Ìṣẹ́yún ní Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà

Nàíjíría-ìsẹ́yún-àlàyé

Ìṣẹ́yún ní ilẹ̀ Nàíjíría sì jẹ́ ohun tí kò ṣé fi etí gbọ́ pàápàá ní àwùjọ àti ní àwọn ilé ìjọsìn. Orìsirìsi ọ̀rọ̀ àti àgbàwí ni ó sì ń lọ lọ́wọ́ nípa fífi ojú ẹ̀ṣẹ̀ wo ìṣẹ̀yún ní ilẹ̀ Nàíjíría, láti dín iye àwọn obìnrin tí ó ń kú nípasẹ̀ àwọn ọ̀nà tí ó léwu tí wọ́n fi ń ṣẹ́yún.Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi ojú ẹ̀ṣẹ̀ wo ìṣẹ̀yùn, ìtọ́jú wà fún ẹnití ó bá ti ṣẹ́yún ní ilé ìwòsàn ìjọba tàbí ti aládàáni, tí k̀ií sìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀

Ǹjẹ̀ ẹ̀ṣè ni ìṣẹ̀yún ní Orílẹ̀-èdè Nàíjíría?

Ìgbà kan ṣoṣo tí wọ́n gba ìsẹ́yún ní Nàíjíríà ni láti fi la ẹ̀mí obìnrin náà. Oríṣi ìlaǹà òfin méjì ni ó wà ní Àrí́wá àti Gúsù Nàíjíríà nípa ìṣẹ́yún, ìlànà òfin ti Gúsù gba ìṣẹ́yún fún àláfíà pípé obìnrin náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará Àríwá ni ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí, tí ó sì jẹ́ pé ìlànà ofin tí ó fi ìyà jẹ ẹlẹ́sẹ̀ ni wọn ń lò tí àwọn ará Gúsù sì jẹ́ ẹlẹ́sin Kìrìsìtẹ́nì tí ó jẹ́ ìlànà òfin ti àwọn ọ̀daràn ni wọ́n ń lò.

Irú ìṣẹ́yún wo ni ó wà ní Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà?

Ọ̀nà ìṣègùn: Lílo òògùn bí Misoprostol (Cytotec, Miso Fem, Vanprazol-200.
Ọ̀nà abe: Ìsẹ́yún Manual Vacuum Aspiration (MVA)

Kínni òsùwọ̀n ìṣẹ́yún ní Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà?Obìnrin mélòó ni ó ń ṣẹ́yún?

Ní ọdún 2012, ìfojúsùn fi hàn pé ìṣẹ́yún mílíọ́nù kan lé ní ọ̀kẹ́ méjìlá àbọ̀(1.25m) ni ó wáyé ní ilẹ̀ Nàíj́iríà, èyí túnmò sí pé nínú ẹgbẹ̀rún obìnrin, mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ni á ṣẹ́yún ní ààrin ọdún mẹ́ẹ̀dógún sí ọ́kàndìńláàdọ́ta. Àfojúsùn àwọn oyún tí ó wáyé láìròtẹ́lẹ̀ jẹ́ ọ́kàndìńlọ́gọ́ta nínú ẹgbẹ̀rún obìnrin ní ààrin ọdún mẹ́ẹ̀dógún sí ọ́kànd̀ińláàdọ́ta. Mẹ́rìndínlọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún oyún àiròtẹ́lẹ̀ ni ó ma ń jẹ́ ṣíṣẹ́

Ìṣẹ́yún pẹ̀lú òògùn (Ìṣẹ́yún Olóògùn) ní Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà

Ǹjẹ́ òògùn ìṣẹ́yún (Mifepristone àti Misoprostol) wà ní Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà?

Òògùn ìṣẹ́yún wà ní Náíjíríà àmó kò ṣeé rà láì mú ìwé dání láti ọwọ́ oníṣègùn òyìnbó.
Àkíyèsí: Misoprostol wà ní Nàíjíríà gẹ́gẹ́bí ìtọ́jú lẹ́yìn oyún (Post-Partum Hemorrhage)

Báwo ni oyún ṣe lè pẹ́ sí kí ènìyàn tó lo òògùn ìṣẹ́yún?

Ènìyàn le lo Misoprostol ní ọ̀sẹ̀ kọkànlá fún ìṣẹ́yún olóògùn pẹ̀lú iye àti lílò tí ó pé.

Ǹjé mo lè ra Mifepristone àbí Misoprostol láì ní ìwé láti ilé ìwòsàn?

Misoprostol lábẹ́ orúkọ Cytotec le jẹ́ rírà ní ilè ìtajà òògùn àmó pẹ̀lú ìwé láti ilé ìwòsàn. Àkíyèsí: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onítàjà òògùn ni yóò ta Misoprostol láì mú ìwé láti ilé ìwòsàn àmó wọn kò kì ń ṣe àlàyé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lórí ẹni tí ó le lòó, iye tí ó le lò àti lílo òògùn ìṣẹ́yún. Jọ̀wọ́ kàn sí abala yìí lórí ayélujára wa fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtọ́sọ́nà ní bí a ti ń lo òògùn náà:——–

Irú òògùn ìṣẹ̀yùn wo ni ó gbajúgbajà ní Nàíjíríà?

