safe2choose

Àwọn ìṣẹ́yún tí ó ní àlàyé jẹ́ ìṣẹ́yún tó ní ààbò.

Ṣé ò ń wá àlàyé nípa ìṣẹ́yún aláìléwu àti àṣàyàn ní safe2choose?

Gbogbo ènìyàn ló ní ẹ̀tọ́ láti rí àlàyé tó péye tí kò ní ìdájọ́ nínú nígbà tí a bá ń ronú nípa ìṣẹ́yún. Ní safe2choose, a pèsè ọ̀pọlọ̀pọ̀ àwọn orísun láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ ní ṣíṣe àwọn àṣàyàn tí ó ní ìmọ̀ràn, láì ka ibi tí o wà ní àgbáyé sí. À ń fún ni ní àwọn ìtàn ti ara ẹni, àlàyé ofin ti orílẹ̀-èdè ní pàtó, gbígba àwọn ìtọ́sọ́na láti orí ayélujára, àdárọ ẹsẹ, àti àwọn àǹfàní ìkẹ́èkọ́, èróǹgbà wa ní láti jẹ́ kí ìmọ̀ ìṣẹ́yún àìléwu wà ní àrọ́wọ́tó tí ó sì ń ró ni lágbára. Ṣàwárí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ìsàlẹ̀ láti rí àtìlẹ́yìn àti àwọn ìdáhùn tí o nílò.

A laptop showing the safe2choose site, a pair of hands with a watch in the left wrist is interacting with the laptop, there's a cup of coffee, a notebook, and a plant on the sides of the laptop. illustration

Báwo ni ìrírí Gidi nípa ìṣẹ́yún ṣe rí?

Àwọn ìtàn ìṣẹ́yún: àwọn ohùn gidi, àwọn àṣàyàn gidi.

Kà (tàbí pín tìrẹ) àwọn ìtàn ìṣẹ́yún tí ó lágbára láti káàkiri àgbáyé. Àwọn ìrírí tó jẹ́ òótò́ wọ̀nyí ṣe ìrànlọ́wọ́ láti fọ́ àbùkù àti láti rán wa létí pé ìṣẹ́yún jẹ́ apákan tí ó wọ́pọ̀ tí ó sì wúlò ní ti ìlera ìbísí. ”

llustration of abortion access worldwide showing a globe with location pins, law books and a judge’s gavel symbolizing abortion laws, and abortion pills with a glass of water. illustration

Kí Ni Òfin àti Àṣàyàn Ìṣẹ́yún Ní Orílẹ̀-Èdè Mi?

Àlàyé nípa ìṣẹ́yún ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọkan.

Àwọn òfin àti ànfààní yàtọ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Ṣàwárí ohun tí ó jẹ́ òfin àti ohun tí ó wà ní orílẹ̀-èdè rẹ láti ṣe àwọn àṣàyàn tí ó ní ìmọ̀ràn àti àìléwu pẹ̀lú ìgboyà.

Woman researching reproductive health online, with laptop showing uterus diagram and icons of contraception methods like IUD, condom, pill, and injection. illustration

Àwọn Búlòògì Ìṣẹ́yún Wa

Gba àwọn ìròyìn tuntun pẹ̀lú safe2choose.

Ṣàwárí àwọn àpilẹ̀kọ àlàyé lórí ìṣẹ́yún, ẹ̀tọ́ ìbímọ, àti ìtọ́jú, pẹ̀lú ìmọ̀ràn àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n, ìrírí ara ẹni, àti ìmúdójúìwọ̀n láti ọ̀dọ̀ ilé-iṣẹ́ náà.

Podcast cover art for ‘Mind Your Uterus’ by safe2choose, featuring two diverse people sitting confidently against a pink background with stars and patterns. illustration

Àdárọ-ẹsẹ Ìṣẹ́yún wa

Ìtàkurọ̀sọ tó ṣe pàtàkì.

Gbọ́ ohùn àgbáyé tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀tọ́ ìṣẹ́yún àti òtítọ́. Gbọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alátakò, àwọn olùpèsè, àti àwọn Akóòtàn kárí ayé bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ ní gbangba nípa ìṣẹ́yún tí wọ́n sì ń j̀a fún ìráyè, ìṣẹ̀lẹ̀ kan ní gbà kan.

Illustration of a woman presenting digital resources on abortion pills, secure files, and learning tools, symbolizing training and certification for abortion counselors illustration

Báwo ni mo ṣe lè di olùgbani-nímọ̀ràn ìṣẹ́yún tí ó ní ìwé-ẹ̀rí?

Ìwé-ẹ̀rí àwọn olùgbani-nímọ̀ràn ìṣẹ́yún lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Èyí jẹ́ ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn tí wọ́n fẹ́ ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa pípèsè ìmọ̀ràn ìṣẹ́yún tó péye tí ó sì ní ìyọ́nú. Ó wà fún àwọn ènìyàn àti àwọn àjọ káàkiri àgbáyé.

KÀN SÍ WA

Má ṣe ṣiyèméjì láti kàn sí wa.

Tí o bá nílò àfikún àlàyé tàbí tí o kò rí ohun tí ò ń wá, má ṣe ṣiyèméjì láti kàn sí wa nípasẹ̀ Ojú-ewé ìmọ̀ràn wa àti àwọn ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ wa