A ti ṣètò àwọn ohun èlò ìrànwọ́ wa ní ọ̀nà tí ó rọrùn, èdè oríṣiríṣi, tí ó sì ṣeé gbà sí ayélujára. Má ṣe ṣàfira láti pín àwọn nkàn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ó le nílọ̀ rẹ̀. Tí ó bá wù ọ́ láti gba àlàyé síwájú síi tàbí tí o bá ní àbá, kàn sí ikọ̀ olùbánidámọ̀ràn wa.

Àwọn ìlànà ìṣẹ́yún lọ́nà tí kò béwu dé tí o lè gbà lórí ẹ̀rọ ayélujára
Àwọn ìlànà ìṣẹ́yún wa tí ó jẹ́ pdf máa jẹ́ kí o lè gbà á láti orí ẹ̀rọ ayélujára kí o sì lè lò ó níbikíbi, kódà níbi tí kò ti sí àǹfààní láti lo ẹ̀rọ ayélujára.
Oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú òògùn
Oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú fífà oyún jáde

Wo fídíò wa lórí oyún ṣíṣẹ́ lọ́nà tí kò béwu dé
Ó máa ń rọrùn láti mọ ohun tí ó wà nínú fídíò nígbà tí o bá fẹ́ mọ ohun tí ó yẹ kí o retí nígbà tí o bá ń ṣẹ́yún. Wo àwọn fídíò tí ó ń bọ̀ yìí láti mọ̀ nípa àwọn ìlànà oyún ṣíṣẹ́ tí kò béwu dé.
Oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú òògùn
Oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú fífà oyún jáde

Ìwádìí
Ìwádìí lórí fífi àbùkù kan àwọn olùtọ́jú oyún ṣíṣẹ́, pẹ̀lú Ipas
safe2choose ṣe ìwádìí káàkiri àgbáyé nípa fífi àbùkù kan àwọn olùtọ́jú oyún ṣíṣẹ́, wọ́n sì ṣe ìjábọ̀ tí ó kún ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Ipas. Láti ká ohun àbájáde ìwádìí náà, wo ìjábọ̀ wa ní ìsàlẹ̀.