Misoprostol wà ní abẹ́ orúkọ Cytotec, Miso-fem ati Vanaprazol – 200.
Mifepristone wà ní àpapọ́ ní abẹ́ orùkọ Mifepack

Èló ni òògùn ìṣẹ́yún ní Nàíjíríà?

Òògùn náà ma ń ṣábà jẹ́ ààrin dọ́là mẹ́ta sí dọ́là mẹ́sàn-án

Tani mo lè késí fún àlàyé síwájú si lórí ìṣẹ́yún ní Nàíjíríà?

Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé àti àdúrótì, kàn sí safe2choose.org tàbí kí o kàn sí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ obìnrin tí wọ́n le sọ oríṣiríṣi èdè tí wọ́n jẹ́ abánisọ̀rọ̀

Ìṣẹ́yún ní ilé ìwòsàn ní Nàíjíríà

Kínni irú àwọn ìṣẹ́yún tí ó wà ní ilé ìwòsàn ní Nàíjíríà?

Manual Vacuum Aspiration àti ti Electrical Vacuum Aspiration

Ibo ni mo ti lè rí ìṣẹ́yún Manual Vacuum Aspiration(MVA) ní Nàíjíríà?

Ìṣẹ́yún tí ó bá òfin mu àti ìtọ́jú lẹ́yín ìṣẹ́yún jẹ́ ohun tí ó jẹ́ pé àwọn tí ó ní ẹ̀kọ́ àti àṣẹ fún ìwòsàn ni wọn ma ń ṣeé àtipé ó wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ìwòsàn ìjọba àti aládàáni ni ènìyàn ti le ríi. Àkíyèsí: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ó jẹ́ àwọn tí kò ní ẹ̀kọ́ tàbí àṣẹ láti ṣẹ́yún ni wọ́n ma ń ṣeé, tí ó sì ma ń di ìpèníjà
Ríi dájú wípé ẹni tí o yàn fún ara rẹ jẹ́ eni tí ó ní ìwé-ẹ̀rí àti ẹ̀kọ́ fún ìtọ́jú ìṣẹ́yún tí ó péye

Èló ni iye Manual Vacuum Aspiration (MVA) ní Nàíjíríà?

Iye tí wọ́n ń ṣe ìṣẹ́yún àti ìtọ́jú ẹ̀yìn ìṣẹ́yún yàtọ̀ láti ibì kan sí ibí kan ( tí ó bá jẹ́ ti ìjọba àbí ti aládàáani), ó yàtò láti ẹnì kan tí ó ń ṣeé sí ẹlòmíràn lórí ọ̀nà tí wọ́n gbà (bóyá òògùn tàbí iṣẹ́ abẹ),àwọn ìdojúkọ àti bí ó ṣe peléke tó. Owó náà jẹ́ àarin dọ́là mẹ́ta sí mẹ́tàlèélọ́gọ́rùn-ún dọ́là.

Báwo ni mo ṣelè rí àlàyé si?

Fún àlàyé síwájú si, kàn sí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ obìnrin tí wọ́n le sọ oríṣiríṣi èdè tí wọ́n jẹ́ abánisọ̀rọ̀

Kọ ẹkọ nipa Iṣẹyun ni orilẹ-ede rẹ

Àwọn Ònkọ̀wé:

láti ọwọ́ ẹgbẹ́ safe2choose àti àwọn alátìlẹyìn amòye ní carafem, lórí àmọ̀ràn Ipas ní 2019 àti àmòràn WHO ní 2012

[1] Cost-effectiveness analysis of unsafe abortion and alternative first-trimester pregnancy termination strategies in Nigeria and Ghana.” African Journal of Reproductive Health, ResearchGate. https://www.researchgate.net/publication/49763986_Cost-effectiveness_analysis_of_unsafe_abortion_and_alternative_first-trimester_pregnancy_termination_strategies_in_Nigeria_and_Ghana

[2] “Facts on Unwanted Pregnancy and Induced Abortion in Nigeria.” Guttmacher Institute. https://www.guttmacher.org/sites/default/files/factsheet/fb_nigeria.pdf

[3] “Impact of abortion laws on women’s choice of abortion service providers and facilities in southeastern Nigeria.” Nigerian Journal of Clinical Practice. https://www.njcponline.com/article.asp?issn=1119-3077;year=2018;volume=21;issue=9;spage=1114;epage=1120;aulast=Chigbu

[4] “An Abortion Pill in a Murky Market.” Pulitzer Center. https://pulitzercenter.org/reporting/abortion-pill-murky-market

[5] “The Incidence of Abortion in Nigeria” https://www.ncbi.nlm.nih.gov/pmc/articles/PMC4970740/