Nigeria

Anonymous, Age: 30

Òṣìṣẹ́ safe2choọ̀sẹ̀ fanimóra, ó sì lọ́yàyà. Wọ́n tún ní àkọsílẹ̀ mi nítorínà n kò nílò láti tún àlàyé ṣe nígbàtí mo padà lo kò tilè dámilójú bóyá enìkan náà ni mò ń bá jíròrò láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin ètò náà, àmọ́ ó dàbí pé enìkan náà ni, onítọ̀hún sì ṣe ìrànwọ́ dáradára. Oyún ṣíṣẹ́ náà lo ní ìrọwọ́rọsè. Gbogbo rẹ̀ lọ déédéé bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ẹ̀rù bàmí díẹ̀ nítorí ara mi ń gbọ̀n bíi ẹni máa kú. Ọwọ́ àti gbogbo ara mi ló ń gbọ̀n. Mo wọ àwọ̀tẹ́lè ǹkan oṣù nkò sì kọ́kọ́ ríi kí ǹkankan dà lára mi, àmọ́ kété tí mo dìde ló ya bíi omi ẹ̀rọ. Ó bà mìí lẹ́rù díẹ̀. Ẹ̀bi dé bá mi, kódà mo ṣì má ń dá ara mi lẹ́bi, mi ò mọ ìgbàtì ẹ̀bi náà yóó tán lára mi. Ẹ̀jẹ̀ náà dà gidi gan fún wákàtí méjì àkọ́kọ́, lẹ́yìn náà fún bíi ọ̀sẹ̀ méjì, ó dà bí ǹkan oṣù mi ṣe ń dà. Ìgbàmíràn mo máa rí ẹ̀jẹ̀ kékeré tàbí kó tilẹ̀ má sí rárá, ìgbàmíràn sì rèé ǹkan aláwọ̀ páálí ni yóó yọ láti ojú ara mi. Níbáyìí, ó ti pé ọ̀sẹ̀ méjì tí mo ti ṣẹ́ oyún yìí bí mo sì ṣe ń kọ èyí, ẹ̀jẹ̀ náà ti dá ráú ráú… àbí pẹ̀lú ìrètí. Mo lérò wípé ètò ìṣẹ́yún mi lo dédé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ó bà mìí lẹ́rù díẹ̀!

Mú orílè èdè náà