Onírúurú ọ̀nà ló wà téèyàn lè gbà dènà oyún lẹ́yìn tó bá ṣẹ́yún, èyí tó sì dára jù lọ ni èyí tó bá ohun tó o nílò àti ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ mu. Ohun tó dáa jù ni pé kó o wá ọ̀nà tí kò ní jẹ́ kó o lóyún tí ó rọrùn fún ọ; ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tó o lè ṣe, bíi rọ́bà ìdáàbòbò (kọ́ńdọ̀mù), oògùn ìfètò sọ́mọ bíbí,IUD (Ohun èlò tí a fi ń dènà oyún tí a gbé sínú ilé ọmọ), àti ohun èlò tí wọ́n fi ń sì ẹ̀yà ara míì mọ́ ara. Yálà o ń wá nǹkan tó máa wà fún àkókò gígùn, tó ní èròjà hòmónù nínú tàbí tí kò ní èròjà hòmónù nínú, oríṣiríṣi nǹkan ló wà tó o lè ṣe àwọn oríṣiríṣi ọ̀nà ló wà.
Tó o bá fẹ́ mọ àwọn àṣàyàn rẹ, lọ wo ìkànnì Find My Method – Ó jẹ́ ohun èlò tó dára láti ṣe àfiwé àwọn ọ̀nà àti láti mọ èyí tó dára.
Bákan náà, má gbàgbé pé o jẹ àìléwu láti ní ìbálòpọ̀ lẹ́yìn tó o bá ti ṣẹ́yún tó o sì ti múra tán nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Àmọ́ rántí, o lè lóyún ní kété bi ọ̀sè méjì lẹ́yìn ìṣẹ́yún, kódà bó bá ṣì ń ṣẹ̀jẹ̀. Àkókò oṣù rẹ tún le yípadà díẹ̀, nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kó o mọ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ ṣe máa ń rí.
Oyún àti Ọ̀nà Ìdènà Oyún - FAQ
Ìbánisọrọ àti Atilẹyìn
Gba àtìlẹyìn àti ìmọràn nípa ìṣẹyún
A pèsè àlàyé tó dá lórí ẹrí lórí ìṣẹyún aláìléwu. Iṣẹ ìmọràn ọfẹ wa wà ní ààbò, ìkọkọ, ìrọrùn, àti láìsí ìdájọ. A n duro de ifiranṣẹ rẹ!