púpọ̀)
    Àkíyèsí: kò sí ẹ̀rí ìmọ̀ràn nípa iye ìgbà tí ó ye kí o dúró kí o tó ní ìbálòpọ̀ lẹ́yìn tí o ṣẹ́yún, àmọ́ ìgbìyànjú gbogboogbò ni wípé kí o dúró kí ẹ̀jẹ̀ tí ó ki bọ́ tán, kí o sì gbó ohun tí ara rẹ ń sọ àti ìfẹ́ ọkàn rẹ. [2]
precautions-to-take-after-abortion-pills

Àmì ìkìlọ̀: wíwá ìrànlọ́wọ́

Tí o bá ní ọ̀kan lára àwọn atọ́ka àìlera wọ̀nyí, èyí jẹ́ àmì ìkìlọ̀ wípé o lè máa ní ìnira, ó sì yẹ kí o tètè wá oníṣègùn rẹ lọ.

  • Tí aṣọ nǹkan oṣù rẹ bá kún (tó kún bámú bámú láti iwájú sí ẹ̀yìn) láàárín wákàtí méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
  • Ara gbígbóná ìwọ̀n cẹlṣíọ̀ṣì méjìdínlógójì (Ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún o lé pọ́ìntì mẹ́rin Fárẹ́háíntì) tí kò sì wálẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí o lo ibuprofen. Ríi dájú pé o lo òṣùwọ̀n ìgbóná tàbí òtútù láti ṣe àyẹ̀wò náà.
  • Ara gbígbóná ìwọ̀n cẹlṣíọ̀ṣì méjìdínlógójì (Ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún o lé pọ́ìntì mẹ́rin Fárẹ́háíntì) tí kò sì wálẹ̀ lẹ́yìn wákàtí mẹ́rìnlélógún tí o ti lo Misoprostol. Ríi dájú pé o lo òṣùwọ̀n ìgbóná tàbí òtútù láti ṣe àyẹ̀wò náà.
  • Ìrora tí kò dẹ̀ lẹ́yìn tí o lo ibuprofen
  • Òórùn tàbí àwọ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ yàtò sì ti nǹkan oṣù rẹ tàbí ó ní òórùn burúkú
  • Tí o bá ní ọwọ́, ọrùn àti ojú pípọ́n, yíyún tàbí wíwú, ó ṣeé ṣe kí ògùn náà má bá ọ lára mu. O lè lo ẹ̀rọ̀ (antihistamine) àmọ́ tí o kò bá le mí mọ́, a jẹ́ pé kò bá ọ lára mu rárá, o sì nílò láti kàn sí oníṣègùn rẹ ni kíá kíá [14]
Warning-signs-during-an-abortion-with-pills

Àwọn Ònkọ̀wé

Nípasẹ̀ iko safe2choose àti àwọn ọ̀mọ̀rán ní carafem ní ìbámu pèlú ìmọ̀ràn Ipas ní ọdún 2020 àti ìmọ̀ràn WHO ní 2012 àti 2014.

carafem ń pèse ètò ìsẹ́yún àti ìfètò sọ́mọ bíbí tí ó rọrùn tí ó sì dájú kí àwọn ènìyàn le ṣàkóso iye àti àyè tí ó wà láàrin àwọn ọmọ wọn

Ipas nìkan ni àjọ àgbáyé tí ó fojúsí ìtànkálẹ̀ ìráàyè sí ìṣẹ́yún àìléwu àti ìtọ́jú ìdènà oyún nìkan.

WHO jẹ́ àgbárí United Nations tí wọ́n gbé iṣẹ́ ìlera gbogbogbò lágbàáyé fún.

[1] World Health Organization. Safe abortion: technical and policy guidance for health systems. Retrieved from: https://apps.who.int/iris/bitstream/handle/10665/70914/;jsessionid=AB2B02D2E41FB4F6CF95B5F59B0A9AF4?sequence=1

[2] Ipas. (2020). Clinical Updates in Reproductive Health. L. Castleman & N. Kapp (Eds.). Chapel Hill, NC: Ipas. Retrieved from: https://www.ipas.org/wp-content/uploads/2020/08/ClinicalUpdatesInReproductiveHealthCURHE20-English-digital.pdf

[3] World Health Organization. Clinical guidelines for safe abortion. 2014. Retrieved from: https://apps.who.int/iris/bitstream/handle/10665/97415/9789241548717_eng.pdf?sequence=1

[4] National Abortion Federation. 2020 Clinical Policy Guidelines for Abortion Care. Retrieved from: https://5aa1b2xfmfh2e2mk03kk8rsx-wpengine.netdna-ssl.com/wp-content/uploads/2020_cpgs_final.pdf

[5] Guttmacher institute. Early Pregnancy Failure: Misoprostol May Be Good Alternative to Surgery. Retrieved from: https://www.guttmacher.org/journals/psrh/2006/early-pregnancy-failure-misoprostol-may-be-good-alternative-surgery

[6] Platais I, Tsereteli T, Grebennikova G, Lotarevich T, Winikoff B. Prospective study of home use of mifepristone and misoprostol for medical abortion up to 10 weeks of pregnancy in Kazakhstan. Retrieved from: https://www.ncbi.nlm.nih.gov/pubmed/?term=Prospective+study+of+home+use+of+mifepristone+and+misoprostol+for+medical+abortion+up+to+10+weeks+of+pregnancy+in+Kazakhstan

[7] Gynuity. Efficacy of Misoprostol Alone for First-Trimester Medical Abortion: A Systematic Review. Retrieved from: https://gynuity.org/resources/efficacy-of-misoprostol-alone-for-first-trimester-medical-abortion-a-systematic-review

[8] Elizabeth G. Raymond, Caitlin Shannon, Mark A, Weaver, Beverly Winikoff. First-trimester medical abortion with mifepristone 200 mg and misoprostol: a systematic review. Retrieved from: https://www.contraceptionjournal.org/article/S0010-7824(12)00643-9/fulltext

[9] Livshits, Anna et al. Fertility and Sterility, Volume 91, Issue 5, 1877 – 1880. Ibuprofen and paracetamol for pain relief during medical abortion: a double-blind randomized controlled study. Retrieved from: https://www.fertstert.org/article/S0015-0282(08)00176-3/fulltext

[10] Gynuity. providing medical abortion in low-resource settings: an introductory guidebook. Second Edition. Retrieved from: https://gynuity.org/assets/resources/clinguide_maguide2nd_edition_en.pdf

[11] Planned Parenthood. How does the abortion pill work? Retrieved from: https://www.plannedparenthood.org/learn/abortion/the-abortion-pill/how-does-the-abortion-pill-work

[12] Gynuity. Self-Assessment of Medical Abortion Outcome using Symptoms and Home Pregnancy Testing. Retrieved from: https://gynuity.org/resources/self-assessment-of-medical-abortion-outcome-using-symptoms-and-home-pregnan

[13] National Abortion Federation. Expected Side Effects of Medical Abortion. Retrieved from: https://prochoice.org/online_cme/m2expected2.asp

[14] A.R. Davis, C.M. Robilotto, C.L. Westhoff, S. Forman, J. Zhang. Bleeding patterns after vaginal misoprostol for treatment of early pregnancy failure. Retrieved from: https://academic.oup.com/humrep/article/19/7/1655/2356520

[15] NHS. Risks-Abortion. Retrieved from: https://www.nhs.uk/conditions/abortion/risks/

Oyún ṣíṣẹ́ tí kò béwu dé pẹ̀lú òògùn

Our services